YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 138

138
Adura Ọpẹ́
1EMI o ma yìn ọ tinu-tinu mi gbogbo; niwaju awọn oriṣa li emi o ma kọrin iyìn si ọ.
2Emi o ma gbadura siha tempili mimọ́ rẹ, emi o si ma yìn orukọ rẹ nitori iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ; nitori iwọ gbé ọ̀rọ rẹ ga jù gbogbo orukọ rẹ lọ.
3Li ọjọ ti mo kepè, iwọ da mi lohùn, iwọ si fi ipa mu mi lara le li ọkàn mi.
4Gbogbo awọn ọba aiye yio yìn ọ, Oluwa, nigbati nwọn ba gbọ́ ọ̀rọ ẹnu rẹ.
5Nitõtọ, nwọn o ma kọrin ni ipa-ọ̀na Oluwa: nitori pe nla li ogo Oluwa.
6Bi Oluwa tilẹ ga, sibẹ o juba awọn onirẹlẹ; ṣugbọn agberaga li o mọ̀ li òkere rére.
7Bi emi tilẹ nrìn ninu ipọnju, iwọ ni yio sọ mi di ãye: iwọ o nà ọwọ rẹ si ibinu awọn ọta mi, ọwọ ọtún rẹ yio si gbà mi.
8Oluwa yio ṣe ohun ti iṣe ti emi li aṣepe: Oluwa, ãnu rẹ duro lailai: máṣe kọ̀ iṣẹ ọwọ ara rẹ silẹ.

Currently Selected:

O. Daf 138: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy