Mat 16
16
Àwọn Juu ń Fẹ́ Àmì
(Mak 8:11-13; Luk 12:54-56)
1AWỌN Farisi pẹlu awọn Sadusi si wá, nwọn ndán a wò, nwọn si nfẹ ki o fi àmi hàn fun wọn lati ọrun wá.
2Ṣugbọn o dahùn o si wi fun wọn pe, Nigbati ó ba di aṣalẹ, ẹnyin a wipe, Ọjọ ó dara: nitoriti oju ọrun pọ́n.
3 Ati li owurọ̀ ẹnyin a wipe, Ọjọ kì yio dara loni, nitori ti oju ọrun pọ́n, o si ṣú dẹ̀dẹ. A! ẹnyin agabagebe, ẹnyin le mọ̀ àmi oju ọrun; ṣugbọn ẹnyin ko le mọ̀ àmi akokò wọnyi?
4 Iran buburu ati panṣaga nfẹ àmi; a kì yio si fi àmi fun u, bikoṣe àmi ti Jona wolĩ. O si fi wọn silẹ, o kuro nibẹ.
Ìwúkàrà Àwọn Farisi ati Àwọn Sadusi
(Mak 8:14-21)
5Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si de apakeji, nwọn gbagbé lati mu akara lọwọ.
6Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ kiyesara, ki ẹ si mã sọra niti iwukara awọn Farisi ati ti awọn Sadusi.
7Nwọn si mbá ara wọn ṣaroye, wipe, Nitoriti awa ko mu akara lọwọ ni.
8Nigbati Jesu si woye, o wi fun wọn pe, Ẹnyin onigbagbọ́ kekere, ẽṣe ti ẹnyin fi mba ara nyin ṣaroye, nitoriti ẹnyin ko mu akara lọwọ?
9 Kò iti yé nyin di isisiyi, ẹnyin kò si ranti iṣu akara marun ti ẹgbẹdọgbọn enia, ati iye agbọ̀n ti ẹnyin si kójọ.
10 Ẹ kò si ranti iṣu akara meje ti ẹgbaji enia, ati iye agbọ̀n ti ẹnyin kójọ?
11 Ẽha ti ṣe ti kò fi yé nyin pe, emi kò ti itori akara sọ fun nyin pe, ẹ kiyesi ara nyin niti iwukara ti awọn Farisi ati ti awọn Sadusi.
12Nigbana li o to yé wọn pe, ki iṣe iwukara ti akara li o wipe ki nwọn kiyesara rẹ̀, ṣugbọn ẹkọ́ ti awọn Farisi ati ti awọn Sadusi.
Peteru Jẹ́wọ́ Ẹni tí Jesu Í Ṣe
(Mak 8:27-30; Luk 9:18-21)
13Nigbati Jesu de igberiko Kesarea Filippi, o bi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lẽre, wipe, Tali awọn enia nfi emi Ọmọ-enia ipe?
14Nwọn si wi fun u pe, Omiran ní, Johanu Baptisti; omiran wipe, Elijah; awọn ẹlomiran ni, Jeremiah, tabi ọkan ninu awọn woli.
15O bi wọn lẽre, wipe, Ṣugbọn tali ẹnyin nfi mi pè?
16Simoni Peteru dahùn, wipe, Kristi, Ọmọ Ọlọrun alãye ni iwọ iṣe.
17Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Alabukun-fun ni iwọ Simoni Ọmọ Jona: ki iṣe ẹran ara ati ẹ̀jẹ li o sá fi eyi hàn ọ, ṣugbọn Baba mi ti mbẹ li ọrun.
18 Emi si wi fun ọ pẹlu pe, Iwọ ni Peteru, ori apata yi li emi ó si kọ ijọ mi le; ẹnu-ọ̀na ipo-oku kì yio si le bori rẹ̀.
19 Emi ó si fun ọ ni kọkọrọ ijọba ọrun: ohunkohun ti iwọ ba dè li aiye, a o si dè e li ọrun: ohunkohun ti iwọ ba tú li aiye, a o si tú u li ọrun.
20Nigbana li o kìlọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, ki nwọn ki o màṣe sọ fun ẹnikan pe, on ni Kristi na.
Jesu Sọtẹ́lẹ̀ nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀
(Mak 8:31—9:1; Luk 9:22-27)
21Lati igbana lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ si ifihàn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, bi on ko ti le ṣailọ si Jerusalemu, lati jẹ ọ̀pọ ìya lọwọ awọn àgbagbà ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ki a si pa on, ati ni ijọ kẹta, ki o si jinde.
22Nigbana ni Peteru mu u, o bẹ̀rẹ si iba a wi pe, Ki a ma ri i, Oluwa, kì yio ri bẹ̃ fun ọ.
23Ṣugbọn o yipada, o si wi fun Peteru pe, Kuro lẹhin mi, Satani, ohun ikọsẹ̀ ni iwọ jẹ fun mi: iwọ ko rò ohun ti iṣe ti Ọlọrun, bikoṣe eyi ti iṣe ti enia.
24Nigbana ni Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Bi ẹnikan ba nfẹ lati tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin.
25 Nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ gbà ẹmi rẹ̀ là, yio sọ ọ nù: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi, yio ri i.
26 Nitoripe ère kini fun enia, bi o jèrè gbogbo aiye, ti o si sọ ẹmí rẹ̀ nù? tabi kili enia iba fi ṣe paṣiparọ ẹmí rẹ̀?
27 Nitori Ọmọ-enia yio wá ninu ogo Baba rẹ̀ pẹlu awọn angẹli rẹ̀; nigbana ni yio san a fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀.
28 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹlomiran wà ninu awọn ti o duro nihinyi, ti kì yio ri ikú, titi nwọn o fi ri Ọmọ-enia ti yio ma bọ̀ ni ijọba rẹ̀.
Currently Selected:
Mat 16: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.