Lef 26
26
Ibukun fún Ìgbọràn
(Deu 7:12-24; 28:1-14)
1ẸNYIN kò gbọdọ yá oriṣa, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ gbé ere tabi ọwọ̀n kan dide naró fun ara nyin, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ gbé ere okuta gbigbẹ kalẹ ni ilẹ nyin, lati tẹriba fun u: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
2Ki ẹnyin ki o pa ọjọ́-isimi mi mọ́, ki ẹ si bọ̀wọ fun ibi mimọ́ mi: Emi li OLUWA.
3Bi ẹnyin ba nrìn ninu ìlana mi, ti ẹ si npa ofin mi mọ́, ti ẹ si nṣe wọn;
4Nigbana li emi o fun nyin li òjo li akokò rẹ̀, ilẹ yio si ma mú ibisi rẹ̀ wá, igi oko yio si ma so eso wọn.
5Ipakà nyin yio si dé ìgba ikore àjara, igba ikore àjara yio si dé ìgba ifunrugbìn: ẹnyin o si ma jẹ onjẹ nyin li ajẹyo, ẹ o si ma gbé ilẹ nyin li ailewu.
6Emi o si fi alafia si ilẹ na, ẹnyin o si dubulẹ, kò si sí ẹniti yio dẹruba nyin: emi o si mu ki ẹranko buburu ki o dasẹ kuro ni ilẹ na, bẹ̃ni idà ki yio là ilẹ nyin já.
7Ẹnyin o si lé awọn ọtá nyin, nwọn o si ti ipa idà ṣubu niwaju nyin.
8Marun ninu nyin yio si lé ọgọrun, ọgọrun ninu nyin yio si lé ẹgbarun: awọn ọtá nyin yio si ti ipa idà ṣubu niwaju nyin.
9Nitoriti emi o fi ojurere wò nyin, emi o si mu nyin bisi i, emi o si sọ nyin di pupọ̀, emi o si gbé majẹmu mi kalẹ pẹlu nyin.
10Ẹnyin o si ma jẹ ohun isigbẹ, ẹnyin o si ma kó ohun ẹgbẹ jade nitori ohun titun.
11Emi o si gbé ibugbé mi kalẹ lãrin nyin: ọkàn mi ki yio si korira nyin.
12Emi o si ma rìn lãrin nyin, emi o si ma ṣe Ọlọrun nyin, ẹnyin o si ma ṣe enia mi.
13Emi li OLUWA Ọlọrun nyin ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá, ki ẹnyin ki o máṣe wà li ẹrú wọn; emi si ti dá ìde àjaga nyin, mo si mu nyin rìn lõrogangan.
Ìjìyà fún Ìwà Àìgbọràn
(Deu 28:15-68)
14Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbọ́ ti emi, ti ẹ kò si ṣe gbogbo ofin wọnyi;
15Bi ẹnyin ba si gàn ìlana mi, tabi bi ọkàn nyin ba korira idajọ mi, tobẹ̃ ti ẹnyin ki yio fi ṣe gbogbo ofin mi, ṣugbọn ti ẹnyin dà majẹmu mi;
16Emi pẹlu yio si ṣe eyi si nyin; emi o tilẹ rán ẹ̀ru si nyin, àrun-igbẹ ati òjojo gbigbona, ti yio ma jẹ oju run, ti yio si ma mú ibinujẹ ọkàn wá: ẹnyin o si fun irugbìn nyin lasan, nitoripe awọn ọtá nyin ni yio jẹ ẹ.
17Emi o si kọ oju mi si nyin, a o si pa nyin niwaju awọn ọtá nyin: awọn ti o korira nyin ni yio si ma ṣe olori nyin; ẹnyin o si ma sá nigbati ẹnikan kò lé nyin.
18Ninu gbogbo eyi, bi ẹnyin kò ba si gbọ́ ti emi, nigbana li emi o jẹ nyin ni ìya ni ìgba meje si i nitori ẹ̀ṣẹ nyin.
19Emi o si ṣẹ́ igberaga agbara nyin; emi o si sọ ọrun nyin dabi irin, ati ilẹ nyin dabi idẹ:
20Ẹnyin o si lò agbara nyin lasan: nitoriti ilẹ nyin ki yio mú ibisi rẹ̀ wá, bẹ̃ni igi ilẹ nyin ki yio so eso wọn.
21Bi ẹnyin ba si nrìn lodi si mi, ti ẹnyin kò si gbọ́ ti emi; emi o si mú iyọnu ìgba meje wá si i lori nyin gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ nyin.
22Emi o si rán ẹranko wá sinu nyin pẹlu, ti yio ma gbà nyin li ọmọ, ti yio si ma run nyin li ẹran-ọ̀sin, ti yio si mu nyin dinkù; opópo nyin yio si dahoro.
23Bi ẹnyin kò ba gbà ìkilọ mi nipa nkan wọnyi, ṣugbọn ti ẹnyin o ma rìn lodi si mi;
24Nigbana li emi pẹlu yio ma rìn lodi si nyin, emi o si jẹ nyin ni ìya si i ni ìgba meje nitori ẹ̀ṣẹ nyin.
