Mak 3
3
Ọkunrin Tí Ọwọ́ Rẹ̀ Rọ
(Mat 12:9-14; Luk 6:6-11)
1O si tún wọ̀ inu sinagogu lọ; ọkunrin kan si mbẹ nibẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ kan rọ.
2Nwọn si nṣọ ọ, bi yio mu u larada li ọjọ isimi; ki nwọn ki o le fi i sùn.
3O si wi fun ọkunrin na ti ọwọ́ rẹ̀ rọ pe, Dide, duro larin.
4O si wi fun wọn pe, O tọ́ lati mã ṣe rere li ọjọ isimi, tabi lati mã ṣe buburu? lati gbà ẹmí là, tabi lati pa a run? Nwọn si dakẹ.
5Nigbati o si fi ibinu wò gbogbo wọn yiká, ti inu rẹ̀ bajẹ nitori lile àiya wọn, o wi fun ọkunrin na pe, Nà ọwọ́ rẹ. O si nà a: ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò gẹgẹ bi ekeji.
6Awọn Farisi jade lọ lojukanna lati ba awọn ọmọ-ẹhin Herodu gbìmọ pọ̀ si i, bi awọn iba ti ṣe pa a.
Ọpọlọpọ Eniyan Lẹ́bàá Òkun
7Jesu pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si kuro nibẹ̀ lọ si eti okun: ijọ enia pipọ lati Galili ati Judea wá si tọ̀ ọ lẹhin,
8Ati lati Jerusalemu, ati lati Idumea, ati lati oke odò Jordani, ati awọn ti o wà niha Tire on Sidoni, ijọ enia pipọ; nigbati nwọn gbọ́ ohun nla ti o ṣe, nwọn tọ̀ ọ wá.
9O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, ki nwọn mu ọkọ̀ kekere kan sunmọ on, nitori ijọ enia, ki nwọn ki o má bà bilù u.
10Nitoriti o mu ọ̀pọ enia larada; tobẹ̃ ti nwọn mbì ara wọn lù u lati fi ọwọ́ kàn a, iye awọn ti o li arùn.
11Ati awọn ẹmi aimọ́, nigbàkugba ti nwọn ba ri i, nwọn a wolẹ niwaju rẹ̀, nwọn a kigbe soke, wipe, Iwọ li Ọmọ Ọlọrun.
12O si kìlọ fun wọn gidigidi pe, ki nwọn ki o máṣe fi on hàn.
13O si gùn ori òke lọ, o si npè ẹnikẹni ti o fẹ sọdọ rẹ̀: nwọn si tọ̀ ọ wá.
14O si yàn awọn mejila, ki nwọn ki o le mã gbé ọdọ rẹ̀, ati ki o le ma rán wọn lọ lati wasu,
15Ati lati li agbara lati wò arunkarun san, ati lati lé awọn ẹmi èṣu jade:
16Simoni ẹniti o si sọ apele rẹ̀ ni Peteru;
17Ati Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin Jakọbu; o si sọ apele wọn ni Boanerge, eyi ti ijẹ Awọn ọmọ ãrá:
18Ati Anderu, ati Filippi, ati Bartolomeu, ati Matiu, ati Tomasi, ati Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Taddeu, ati Simoni ti a npè ni Selote,
19Ati Judasi Iskariotu, ẹniti o si fi i hàn pẹlu: nwọn si wọ̀ ile kan lọ.
Jesu ati Beelisebulu
(Mat 12:22-32; Luk 11:14-23; 12:10)
20Ijọ enia si tún wọjọ pọ̀, ani tobẹ̃ ti nwọn ko tilẹ le jẹ onjẹ.
21Nigbati awọn ibatan rẹ̀ si gbọ́ eyini, nwọn jade lọ lati mu u: nitoriti nwọn wipe, Ori rẹ̀ bajẹ.
22Awọn akọwe ti o ti Jerusalemu sọkalẹ wá, wipe, O ni Beelsebubu, olori awọn ẹmi èṣu li o si fi nlé awọn ẹmi èṣu jade.
23O si pè wọn sọdọ rẹ̀, o si fi owe ba wọn sọrọ pe, Satani yio ti ṣe le lé Satani jade?
24 Bi ijọba kan ba si yàpa si ara rẹ̀, ijọba na kì yio le duro.
25 Bi ile kan ba si yàpa si ara rẹ̀, ile na kì yio le duro.
26 Bi Satani ba si dide si ara rẹ̀, ti o si yàpa, on kì yio le duro, ṣugbọn yio ni opin.
27 Kò si ẹniti o le wọ̀ ile ọkunrin alagbara kan lọ, ki o si kó o li ẹrù lọ, bikoṣepe o tètekọ dè ọkunrin alagbara na li okùn; nigbana ni yio le kó o li ẹrù ni ile.
28 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Gbogbo ẹ̀ṣẹ li a o dari wọn jì awọn ọmọ enia, ati gbogbo ọrọ-odi nipa eyiti nwọn o ma fi sọrọ-odi:
29 Ṣugbọn ẹniti o ba sọrọ-odi si Ẹmi Mimọ́ kì yio ni idariji titi lai, ṣugbọn o wà ninu ewu ẹbi ainipẹkun:
30Nitoriti nwọn wipe, O li ẹmi aimọ́.
Àwọn Ta ni Ẹbí Jesu?
(Mat 12:46-50; Luk 8:19-21)
31Nigbana li awọn arakunrin rẹ̀ ati iya rẹ̀ wá, nwọn duro lode, nwọn si ranṣẹ si i, nwọn npè e.
32Awọn ọ̀pọ enia si joko lọdọ rẹ̀, nwọn si wi fun u pe, Wò o, iya rẹ ati awọn arakunrin rẹ nwá ọ lode.
33O si da wọn lohùn, wipe, Tani iṣe iya mi, tabi awọn arakunrin mi?
34O si wò gbogbo awọn ti o joko lọdọ rẹ̀ yiká, o si wipe, Wò iya mi ati awọn arakunrin mi:
35 Nitori ẹnikẹni ti o ba ṣe ifẹ Ọlọrun, on na li arakunrin mi, ati arabinrin mi, ati iya mi.
Currently Selected:
Mak 3: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.