YouVersion Logo
Search Icon

Neh 7

7
1O SI ṣe, nigbati a mọ odi na tan, ti mo si gbe ilẹkùn ro, ti a si yan awọn oludena ati awọn akọrin, ati awọn ọmọ Lefi,
2Mo si fun Hanani arakunrin mi, ati Hananiah ijòye ãfin, li aṣẹ lori Jerusalemu: nitori olododo enia li o ṣe, o si bẹ̀ru Ọlọrun jù enia pupọ lọ.
3Mo si wi fun wọn pe, Ẹ má jẹ ki ilẹkùn odi Jerusalemu ṣi titi õrùn o fi mú; bi nwọn si ti duro, jẹ ki wọn se ilẹkùn, ki nwọn si há wọn, ki nwọn si yan ẹ̀ṣọ ninu awọn ti ngbe Jerusalemu, olukuluku ninu iṣọ rẹ̀, ati olukuluku ninu ile rẹ̀.
Orúkọ Àwọn tí Wọ́n Pada láti Oko Ẹrú
(Esr 2:1-70)
4Ṣugbọn ilu na gbõrò, o si tobi, awọn enia inu rẹ̀ si kere, a kò si kọ́ ile tan.
5Ọlọrun mi si fi si mi li ọkàn lati ko awọn ijòye jọ, ati awọn olori, ati awọn enia, ki a le kà wọn nipa idile wọn. Mo si ri iwe idile awọn ti o kọ́ goke wá, mo ri pe, a kọ ọ sinu rẹ̀.
6Wọnyi ni awọn ọmọ igberiko, ti o gòke wá lati ìgbekun ninu awọn ti a ti ko lọ, ti Nebukadnesari ọba Babiloni ti ko lọ, ti nwọn tun padà wá si Jerusalemu, ati si Juda, olukuluku si ilu rẹ̀.
7Awọn ti o ba Serubbabeli wá, Jeṣua, Nehemia, Asariah, Raamiah, Nahamani, Mordikai, Bilṣani, Mispereti, Bigfai, Nehumu, Baana. Iye awọn ọkunrin enia Israeli li eyi;
8Awọn ọmọ Paroṣi, ẹgbã o le mejilelãdọsan.
9Awọn ọmọ Ṣefatiah, ojidinirinwo o le mejila.
10Awọn ọmọ Ara, adọtalelẹgbẹta o le meji.
11Awọn ọmọ Pahat-moabu, ti awọn ọmọ Jeṣua, ati Joabu, ẹgbẹrinla o le mejidilogun.
12Awọn ọmọ Elamu, ẹgbẹfa o le mẹrinlelãdọta.
13Awọn ọmọ Sattu, ojilelẹgbẹrin o le marun.
14Awọn ọmọ Sakkai, ojidilẹgbẹrin.
15Awọn ọmọ Binnui, ojilelẹgbẹta o le mẹjọ.
16Awọn ọmọ Bebai, ẹgbẹta o le mejidilọgbọn.
17Awọn ọmọ Asgadi, egbejila o di mejidilọgọrin.
18Awọn ọmọ Adonikamu ọtalelẹgbẹta o le meje.
19Awọn ọmọ Bigfai, ẹgbã o le mẹtadilãdọrin.
20Awọn ọmọ Adini, ãdọtalelẹgbẹta o le marun.
21Awọn ọmọ Ateri, ti Hesekiah mejidilọgọrun.
22Awọn ọmọ Haṣamu, ọrindinirinwo o le mẹjọ.
23Awọn ọmọ Besai, ọrindinirinwo o le mẹrin.
24Awọn ọmọ Harifu mejilelãdọfa.
25Awọn ọmọ Gibioni, marundilọgọrun.
26Awọn ọkunrin Betlehemu ati Netofa, ọgọsan o le mẹjọ.
27Awọn ọkunrin Anatoti, mejidilãdoje.
28Awọn ọkunrin Bet-asmafeti, mejilelogoji.
29Awọn ọkunrin Kiriat-jearimu, Kefira, ati Beeroti, ọtadilẹgbẹrin o le mẹta,
30Awọn ọkunrin Rama ati Gaba, ẹgbẹta o le mọkanlelogun.
31Awọn ọkunrin Mikmasi, mejilelọgọfa.
32Awọn ọkunrin Beteli ati Ai, mẹtalelọgọfa.
33Awọn ọkunrin Nebo miran mejilelãdọta.
34Awọn ọmọ Elamu miran ẹgbẹfa o le mẹrinlelãdọta.
35Awọn ọmọ Harimu, ọrindinirinwo.
36Awọn ọmọ Jeriko, ọtadinirinwo o le marun.
37Awọn ọmọ Lodi, Hadidi, ati Ono, ọrindilẹgbẹrin o le ọkan.
38Awọn ọmọ Senaah ẹgbãji o di ãdọrin.
39Awọn alufa: awọn ọmọ Jedaiah ti ile Jeṣua, ẹgbã o di mẹtadilọgbọn.
40Awọn ọmọ Immeri, ẹgbẹrun o le mejilelãdọta.
41Awọn ọmọ Paṣuri, ẹgbẹfa o le mẹtadiladọta.
42Awọn ọmọ Harimu ẹgbẹrun o le mẹtadilogun.
