YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 60

60
Adura fún Ìgbàlà
Orin Dafidi, nigbati o mba awọn ara Siria ti o wà larin odò meji, ati awọn ara Siria ti Soba ja, nigbati Joabu pada, ti o si pa ẹgbãfa ninu awọn ara Edomu li afonifoji iyọ̀.
1ỌLỌRUN, iwọ ti ṣa wa tì, iwọ ti tú wa ka, inu rẹ ti bajẹ; tún ara rẹ yipada si wa.
2Iwọ ti mu ilẹ warìri; iwọ ti fọ ọ: mu fifọ rẹ̀ bọ̀ sipò: nitoriti o nmì.
3Iwọ ti fi ohun ti o ṣoro hàn awọn enia rẹ: iwọ mu wa mu ọti-waini itagbọngbọn.
4Iwọ ti fi ọpagun fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ, ki a le ma fi i hàn nitori otitọ.
5Ki a le gbà awọn olufẹ rẹ là; fi ọwọ ọtún rẹ ṣe igbala, ki o si gbohùn mi.
6Ọlọrun ti sọ̀rọ ninu ìwa-mimọ́ rẹ̀ pe; Emi o yọ̀, emi o pin Ṣekemu, emi o si wọ̀n afonifoji Sukkotu.
7Ti emi ni Gileadi, ti emi ni Manasse; Efraimu pẹlu li agbara ori mi; Juda li olofin mi;
8Moabu li ikoko-iwẹsẹ mi; lori Edomu li emi o bọ́ bàta mi si: Filistia ma ho iho ayọ̀ fun mi!
9Tani yio mu mi wá sinu ilu olodi nì? tani yio sin mi lọ si Edomu?
10Iwọ ha kọ́, Ọlọrun, ẹniti o ṣa wa tì? ati iwọ, Ọlọrun, ti kò ba ogun wa jade lọ?
11Fun wa ni iranlọwọ ninu ipọnju: nitori pe asan ni iranlọwọ enia.
12Nipasẹ Ọlọrun li awa o ṣe akin: nitori on ni yio tẹ̀ awọn ọta wa mọlẹ.

Currently Selected:

O. Daf 60: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in