YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 6

6
Adura nígbà ìyọnu
1OLUWA, máṣe ba mi wi ni ibinu rẹ, ki iwọ ki o má ṣe nà mi ni gbigbona ibinujẹ rẹ.
2Oluwa, ṣãnu fun mi; nitori ailera mi: Oluwa, mu mi lara da; nitori ti ara kan egungun mi.
3Ara kan ọkàn mi gogo pẹlu: ṣugbọn iwọ, Oluwa, yio ti pẹ to!
4Pada, Oluwa, gbà ọkàn mi: gbà mi là nitori ãnu rẹ.
5Nitoriti kò si iranti rẹ ninu okú: ninu isa okú tani yio dupẹ fun ọ?
6Agara ikerora mi da mi: li oru gbogbo li emi nmu ẹní mi fó li oju omi; emi fi omije mi rin ibusùn mi.
7Oju mi bajẹ tan nitori ibinujẹ; o di ogbó tan nitori gbogbo awọn ọta mi.
8Ẹ lọ kuro lọdọ mi, gbogbo ẹnyin oniṣẹ ẹ̀ṣẹ; nitori ti Oluwa gbọ́ ohùn ẹkún mi.
9Oluwa gbọ́ ẹ̀bẹ mi; Oluwa yio gbà adura mi.
10Oju yio tì gbogbo awọn ọta mi, ara yio sì kan wọn gogo: nwọn o pada, oju yio tì wọn lojíji.

Currently Selected:

O. Daf 6: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in