43Awọn ọmọ Lefi: awọn ọmọ Jeṣua, ti Kadmieli, ninu ọmọ Hodafa, mẹrinlelãdọrin.
44Awọn akọrin: awọn ọmọ Asafu, mejidilãdọjọ.
45Awọn oludena: awọn ọmọ Ṣallumu, awọn ọmọ Ateri, awọn ọmọ Talmoni, awọn ọmọ Akkubu, awọn ọmọ Hatita, awọn ọmọ Ṣobai, mejidilogoje.
46Awọn ọmọ Netinimu: awọn ọmọ Siha, awọn ọmọ Haṣufa, awọn ọmọ Tabbaoti,
47Awọn ọmọ Kerosi, awọn ọmọ Sia, awọn ọmọ Padoni,
48Awọn ọmọ Lebana, awọn ọmọ Hagaba, awọn ọmọ Salmai,
49Awọn ọmọ Hanani, awọn ọmọ Giddeli, awọn ọmọ Gahari,
50Awọn ọmọ Reaiah, awọn ọmọ Resini, awọn ọmọ Nekoda,
51Awọn ọmọ Gassamu, awọn ọmọ Ussa, awọn ọmọ Fasea,
52Awọn ọmọ Besai, awọn ọmọ Meunimu, awọn ọmọ Nefiṣesimu,
53Awọn ọmọ Bakbuku, awọn ọmọ Hakufa, awọn ọmọ Harhuri,
54Awọn ọmọ Basliti, awọn ọmọ Mehida, awọn ọmọ Harsa,
55Awọn ọmọ Barkosi, awọn ọmọ Sisera, awọn ọmọ Tama,
56Awọn ọmọ Nesia, awọn ọmọ Hatifa.
57Awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni: awọn ọmọ Sotai, awọn ọmọ Sofereti, awọn ọmọ Perida,
58Awọn ọmọ Jaala, awọn ọmọ Darkoni, awọn ọmọ Giddeli,
59Awọn ọmọ Ṣefatiah, awọn ọmọ Hattili, awọn ọmọ Pokereti ti Sebaimu, awọn ọmọ Amoni.
60Gbogbo awọn Netinimu, ati awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni jẹ irinwo din mẹjọ.
61Awọn wọnyi li o si goke lati Telhariṣa, Kerubu, Addoni, ati Immeri wá: ṣugbọn nwọn kò le fi ile baba wọn hàn, tabi iran wọn, bi nwọn iṣe ti Israeli.
62Awọn ọmọ Delaiah, awọn ọmọ Tobiah, awọn ọmọ Nekoda, ojilelẹgbẹta ole meji.
63Ati ninu awọn alufa: awọn ọmọ Habaiah, awọn ọmọ Kosi, awọn ọmọ Barsillai, ti o ni ọkan ninu awọn ọmọbinrin Barsillai, ara Gileadi, li aya, a si npè e nipa orukọ wọn.
64Awọn wọnyi wá iwe orukọ wọn ninu awọn wọnyi ti a kọ orukọ wọn nipa idile ṣugbọn a kò ri i: nitorina li a ṣe yà wọn kurò ninu oyè alufa.
65Bãlẹ na si wi fun wọn pe, ki nwọn máṣe jẹ ninu ohun mimọ́ julọ, titi alufa kan yio fi duro pẹlu Urimu, ati Tummimu,
66Iye gbogbo ijọ jasi ẹgbãmọkanlelogun o le ojidinirinwo.
67Laikà awọn iranṣẹkunrin wọn ati iranṣẹ-binrin wọn, iye wọn jẹ ẹgbẹtadilẹgbãrin o di ẹtalelọgọta: nwọn si ni ojilugba o le marun akọni ọkunrin ati akọni obinrin.
68Ẹṣin wọn jẹ ọtadilẹgbẹrin o di mẹrin: ibaka nwọn jẹ ojilugba o le marun:
69Rakumi jẹ ojilenirinwo o di marun: kẹtẹkẹtẹ jẹ ẹgbẹrinlelọgbọn o di ọgọrin.
70Omiran ninu awọn olori ninu awọn baba fi nkan si iṣẹ na. Bãlẹ fi ẹgbẹrun dramu wura, ãdọta awokoto, ọrindilẹgbẹta le mẹwa ẹwu alufa sinu iṣura na.
71Ninu awọn olori ninu awọn baba fi ọkẹ meji dramu wura, ati ẹgbọkanla mina fadaka si iṣura iṣẹ na.
72Ati eyiti awọn enia iyokù mu wá jẹ ọkẹ meji dramu wura, ati ẹgbã mina fadaka, ati ẹwu alufa mẹtadilãdọrin.
73Bẹ̃ni awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati awọn oludena, ati awọn akọrin, ati ninu awọn enia, ati awọn Netinimu, ati gbogbo Israeli, ngbe ilu wọn; nigbati oṣu keje si pé, awọn ọmọ Israeli wà ni ilu wọn.

Currently Selected:

Neh 7: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in