YouVersion Logo
Search Icon

Num 4

4
Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi — Ìdílé Kohati
1OLUWA si sọ fun Mose ati Aaroni pe,
2Kà iye awọn ọmọ Kohati kuro ninu awọn ọmọ Lefi, nipa idile wọn, ile baba wọn,
3Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin, lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ.
4Eyi ni yio ṣe iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Kohati ninu agọ́ ajọ, niti ohun mimọ́ julọ wọnni:
5Nigbati ibudó ba si ṣí siwaju, Aaroni o wá, ati awọn ọmọ rẹ̀, nwọn o si bọ́ aṣọ-ikele rẹ̀ silẹ, nwọn o si fi i bò apoti ẹrí;
6Nwọn o fi awọ seali bò o, nwọn o si nà aṣọ kìki alaró bò o, nwọn o si tẹ̀ ọpá nì bọ̀ ọ.
7Ati lori tabili àkara ifihàn nì, ki nwọn ki o nà aṣọ alaró kan si, ki nwọn ki o si fi awopọkọ sori rẹ̀, ati ṣibi ati awokòto, ati ìgo ohun didà: ati àkara ìgbagbogbo nì ki o wà lori rẹ̀:
8Ki nwọn ki o si nà aṣọ ododó bò wọn, ki nwọn ki o si fi awọ seali bò o, ki nwọn ki o si tẹ̀ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ.
9Ki nwọn ki o si mú aṣọ alaró kan, ki nwọn ki o si fi bò ọpá-fitila nì, ati fitila rẹ̀, ati alumagaji rẹ̀, ati awo alumagaji rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo oróro rẹ̀, eyiti nwọn fi nṣe iṣẹ rẹ̀.
10Ki nwọn ki o si fi on ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀ sinu awọ seali, ki nwọn ki o si gbé e lé ori igi.
11Ati lori pẹpẹ wurà ni ki nwọn ki o nà aṣọ alaró kan si, nwọn o si fi awọ seali bò o, nwọn o si tẹ̀ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ.
12Ki nwọn ki o si kó gbogbo ohunèlo ìsin, ti nwọn fi nṣe iṣẹ-ìsin ninu ibi-mimọ́, ki nwọn ki o si fi wọn sinu aṣọ alaró kan, ki nwọn ki o si fi awọ seali bò wọn, ki nwon ki o si fi wọn kà ori igi.
13Ki nwọn ki o si kó ẽru kuro lori pẹpẹ, ki nwọn ki o si nà aṣọ elesè-aluko kan bò o.
14Ki nwọn ki o si fi gbogbo ohun-èlo rẹ̀ ti nwọn fi ṣe iṣẹ-ìsin rẹ̀ sori rẹ̀, awo iná, ati kọkọrọ ẹran, ati ọkọ́-ẽru, ati awokòto, ati gbogbo ohun-èlo pẹpẹ na; ki nwọn ki o si nà awọ seali sori rẹ̀, ki nwọn ki o si tẹ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ.
15Nigbati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ba pari ati bò ibi-mimọ́ na tán, ati gbogbo ohun-èlo ibi-mimọ́ na, nigbati ibudó yio ba ṣí siwaju; lẹhin eyinì, li awọn ọmọ Kohati yio wá lati gbé e: ṣugbọn nwọn kò gbọdọ fọwọkàn ohun mimọ́ kan, ki nwọn ki o má ba kú. Wọnyi li ẹrù awọn ọmọ Kohati ninu agọ́ ajọ.
16Ohun itọju Eleasari ọmọ Aaroni alufa si ni oróro fitila, ati turari didùn, ati ẹbọ ohunjijẹ ìgbagbogbo, ati oróro itasori, ati itọju agọ́ na gbogbo, ati ti ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, ninu ibi-mimọ́ nì, ati ohun-èlo rẹ̀ na.
17OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,
18Ẹ máṣe ke ẹ̀ya idile awọn ọmọ Kohati kuro lãrin awọn ọmọ Lefi:
19Ṣugbọn bayi ni ki ẹ ṣe fun wọn, ki nwọn ki o le yè, ki nwọn ki o má ba kú, nigbati nwọn ba sunmọ ohun mimọ́ julọ: ki Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wọnú ilé, ki nwọn si yàn wọn olukuluku si iṣẹ rẹ̀ ati si ẹrù rẹ̀;
20Ṣugbọn nwọn kò gbọdọ wọle lọ lati wò ohun mimọ́ ni iṣẹju kan, ki nwọn ki o má ba kú.
Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi — Ìdílé Geriṣoni
21OLUWA si sọ fun Mose pe,
22Kà iye awọn ọmọ Gerṣoni pẹlu, gẹgẹ bi ile baba wọn, nipa idile wọn;
23Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ titi di ẹni ãdọta ọdún ni ki o kaye wọn; gbogbo awọn ti o wọnu-ile lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin, lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ.
24Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Gerṣoni, lati sìn ati lati rù ẹrù:
