YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 143

143
Adura Ìrànlọ́wọ́
1OLUWA, gbọ́ adura mi, fi eti si ẹ̀bẹ mi; ninu otitọ rẹ dá mi lohùn ati ninu ododo rẹ.
2Ki o má si ba ọmọ-ọdọ rẹ lọ sinu idajọ, nitori ti kò si ẹniti o wà lãye ti a o dalare niwaju rẹ.
3Nitori ti ọta ti ṣe inunibini si ọkàn mi; o ti lù ẹmi mi bolẹ; o ti mu mi joko li òkunkun, bi awọn ti o ti kú pẹ.
4Nitorina li ẹmi mi ṣe rẹ̀wẹsi ninu mi; òfo fò aiya mi ninu mi.
5Emi ranti ọjọ atijọ; emi ṣe àṣaro iṣẹ rẹ gbogbo, emi nronu iṣẹ ọwọ rẹ.
6Emi nà ọwọ mi si ọ; ongbẹ rẹ ngbẹ ọkàn mi bi ilẹ gbigbẹ.
7Oluwa, gbọ́ temi nisisiyi; o rẹ̀ ọkàn mi tan; máṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lara mi, ki emi ki o má bà dabi awọn ti o lọ sinu ihò.
8Mu mi gbọ́ iṣeun-ifẹ rẹ li owurọ; nitori iwọ ni mo gbẹkẹle: mu mi mọ̀ ọ̀na ti emi iba ma tọ̀; nitori mo gbé ọkàn mi soke si ọ.
9Oluwa, gbà mi lọwọ awọn ọta mi: ọdọ rẹ ni mo sa pamọ́ si.
10Kọ́ mi lati ṣe ohun ti o wù ọ: nitori iwọ li Ọlọrun mi: jẹ ki ẹmi rẹ didara fà mi lọ ni ilẹ ti o tẹju.
11Oluwa, sọ mi di ãye nitori orukọ rẹ: ninu ododo rẹ mu ọkàn mi jade ninu iṣẹ́.
12Ati ninu ãnu rẹ ke awọn ọta mi kuro, ki o si run gbogbo awọn ti nni ọkàn mi lara: nitori pe iranṣẹ rẹ li emi iṣe.

Currently Selected:

O. Daf 143: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in