YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 18:30-36

O. Daf 18:30-36 YBCV

Bi o ṣe ti Ọlọrun ni, ọ̀na rẹ̀ pé: a ti ridi ọ̀rọ Oluwa: on li apata fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e. Nitori pe tani iṣe Ọlọrun, bikoṣe Oluwa? tabi tani iṣe apáta bikoṣe Ọlọrun wa? Ọlọrun li o fi agbara dì mi li amure, o si mu ọ̀na mi pé. O ṣe ẹsẹ mi bi ẹsẹ àgbọnrín, o si gbé mi kà ibi giga mi. O kọ́ ọwọ mi li ogun jija, tobẹ̃ ti apa mi fà ọrun idẹ. Iwọ ti fi asà igbala rẹ fun mi pẹlu: ọwọ ọ̀tun rẹ si gbé mi duro, ati ìwa-pẹlẹ rẹ sọ mi di nla. Iwọ sọ ìrin ẹsẹ mi di nla nisalẹ mi, ki kóko-ẹsẹ mi ki o máṣe yẹ̀.