25Awọn ni yio si ma rù aṣọ-ikele agọ́, ati agọ́ ajọ, ibori rẹ̀, ati ibori awọ seali ti mbẹ lori rẹ̀, ati aṣọ-tita fun ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ;
26Ati aṣọ-isorọ̀ ti agbalá, ati aṣọ-tita fun ẹnu-ọ̀na agbalá, ti mbẹ lẹba agọ́ ati lẹba pẹpẹ yiká, ati okùn wọn, ati gbogbo ohun-èlo iṣẹ-ìsin wọn, ati ohun gbogbo ti a ṣe fun wọn; bẹ̃ni nwọn o ma sìn.
27Nipa aṣẹ Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀ ni ki gbogbo iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Gerṣoni jẹ́, ni gbogbo ẹrù wọn, ati ni gbogbo iṣẹ-ìsin wọn: ki ẹnyin si yàn wọn si itọju gbogbo ẹrù wọn.
28Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Gerṣoni ninu agọ́ ajọ: ki itọju wọn ki o si wà li ọwọ́ Itamari ọmọ Aaroni alufa.
Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi — Ìdílé Merari
29Ati awọn ọmọ Merari, ki iwọ ki o kà wọn gẹgẹ bi idile wọn, nipa ile baba wọn;
30Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún ni ki iwọ ki o kà wọn, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ́.
31Eyi si ni itọju ẹrù wọn, gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ-ìsin wọn ninu agọ́ ajo; awọn apáko agọ́, ati ọpá-idabu rẹ̀, ati opó rẹ̀, ati ìhò-ìtẹbọ rẹ̀,
32Ati opó agbalá yiká, ati ihò-ìtẹbọ wọn, ati ẽkàn wọn, ati okùn wọn, pẹlu ohun-èlo wọn gbogbo, ati pẹlu ohun-ìsin wọn gbogbo: li orukọ li orukọ ni ki ẹnyin ki o kà ohun-èlo ti iṣe itọju ẹrù wọn.
33Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Merari, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn gbogbo, ninu agọ́ ajọ, labẹ Itamari ọmọ Aaroni alufa.
Iye Àwọn Ọmọ Lefi
34Mose ati Aaroni ati awọn olori ijọ awọn enia si kà awọn ọmọ Kohati nipa idile wọn, ati gẹgẹ bi ile baba wọn,
35Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na fun iṣẹ ninu agọ́ ajọ:
36Awọn ti a si kà ninu wọn nipa idile wọn jẹ́ ẹgbẹrinla o din ãdọta.
37Wọnyi li awọn ti a kà ni idile awọn ọmọ Kohati, gbogbo awọn ti o le ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ, ti Mose ati Aaroni kà, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nipa ọwọ́ Mose.
38Awọn ti a si kà ninu awọn ọmọ Gerṣoni, nipa idile wọn, ati gẹgẹ bi ile baba wọn,
39Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na, fun iṣẹ ninu agọ́ ajọ,
40Ani awọn ti a kà ninu wọn, nipa idile wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn, jẹ́ ẹgbẹtala o le ọgbọ̀n.
41Wọnyi li awọn ti a kà ni idile awọn ọmọ Gerṣoni, gbogbo awọn ti o ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ, ti Mose ati Aaroni kà gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA.
42Awọn ti a si kà ni idile awọn ọmọ Merari, nipa idile wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn,
43Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na, fun iṣẹ ninu agọ́ ajọ,
44Ani awọn ti a kà ninu wọn nipa idile wọn jẹ́ ẹgbẹrindilogun.
45Wọnyi li awọn ti a kà ninu idile awọn ọmọ Merari, ti Mose ati Aaroni kà gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nipa ọwọ́ Mose.
46Gbogbo awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Lefi, ti Mose ati Aaroni ati awọn olori Israeli kà, nipa idile wọn, ati gẹgẹ bi ile baba wọn,
47Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wá lati ṣe iṣẹ-ìsin, ati iṣẹ ẹrù ninu agọ́ ajọ,
48Ani awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgbẹtalelẹgbarin o din ogun.
49Gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA li a kà wọn nipa ọwọ́ Mose, olukuluku nipa iṣẹ-ìsin rẹ̀, ati gẹgẹ bi ẹrù rẹ̀: bẹ̃li a ti ọwọ́ rẹ̀ kà wọn, bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

Currently Selected:

Num 4: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in