YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 147

147
Ọlọrun Alágbára
1Ẹ fi iyìn fun Oluwa: nitori ohun rere ni lati ma kọ orin iyìn si Ọlọrun wa: nitori ti o dùn, iyìn si yẹ.
2Oluwa li o kọ́ Jerusalemu: on li o kó awọn ifọnkalẹ Israeli jọ.
3O mu awọn onirora aiya lara da: o di ọgbẹ wọn:
4O ka iye awọn ìrawọ; o si sọ gbogbo wọn li orukọ.
5Oluwa wa tobi, ati alagbara nla: oye rẹ̀ kò li opin.
6Oluwa gbé awọn onirẹlẹ soke: o rẹ̀ awọn enia buburu si ilẹyilẹ.
7Ẹ fi ọpẹ kọrin si Oluwa; kọrin iyìn si Ọlọrun wa lara duru:
8Ẹniti o fi awọsanma bò oju ọrun, ẹniti o pèse òjo fun ilẹ, ti o mu koriko dàgba lori awọn òke nla.
9O fi onjẹ ẹranko fun u ati fun ọmọ iwò ti ndún.
10Kò ṣe inudidùn si agbara ẹṣin: kò ṣe inudidùn si ẹsẹ ọkunrin.
11Oluwa nṣe inudidùn si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, si awọn ti nṣe ireti ãnu rẹ̀.
12Yìn Oluwa, iwọ Jerusalemu; yìn Ọlọrun rẹ, iwọ Sioni.
13Nitori ti o ti mu ọpá-idabu ẹnu-bode rẹ le; o ti busi i fun awọn ọmọ rẹ ninu rẹ.
14O fi alafia ṣe àgbegbe rẹ, o si fi alikama didara-jù kún ọ.
15O rán aṣẹ rẹ̀ jade wá si aiye; ọ̀rọ rẹ̀ sure tete.
16O fi òjo-didì funni bi irun-agutan, o si fún ìri-didì ká bi ẽrú.
17O dà omi didì rẹ̀ bi òkele; tali o le duro niwaju otutu rẹ̀.
18O rán ọ̀rọ rẹ̀ jade, o si mu wọn yọ́; o mu afẹfẹ rẹ̀ fẹ, omi si nṣàn.
19O fi ọ̀rọ rẹ̀ hàn fun Jakobu, aṣẹ rẹ̀ ati idajọ rẹ̀ fun Israeli.
20Kò ba orilẹ-ède kan ṣe bẹ̃ ri; bi o si ṣe ti idajọ rẹ̀ ni, nwọn kò mọ̀ wọn. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

Currently Selected:

O. Daf 147: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in