Lef 3
3
Ẹbọ Alaafia
1BI ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ẹbọ alafia, bi o ba mú u lati inu ọwọ́-ẹran wá, on iba ṣe akọ tabi abo, ki o mú u wá siwaju OLUWA li ailabùku.
2Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, ki o si pa a li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: ki awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni ki o si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ nì yiká.
3Ki o si mú ninu ẹbọ alafia nì wá, ọrẹ-ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun na.
4Ati iwe nì mejeji, ati ọrá ti mbẹ́ lara wọn, ti mbẹ li ẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe nì, on ni ki o mú kuro.
5Ki awọn ọmọ Aaroni ki o si sun u lori pẹpẹ nì lori ẹbọ sisun, ti mbẹ lori igi ti o wà lori iná: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni, õrùn didùn si OLUWA.
6Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ fun ọrẹ-ẹbọ alafia si OLUWA ba ṣe ti agbo-ẹran; akọ tabi abo, ki o mú u wá li ailabùku.
7Bi o ba mu ọdọ-agutan wá fun ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, njẹ ki o mú u wá siwaju OLUWA:
8Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, ki o si pa a niwaju agọ́ ajọ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o si fi ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ na yiká.
9Ki o si múwa ninu ẹbọ alafia nì, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá rẹ̀, ati gbogbo ìru rẹ̀ ti o lọrá, on ni ki o mú kuro sunmọ egungun ẹhin; ati ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun,
10Ati iwe mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe nì, on ni ki o mú kuro.
11Ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ: onjẹ ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA ni.
12Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ewurẹ, njẹ ki o mú u wá siwaju OLUWA:
13Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori rẹ̀, ki o si pa a niwaju agọ́ ajọ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o si fi ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ na yiká.
14Ki o si mú ninu ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá, ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti o mbẹ lara ifun,
15Ati iwe nì mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe nì, on ni ki o mú kuro.
16Ki alufa ki o si sun wọn lori pẹpẹ: onjẹ ẹbọ ti a fi iná ṣe fun õrùn didùn ni: ti OLUWA ni gbogbo ọrá.
17Ìlana titilai ni fun irandiran nyin, ni gbogbo ibugbé nyin, pe ki ẹnyin ki o máṣe jẹ ọrá tabi ẹ̀jẹ.
Currently Selected:
Lef 3: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.