YouVersion Logo
Search Icon

Num 34

34
Àwọn Ààlà Ilẹ̀ náà
1OLUWA si sọ fun Mose pe,
2Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ Kenaani, (eyi ni ilẹ ti yio bọ́ si nyin lọwọ ni iní, ani ilẹ Kenaani gẹgẹ bi àgbegbe rẹ̀,)
3Njẹ ki ìha gusù nyin ki o jẹ́ ati aginjù Sini lọ titi dé ẹba Edomu, ati opinlẹ gusù nyin ki o jẹ́ lati opin Okun Iyọ̀ si ìha ìla-õrùn:
4Ki opinlẹ nyin ki o si yí lati gusù wá si ìgoke Akrabbimu, ki o si kọja lọ si Sini: ati ijadelọ rẹ̀ ki o jẹ́ ati gusù lọ si Kadeṣi-barnea, ki o si dé Hasari-addari, ki o si kọja si Asmoni:
5Ki opinlẹ rẹ̀ ki o si yiká lati Asmoni lọ dé odò Egipti, okun ni yio si jẹ́ opin rẹ̀.
6Ati opinlẹ ìha ìwọ-õrùn, ani okun nla ni yio jẹ́ opin fun nyin: eyi ni yio jẹ́ opinlẹ ìha ìwọ-õrùn fun nyin.
7Eyi ni yio si jẹ́ opinlẹ ìha ariwa fun nyin: lati okun nla lọ ki ẹnyin ki o fi ori sọ òke Hori:
8Lati òke Hori lọ ki ẹnyin ki o fi ori sọ ati wọ̀ Hamati; ijadelọ opinlẹ na yio si jẹ́ Sedadi:
9Opinlẹ rẹ yio si dé Sifroni, ati ijadelọ rẹ̀ yio dé Hasari-enani: eyi ni yio jẹ́ opinlẹ ìha ariwa nyin.
10Ki ẹnyin ki o si sàmi si opinlẹ nyin ni ìha ìla-õrùn lati Hasari-enani lọ dé Ṣefamu:
11Ki opinlẹ na ki o si ti Ṣefamu sọkalẹ lọ si Ribla, ni ìha ìla-õrùn Aini; ki opinlẹ na ki o si sọkalẹ lọ, ki o si dé ìha okun Kinnereti ni ìha ìla-õrùn.
12Ki opinlẹ na ki o si sọkalẹ lọ si Jordani, ijadelọ rẹ̀ yio jẹ Okun Iyọ̀: eyi ni yio jẹ́ ilẹ nyin gẹgẹ bi àgbegbe rẹ̀ yiká kiri.
13Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, wipe, Eyi ni ilẹ na ti ẹnyin o fi keké gbà ni iní, ti OLUWA paṣẹ lati fi fun ẹ̀ya mẹsan, ati àbọ ẹ̀ya nì:
14Fun ẹ̀ya awọn ọmọ Reubeni gẹgẹ bi ile baba wọn, ati ẹ̀ya awọn ọmọ Gadi gẹgẹ bi ile baba wọn ti gbà; àbọ ẹ̀ya Manasse si ti gbà, ipín wọn:
15Ẹ̀ya mejẽji ati àbọ ẹ̀ya nì ti gbà ipín wọn ni ìha ihin Jordani leti Jeriko, ni ìha gabasi, ni ìha ìla-õrùn.
Àwọn Olórí tí Yóo Pín Ilẹ̀ náà
16OLUWA si sọ fun Mose pe,
17Wọnyi li orukọ awọn ọkunrin ti yio pín ilẹ na fun nyin: Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni.
18Ki ẹnyin ki o si mú olori kan ninu ẹ̀ya kọkan, lati pín ilẹ na ni iní.
19Orukọ awọn ọkunrin na si ni wọnyi: ni ẹ̀ya Juda, Kalebu ọmọ Jefunne.
20Ati ni ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni, Ṣemueli ọmọ Ammihudu.
21Ni ẹ̀ya Benjamini, Elidadi ọmọ Kisloni.
22Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Dani, Bukki ọmọ Jogli.
23Olori awọn ọmọ Josefu: ni ẹ̀ya awọn ọmọ Manasse, Hannieli ọmọ Efodu:
24Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Efraimu, Kemueli ọmọ Ṣiftani.
25Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Sebuluni, Elisafani ọmọ Parnaki.
26Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Issakari, Paltieli ọmọ Assani.
27Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri, Ahihudu ọmọ Ṣelomi.
28Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Naftali, Pedaheli ọmọ Ammihudu.
29Awọn wọnyi li ẹniti OLUWA paṣẹ fun lati pín iní na fun awọn ọmọ Israeli ni ilẹ Kenaani.

Currently Selected:

Num 34: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in