YouVersion Logo
Search Icon

Filp 2:6-11

Filp 2:6-11 YBCV

Ẹniti o tilẹ jẹ aworan Ọlọrun, ti kò ka a si iwọra lati ba Ọlọrun dọgba: Ṣugbọn o bọ́ ogo rẹ̀ silẹ, o si mu awọ̀ iranṣẹ, a si ṣe e ni awòran enia. Nigbati a si ti ri i ni ìri enia, o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, o si tẹriba titi di oju ikú, ani ikú ori agbelebu. Nitorina Ọlọrun pẹlu si ti gbé e ga gidigidi, o si ti fi orukọ kan fun u ti o bori gbogbo orukọ: Pe, li orukọ Jesu ni ki gbogbo ẽkun ki o mã kunlẹ, awọn ẹniti mbẹ li ọrun, ati awọn ẹniti mbẹ ni ilẹ, ati awọn ẹniti mbẹ nisalẹ ilẹ; Ati pe ki gbogbo ahọn ki o mã jẹwọ pe, Jesu Kristi ni Oluwa, fun ogo Ọlọrun Baba.