YouVersion Logo
Search Icon

Owe 15

15
1IDAHÙN pẹlẹ yi ibinu pada; ṣugbọn ọ̀rọ lile ni irú ibinu soke.
2Ahọn ọlọgbọ́n nlò ìmọ rere: ṣugbọn ẹnu aṣiwère a ma gufẹ wère.
3Oju Oluwa mbẹ ni ibi gbogbo, o nwò awọn ẹni-buburu ati ẹni-rere.
4Ahọn imularada ni igi ìye: ṣugbọn ayidayida ninu rẹ̀ ni ibajẹ ọkàn.
5Aṣiwère gàn ẹkọ́ baba rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba feti si ibawi li o moye.
6Ni ile olododo li ọ̀pọlọpọ iṣura: ṣugbọn ninu òwò enia buburu ni iyọnu.
7Ete ọlọgbọ́n tan ìmọ kalẹ: ṣugbọn aiya aṣiwère kì iṣe bẹ̃.
8Ẹbọ awọn enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn adura awọn aduroṣinṣin ni didùn-inu rẹ̀.
9Ọ̀na enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn o fẹ ẹniti ntọ̀ ododo lẹhin.
10Ikilọ kikan wà fun ẹniti o kọ̀ ọ̀na silẹ; ẹniti o ba si korira ibawi yio kú.
11Ipo-okú ati iparun ṣi silẹ niwaju Oluwa; njẹ melomelo li aiya awọn ọmọ enia.
12Ẹlẹgàn kò fẹ ẹniti mba a wi; bẹ̃ni kì yio tọ̀ awọn ọlọgbọ́n lọ.
13Inu-didùn a mu oju daraya; ṣugbọn nipa ibinujẹ aiya, ọkàn a rẹ̀wẹsi.
14Aiya ẹniti oye ye nṣe afẹri ìmọ; ṣugbọn ẹnu aṣiwère nfi wère bọ́ ara rẹ̀.
15Gbogbo ọjọ olupọnju ni ibi; ṣugbọn oninu-didùn njẹ alafia nigbagbogbo.
16Diẹ pẹlu ibẹ̀ru Oluwa, o san jù iṣura pupọ ti on ti iyọnu ninu rẹ̀.
17Onjẹ ewebẹ̀ nibiti ifẹ wà, o san jù abọpa malu lọ ati irira pẹlu rẹ̀.
18Abinu enia rú asọ̀ soke; ṣugbọn ẹniti o lọra ati binu, o tù ìja ninu.
19Ọna ọlẹ dabi igbo ẹgún; ṣugbọn ọ̀na olododo já gẽrege ni.
20Ọlọgbọ́n ọmọ ṣe ayọ̀ baba; ṣugbọn aṣiwère enia gàn iya rẹ̀.
21Ayọ̀ ni wère fun ẹniti oye kù fun; ṣugbọn ẹni-oye a ma rìn ni iduroṣinṣin.
22Laisi ìgbimọ, èro a dasan; ṣugbọn li ọ̀pọlọpọ ìgbimọ, nwọn a fi idi mulẹ.
23Enia ni ayọ̀ nipa idahùn ẹnu rẹ̀; ati ọ̀rọ kan li akoko rẹ̀, o ti wọ̀ to?
24Ọ̀na ìye lọ soke fun ọlọgbọ́n, ki o le kuro ni ipo-okú nisalẹ.
25Oluwa yio run ile agberaga; ṣugbọn yio fi ìpãlà opó kalẹ.
26Ìro inu enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn mimọ́ ni ọ̀rọ didùn niwaju rẹ̀.
27Ẹniti o njẹ ère aiṣododo, o nyọ ile ara rẹ̀ lẹnu; ṣugbọn ẹniti o korira ẹ̀bun yio yè.
28Aiya olododo ṣe àṣaro lati dahùn; ṣugbọn ẹnu enia buburu ngufẹ ohun ibi jade.
29Oluwa jina si awọn enia-buburu; ṣugbọn o gbọ́ adura awọn olododo.
30Imọlẹ oju mu inu dùn; ihin rere si mu egungun sanra.
31Ẹniti o ba gbọ́ ibawi ìye, a joko lãrin awọn ọlọgbọ́n.
32Ẹniti o kọ̀ ẹkọ́, o gàn ọkàn ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba gbọ́ ibawi, o ni imoye.
33Ibẹ̀ru Oluwa li ẹkọ́ ọgbọ́n; ati ṣãju ọlá ni irẹlẹ.

Currently Selected:

Owe 15: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in