Mat 5:3-12
Mat 5:3-12 YBCV
Alabukún-fun li awọn òtoṣi li ẹmí: nitori tiwọn ni ijọba ọrun. Alabukún-fun li awọn ẹniti nkãnu: nitoriti a ó tù wọn ninu. Alabukún-fun li awọn ọlọkàn-tutù: nitori nwọn o jogún aiye. Alabukún-fun li awọn ẹniti ebi npa ati ti ongbẹ ngbẹ sipa ododo: nitori nwọn ó yo. Alabukún-fun li awọn alãnu: nitori nwọn ó ri ãnu gbà. Alabukún-fun li awọn oninu-funfun: nitori nwọn ó ri Ọlọrun. Alabukún-fun li awọn onilaja: nitori ọmọ Ọlọrun ni a ó ma pè wọn. Alabukúnfun li awọn ẹniti a ṣe inunibini si nitori ododo: nitori tiwọn ni ijọba ọrun. Alabukún-fun li ẹnyin, nigbati nwọn ba nkẹgan nyin, ti nwọn ba nṣe inunibini si nyin, ti nwọn ba nfi eke sọ̀rọ buburu gbogbo si nyin nitori emi. Ẹ mã yọ̀, ki ẹnyin ki o si fò fun ayọ̀: nitori ère nyin pọ̀ li ọrun: bẹ̃ni nwọn sá ṣe inunibini si awọn wolĩ ti o ti mbẹ ṣaju nyin.