YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 52

52
Ìdájọ́ ati Oore Ọ̀fẹ́ Ọlọrun
Orin Dafidi, nigbati Doegi, ara Edomu, wá, ti o sọ fun Saulu, ti o si wi fun u pe, Dafidi wa si ile Ahimeleki.
1ẼṢE ti iwọ fi nṣe-fefe ninu ìwa-ìka, iwọ alagbara ọkunrin? ore Ọlọrun duro pẹ titi.
2Ahọn rẹ ngberò ìwa-ìka; bi abẹ mimú o nṣiṣẹ ẹ̀tan.
3Iwọ fẹ ibi jù ire lọ; ati eke jù ati sọ ododo lọ.
4Iwọ fẹ ọ̀rọ ipanirun gbogbo, iwọ ahọn ẹ̀tan.
5Ọlọrun yio si lù ọ bolẹ lailai, yio si dì ọ mu, yio si ja ọ kuro ni ibujoko rẹ, yio si fà ọ tu kuro lori ilẹ alãye.
6Olododo yio ri i pẹlu, yio si bẹ̀ru, yio si ma rẹrin rẹ̀ pe,
7Kiyesi ọkunrin ti kò fi Ọlọrun ṣe agbara rẹ̀; bikoṣe li ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ rẹ̀ li o gbẹkẹle, o si mu ara rẹ̀ le ninu ìwa buburu rẹ̀.
8Ṣugbọn emi dabi igi olifi tutu ni ile Ọlọrun: emi gbẹkẹle ãnu Ọlọrun lai ati lailai.
9Emi o ma yìn ọ lailai nitoripe iwọ li o ṣe e: emi o si ma duro de orukọ rẹ; nitori ti o dara li oju awọn enia mimọ́ rẹ.

Currently Selected:

O. Daf 52: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in