Lef 13
13
Àwọn Òfin tí ó Jẹmọ́ Àrùn Ara
1OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,
2Nigbati enia kan ba ní iwú, apá, tabi àmi didán kan li awọ ara rẹ̀, ti o si mbẹ li awọ ara rẹ̀ bi àrun ẹ̀tẹ; nigbana ni ki a mú u tọ̀ Aaroni alufa wá, tabi ọkan ninu awọn ọmọ rẹ̀, alufa:
3Alufa yio si wò àrun ti mbẹ li awọ ara rẹ̀: bi irun ti mbẹ li oju àrun na ba si di funfun, ati ti àrun na li oju rẹ̀ ba jìn jù awọ ara rẹ̀ lọ, àrun ẹ̀tẹ ni: ki alufa ki o si wò o, ki o si pè e li alaimọ́.
4Bi àmi didán na ba funfun li awọ ara rẹ̀, ati li oju rẹ̀ ti kò si jìn jù awọ lọ, ti irun rẹ̀ kò di funfun, nigbana ni ki alufa ki o sé alarun na mọ́ ni ijọ́ meje:
5Ki alufa ki o si wò o ni ijọ́ keje: si kiyesi i, bi àrun na ba duro li oju rẹ̀, ti àrun na kò ba si ràn li ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o sé e mọ́ ni ijọ́ meje si i:
6Ki alufa ki o si tun wò o ni ijọ́ keje: si kiyesi i, bi àrun na ba ṣe bi ẹni wodú, ti àrun na kò si ràn si i li awọ ara, ki alufa ki o pè e ni mimọ́: kìki apá ni: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o jẹ́ mimọ́.
7Ṣugbọn bi apá na ba ràn pupọ̀ si i li awọ ara, lẹhin igbati alufa ti ri i tán fun mimọ́ rẹ̀, alufa yio si tun wò o.
8Alufa yio wò o, kiyesi i, apá na ràn li awọ ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li alaimọ́: ẹ̀tẹ ni.
9Nigbati àrun ẹ̀tẹ ba mbẹ li ara enia, nigbana ni ki a mú u tọ̀ alufa wá;
10Ki alufa ki o si wò o, si kiyesi i, bi iwú na ba funfun li awọ ara rẹ̀, ti o si sọ irun rẹ̀ di funfun, ti õju si mbẹ ninu iwú na,
11Ẹ̀tẹ lailai ni li awọ ara rẹ̀, ki alufa ki o pè e li alaimọ́: ki o máṣe sé e mọ́; nitoripe alaimọ́ ni.
12Bi ẹ̀tẹ ba si sọ jade kakiri li awọ ara, ti ẹ̀tẹ na ba si bò gbogbo ara ẹniti o ní àrun na, lati ori rẹ̀ titi dé ẹsẹ̀ rẹ̀, nibikibi ti alufa ba wò;
13Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi ẹ̀tẹ na ba bò gbogbo ara rẹ̀, ki o pè àlarun na ni mimọ́; gbogbo rẹ̀ di funfun: mimọ́ li on.
14Ṣugbọn ni ijọ́ ti õju na ba hàn ninu rẹ̀, ki o jẹ́ alaimọ́.
15Ki alufa ki o wò õju na, ki o si pè e li alaimọ́: nitoripe aimọ́ li õju: ẹ̀tẹ ni.
16Tabi bi õju na ba yipada, ti o si di funfun, ki o si tọ̀ alufa wá,
17Alufa yio si wò o: si kiyesi i, bi àrun na ba di funfun, nigbana ni ki alufa ki o pè àlarun na ni mimọ́: mimọ́ li on.
18Ara pẹlu, ninu eyi, ani li awọ ara ti õwo ti sọ, ti o si jiná,
19Ati ni apá õwo na bi iwú funfun ba mbẹ nibẹ̀, tabi àmi didán, funfun ti o si ṣe bi ẹni pọ́n ki a si fi i hàn alufa;
20Alufa yio wò o, si kiyesi i, li oju rẹ̀ bi o ba jìn jù awọ ara lọ, ti irun rẹ̀ si di funfun, ki alufa ki o pè e li alaimọ́: àrun ẹ̀tẹ li o sọ jade ninu õwo na.
21Ṣugbọn bi alufa na ba wò o, si kiyesi i, ti irun funfun kò si sí ninu rẹ̀, bi kò ba si jìn jù awọ ara lọ, ti o si dabi ẹni wodú, nigbana ni ki alufa ki o sé e mọ́ ni ijọ́ meje:
22Bi o ba si ràn siwaju li awọ ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e ni alaimọ́: àrun ni.
