YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 141

141
Adura Ààbò
1OLUWA, emi kigbe pè ọ: yara si ọdọ mi; fi eti si ohùn mi, nigbati mo ba nkepè ọ.
2Jẹ ki adura mi ki o wá si iwaju rẹ bi ẹbọ turari; ati igbé ọwọ mi soke bi ẹbọ aṣãlẹ.
3Oluwa, fi ẹṣọ́ siwaju ẹnu mi; pa ilẹkun ète mi mọ́.
4Máṣe fà aiya mi si ohun ibi kan, lati ma ba awọn ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ ṣiṣẹ buburu; má si jẹ ki emi ki o jẹ ninu ohun didùn wọn.
5Jẹ ki olododo ki o lù mi; iṣeun ni yio jasi: jẹ ki o si ba mi wi; ororo daradara ni yio jasi, ti kì yio fọ́ mi lori: sibẹ adura mi yio sa wà nitori jamba wọn.
6Nigbati a ba bì awọn onidajọ wọn ṣubu ni ibi okuta, nwọn o gbọ́ ọ̀rọ mi, nitori ti o dùn.
7Egungun wa tàn kalẹ li ẹnu isà-òkú, ẹniti o la aporo sori ilẹ.
8Ṣugbọn oju mi mbẹ lara rẹ; Ọlọrun Oluwa, lọdọ rẹ ni igbẹkẹle mi wà; máṣe tú ọkàn mi dà silẹ.
9Pa mi mọ́ kuro ninu okùn ti nwọn dẹ silẹ fun mi, ati ikẹkùn awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.
10Jẹ ki awọn enia buburu ki o bọ́ sinu àwọn ara wọn, nigbati emi ba kọja lọ.

Currently Selected:

O. Daf 141: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in