YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 102

102
Adura olupọnju, nigbati o ni ibinujẹ, ti o si tu aroye rẹ̀ jade niwaju Oluwa.
Adura Olùpọ́njú
1GBỌ adura mi, Oluwa, ki o si jẹ ki igbe mi ki o wá sọdọ rẹ.
2Máṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lara mi li ọjọ ti emi wà ninu ipọnju; dẹ eti rẹ si mi: li ọjọ ti mo ba pè, da mi lohùn-lọgan.
3Nitori ti ọjọ mi run bi ẹ̃fin, egungun mi si jona bi àro.
4Aiya mi lù, o si rọ bi koriko; tobẹ̃ ti mo gbagbe lati jẹ onjẹ mi.
5Nitori ohùn ikerora mi, egungun mi lẹ̀ mọ ẹran-ara mi.
6Emi dabi ẹiyẹ ofú ni iju: emi dabi owiwi ibi ahoro.
7Emi nṣọra, emi dabi ologoṣẹ nikan ni ori ile.
8Awọn ọta mi ngàn mi li ọjọ gbogbo; ati awọn ti nṣe ikanra si mi, nwọn fi mi bu.
9Emi sa jẹ ẽru bi onjẹ, emi si dà ohun mimu mi pọ̀ pẹlu omije.
10Nitori ikannu ati ibinu rẹ; nitori iwọ ti gbé mi soke, iwọ si gbé mi ṣanlẹ.
11Ọjọ mi dabi ojiji ti o nfà sẹhin; emi si nrọ bi koriko.
12Ṣugbọn iwọ, Oluwa, ni yio duro lailai; ati iranti rẹ lati iran dé iran.
13Iwọ o dide, iwọ o ṣãnu fun Sioni: nitori igba ati ṣe oju-rere si i, nitõtọ, àkoko na de.
14Nitori ti awọn iranṣẹ rẹ ṣe inu didùn si okuta rẹ̀, nwọn si kãnu erupẹ rẹ̀.
15Bẹ̃li awọn keferi yio ma bẹ̀ru orukọ Oluwa, ati gbogbo ọba aiye yio ma bẹ̀ru ogo rẹ.
16Nigbati Oluwa yio gbé Sioni ró, yio farahan ninu ogo rẹ̀.
17Yio juba adura awọn alaini, kì yio si gàn adura wọn.
18Eyi li a o kọ fun iran ti mbọ̀; ati awọn enia ti a o da yio ma yìn Oluwa.
19Nitori ti o wò ilẹ lati òke ibi-mimọ́ rẹ̀ wá; lati ọrun wá ni Oluwa bojuwo aiye;
20Lati gbọ́ irora ara-tubu; lati tú awọn ti a yàn si ikú silẹ;
21Lati sọ orukọ Oluwa ni Sioni, ati iyìn rẹ̀ ni Jerusalemu.
22Nigbati a kó awọn enia jọ pọ̀ ati awọn ijọba, lati ma sìn Oluwa.
23O rẹ̀ agbara mi silẹ li ọ̀na; o mu ọjọ mi kuru.
24Emi si wipe, Ọlọrun mi, máṣe mu mi kuro li agbedemeji ọjọ mi: lati irandiran li ọdun rẹ.
25Lati igba atijọ ni iwọ ti fi ipilẹ aiye sọlẹ: ọrun si ni iṣẹ ọwọ rẹ,
26Nwọn o ṣegbe, ṣugbọn Iwọ o duro; nitõtọ gbogbo wọn ni yio di ogbó bi aṣọ; bi ẹ̀wu ni iwọ o pàrọ wọn, nwọn o si pàrọ.
27Ṣugbọn bakanna ni Iwọ, ọdun rẹ kò li opin.
28Awọn ọmọ awọn iranṣẹ rẹ yio duro pẹ, a o si fi ẹsẹ iru-ọmọ wọn mulẹ niwaju rẹ.

Currently Selected:

O. Daf 102: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in