YouVersion Logo
Search Icon

Lef 8

8
Ìyàsímímọ́ Aaroni ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀
(Eks 29:1-37)
1OLUWA si sọ fun Mose pe,
2Mú Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati ẹ̀wu wọnni, ati oróro itasori, ati akọmalu kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo meji, ati agbọ̀n àkara alaiwu kan;
3Ki iwọ ki o si pè gbogbo ijọ enia jọ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
4Mose si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun u; a si pe awọn enia jọ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
5Mose si wi fun ijọ enia pe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ lati ṣe.
6Mose si mú Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wá, o si fi omi wẹ̀ wọn.
7O si wọ̀ ọ li ẹ̀wu, o si fi amure dì i, o si fi aṣọ igunwa wọ̀ ọ, o si wọ̀ ọ li ẹ̀wu-efodi, o si fi onirũru-ọ̀na ọjá ẹ̀wu-efodi dì i, o si fi gbà a li ọjá.
8O si dì igbàiya mọ́ ọ; o si fi Urimu ati Tummimu sinu igbàiya na.
9O si fi fila dé e li ori; ati lara fila na pẹlu, ani niwaju rẹ̀, li o fi awo wurà na si, adé mimọ́ nì; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
10Mose si mú oróro itasori, o si ta a sara agọ́, ati sara ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, o si yà wọn simimọ́.
11O si mú ninu rẹ̀ fi wọ́n ori pẹpẹ nigba meje, o si ta a sara pẹpẹ na, ati si gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada ati ẹsẹ̀ rẹ̀, lati yà wọn simimọ́.
12O si dà ninu oróro itasori si ori Aaroni, o si ta a si i lara, lati yà a simimọ́.
13Mose si mú awọn ọmọ Aaroni wá, o si fi ẹ̀wu wọ̀ wọn, o si fi amure di wọn, o si fi fila dé wọn li ori; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
14O si mú akọmalu wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ fọwọ́ wọn lé ori akọmalu na fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.
15O si pa a; Mose si mú ẹ̀jẹ na, o si fi iká rẹ̀ tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ na yiká, o si wẹ̀ pẹpẹ na mọ́, o si dà ẹ̀jẹ na si isalẹ pẹpẹ, o si yà a simimọ́, lati ṣètutu fun u.
16O si mú gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, ati iwe mejeji, ati ọrá wọn, Mose si sun u lori pẹpẹ.
17Ṣugbọn akọmalu na, ati awọ rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati igbẹ́ rẹ̀, on li o fi iná sun lẹhin ibudó; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
18O si mú àgbo ẹbọ sisun wá: Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ si fọwọ́ wọn lé ori àgbo na.
19O si pa a: Mose si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ yiká.
20O si kun àgbo na; Mose si sun ori rẹ̀, ati ara rẹ̀, ati ọrá na.
21O si ṣìn ifun rẹ̀ ati itan rẹ̀ ninu omi; Mose si sun gbogbo àgbo na lori pẹpẹ: ẹbọ sisun fun õrùn didùn ni: ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
22O si mú àgbo keji wá, àgbo ìyasimimọ́: Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ si fọwọ́ wọn lé ori àgbo na.
23O si pa a; Mose si mú ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, o si tọ́ ọ si eti ọtún Aaroni, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀.
24O si mú awọn ọmọ Aaroni wá, Mose si tọ́ ninu ẹ̀jẹ na si eti ọtún wọn, ati si àtampako ọwọ́ ọtún wọn, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún wọn: Mose si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ yiká.
25O si mú ọrá na, ati ìru ti o lọrá, ati gbogbo ọrá ti o mbẹ lara ifun, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, ati iwe mejeji, ati ọrá wọn, ati itan ọtún:
26Ati lati inu agbọ̀n àkara alaiwu, ti o wà niwaju OLUWA, o mú adidùn àkara alaiwu kan, ati adidùn àkara oloróro kan, ati àkara fẹlẹfẹlẹ kan, o si fi wọn sori ọrá nì, ati si itan ọtún na:
27O si fi gbogbo rẹ̀ lé Aaroni li ọwọ́, ati lé ọwọ́ awọn ọmọ rẹ̀, o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA.
28Mose si gbà wọn li ọwọ́ wọn, o si sun wọn lori pẹpẹ li ẹbọ sisun: ìyasimimọ́ ni nwọn fun õrùn didùn: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA.
29Mose si mú igẹ̀ ẹran na, o si fì i li ẹbọ fifì niwaju OLUWA: nitori ipín ti Mose ni ninu àgbo ìyasimimọ́; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
30Mose si mú ninu oróro itasori nì, ati ninu ẹ̀jẹ ti mbẹ lori pẹpẹ, o si fi i wọ́n ara Aaroni, ati ara aṣọ rẹ̀ wọnni, ati ara awọn ọmọ rẹ̀, ati ara aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; o si yà Aaroni simimọ́, ati aṣọ rẹ̀ wọnni, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀.
31Mose si wi fun Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ bọ̀ ẹran na li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: nibẹ̀ ni ki ẹnyin si jẹ ẹ pẹlu àkara nì ti mbẹ ninu agbọ̀n ìyasimimọ́, bi mo ti fi aṣẹ lelẹ wipe, Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ni ki o jẹ ẹ.
32Eyiti o ba si kù ninu ẹran na ati ninu àkara na ni ki ẹnyin ki o fi iná sun.
33Ki ẹnyin ki o máṣe jade si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ ni ijọ́ meje, titi ọjọ́ ìyasimimọ́ nyin yio fi pé; nitori ijọ́ meje ni a o fi yà nyin simimọ́.
34Bi o ti ṣe li oni yi, bẹ̃li OLUWA fi aṣẹ lelẹ lati ṣe, lati ṣètutu fun nyin.
35Nitorina ni ki ẹnyin ki o joko nibi ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, li ọsán ati li oru ni ijọ́ meje, ki ẹnyin ki o si ma pa aṣẹ OLUWA mọ́, ki ẹnyin ki o má ba kú: nitoripe bẹ̃li a fi aṣẹ fun mi.
36Bẹ̃li Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ṣe ohun gbogbo ti OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ lati ọwọ́ Mose wá.

Currently Selected:

Lef 8: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in