25Emi o si mú idà wá sori nyin, ti yio gbà ẹsan majẹmu mi; a o si kó nyin jọ pọ̀ ninu ilu nyin, emi o rán ajakalẹ-àrun sãrin nyin; a o si fi nyin lé ọtá lọwọ.
26Nigbati mo ba ṣẹ́ ọpá onjẹ nyin, obinrin mẹwa yio yan àkara nyin ninu àro kan, ìwọ̀n ni nwọn o si ma fi fun nyin li àkara nyin: ẹnyin o si ma jẹ, ẹ ki yio si yó.
27Ninu gbogbo eyi bi ẹnyin kò ba si gbọ́ ti emi, ti ẹ ba si nrìn lodi si mi;
28Nigbana li emi o ma rìn lodi si nyin pẹlu ni ikannu; emi pẹlu yio si nà nyin ni ìgba meje nitori ẹ̀ṣẹ nyin.
29Ẹnyin o si jẹ ẹran-ara awọn ọmọ nyin ọkunrin, ati ẹran-ara awọn ọmọ nyin obinrin li ẹnyin o jẹ.
30Emi o si run ibi giga nyin wọnni, emi o si ke ere nyin lulẹ, emi o si wọ́ okú nyin sori okú oriṣa nyin; ọkàn mi yio si korira nyin.
31Emi o si sọ ilu nyin di ahoro, emi o si sọ ibi mimọ́ nyin di ahoro, emi ki yio gbọ́ adùn õrùn didùn nyin mọ́.
32Emi o si sọ ilẹ na di ahoro: ẹnu yio si yà awọn ọtá nyin ti ngbé inu rẹ̀ si i.
33Emi o si tú nyin ká sinu awọn orilẹ-ède, emi o si yọ idà tì nyin lẹhin: ilẹ nyin yio si di ahoro, ati ilu nyin yio di ahoro.
34Nigbana ni ilẹ na yio ní isimi rẹ̀, ni gbogbo ọjọ́ idahoro rẹ̀, ẹnyin o si wà ni ilẹ awọn ọtá nyin; nigbana ni ilẹ yio simi, ti yio si ní isimi rẹ̀.
35Ni gbogbo ọjọ́ idahoro rẹ̀ ni yio ma simi; nitoripe on kò simi li ọjọ́-isimi nyin, nigbati ẹnyin ngbé inu rẹ̀.
36Ati lara awọn ti o kù lãye ninu nyin, li emi o rán ijàiya si ọkàn wọn ni ilẹ awọn ọtá wọn: iró mimì ewé yio si ma lé wọn; nwọn o si sá, bi ẹni sá fun idà; nwọn o si ma ṣubu nigbati ẹnikan kò lepa.
37Nwọn o si ma ṣubulù ara wọn, bi ẹnipe niwaju idà, nigbati kò sí ẹniti nlepa: ẹnyin ki yio si lí agbara lati duro niwaju awọn ọtá nyin.
38Ẹnyin o si ṣegbé ninu awọn orilẹ-ède, ilẹ awọn ọtá nyin yio si mú nyin jẹ.
39Ati awọn ti o kù ninu nyin yio si joro ninu ẹ̀ṣẹ wọn ni ilẹ awọn ọtá nyin; ati nitori ẹ̀ṣẹ awọn baba wọn pẹlu ni nwọn o ma joro pẹlu wọn.
40Bi nwọn ba si jẹwọ irekọja wọn, ati irekọja awọn baba wọn, pẹlu ọ̀tẹ wọn ti nwọn ti ṣe si mi, ati pẹlu nitoripe nwọn ti rìn lodi si mi;
41Emi pẹlu rìn lodi si wọn, mo si mú wọn wá si ilẹ awọn ọtá wọn: njẹ bi àiya wọn alaikọlà ba rẹ̀silẹ, ti nwọn ba si gbà ibawi ẹ̀ṣẹ wọn;
42Nigbana li emi o ranti majẹmu mi pẹlu Jakobu; ati majẹmu mi pẹlu Isaaki, ati majẹmu mi pẹlu Abrahamu li emi o ranti; emi o si ranti ilẹ na.
43Nwọn o si fi ilẹ na silẹ, on o si ní isimi rẹ̀, nigbati o ba di ahoro li aisí wọn; nwọn o si gbà ibawi ẹ̀ṣẹ wọn: nitoripe, ani nitoripe nwọn gàn idajọ mi, ati ọkàn wọn korira ìlana mi.
44Ṣugbọn sibẹ̀ ninu gbogbo eyina, nigbati nwọn ba wà ni ilẹ awọn ọtá wọn, emi ki yio tà wọn nù, bẹ̃li emi ki yio korira wọn, lati run wọn patapata, ati lati dà majẹmu mi pẹlu wọn: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun wọn:
45Ṣugbọn nitori wọn emi o ranti majẹmu awọn baba nla wọn, ti mo mú lati ilẹ Egipti jade wá li oju awọn orilẹ-ède, ki emi ki o le ma ṣe Ọlọrun wọn: Emi li OLUWA.
46Wọnyi ni ìlana ati idajọ, ati ofin ti OLUWA dásilẹ, lãrin on ati awọn ọmọ Israeli li òke Sinai nipa ọwọ́ Mose.
Currently Selected:
Lef 26: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.