23Ṣugbọn bi àmi didán na ba duro ni ipò rẹ̀, ti kò si ràn, õwo tita ni; ki alufa ki o si pè e ni mimọ́.
24Tabi bi ara kan ba mbẹ, ninu awọ ara eyiti ijóni bi iná ba wà, ti ojú jijóna na ba ní àmi funfun didán, ti o ṣe bi ẹni pọn rusurusu tabi funfun;
25Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi irun ninu àmi didán na ba di funfun, ti o ba si jìn jù awọ ara lọ li oju; ẹ̀tẹ li o ti inu ijóni nì sọ jade; nitorina ni ki alufa ki o pè e ni alaimọ́: àrun ẹ̀tẹ ni.
26Ṣugbọn bi alufa ba wò o, si kiyesi i, ti kò sí irun funfun li apá didán na, ti kò si jìn jù awọ ara iyokù lọ, ṣugbọn ti o ṣe bi ẹni ṣújú; nigbana ni ki alufa ki o sé e mọ́ ni ijọ́ meje:
27Ki alufa ki o si wò o ni ijọ́ keje: bi o ba si ràn siwaju li awọ ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li alaimọ́; àrun ẹ̀tẹ ni.
28Bi àmi didán na ba si duro ni ipò rẹ̀, ti kò si ràn si i li awọ ara, ṣugbọn ti o dabi ẹni sújú: iwú ijóni ni, ki alufa ki o si pè e ni mimọ́: nitoripe ijóni tita ni.
29Bi ọkunrin tabi obinrin kan ba ní àrun li ori rẹ̀ tabi li àgbọn,
30Nigbana ni ki alufa ki o wò àrun na: si kiyesi i, bi o ba jìn jù awọ ara lọ li oju, bi irun tinrin pupa ba mbẹ ninu rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li aimọ́: ipẹ́ gbigbẹ ni, ani ẹ̀tẹ li ori tabi li àgbọn ni.
31Bi alufa ba si wò àrun pipa na, si kiyesi i, ti kò ba jìn jù awọ ara lọ li oju, ti kò si sí irun dudu ninu rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o sé àlarun pipa na mọ́ ni ijọ́ meje:
32Ni ijọ́ keje ki alufa ki o si wò àrun na: si kiyesi i, bi pipa na kò ba ràn, ti kò si sí irun pupa ninu rẹ̀, ti pipa na kò si jìn jù awọ ara lọ li oju,
33Ki o fári, ṣugbọn ki o máṣe fá ibi pipa na; ki alufa ki o si sé ẹni pipa nì mọ́ ni ijọ́ meje si i:
34Ni ijọ́ keje ki alufa ki o si wò pipa na; si kiyesi i bi pipa na kò ba ràn si awọ ara, ti kò ba jìn jù awọ ara lọ li oju; nigbana ni ki alufa ki o pè e ni mimọ́: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ mimọ́.
35Ṣugbọn bi pipa na ba ràn siwaju li awọ ara rẹ̀ lẹhin ìpenimimọ́ rẹ̀;
36Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi pipa na ba ràn siwaju li awọ ara, ki alufa ki o máṣe wá irun pupa mọ́; alaimọ́ ni.
37Ṣugbọn li oju rẹ̀ bi pipa na ba duro, ti irun dudu si hù ninu rẹ̀; pipa na jiná, mimọ́ li on: ki alufa ki o pè e ni mimọ́.
38Bi ọkunrin kan tabi obinrin kan ba ní àmi didán li awọ ara wọn, ani àmi funfun didán;
39Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi àmi didán li awọ ara wọn ba ṣe bi ẹni ṣe funfun ṣe dudu; ifinra li o sọ jade li ara; mimọ́ li on.
40Ati ọkunrin ti irun rẹ̀ ba re kuro li ori rẹ̀, apari ni; ṣugbọn mimọ́ li on.
41Ẹniti irun rẹ̀ ba re silẹ ni ìha iwaju rẹ̀, o pari ni iwaju; ṣugbọn mimọ́ li on.
42Bi õju funfun-pupa rusurusu ba mbẹ li ori pipa na, tabi iwaju ori pipa na; ẹ̀tẹ li o sọ jade ninu pipa ori na, tabi ni pipá iwaju na.
43Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi iwú õju na ba funfun-pupa rusurusu ni pipa ori rẹ̀, tabi pipa iwaju rẹ̀, bi ẹ̀tẹ ti ihàn li awọ ara;
44Ẹlẹtẹ ni, alaimọ́ ni: ki alufa ki o pè e li aimọ́ patapata; àrun rẹ̀ mbẹ li ori rẹ̀.
45Ati adẹ́tẹ na, li ara ẹniti àrun na gbé wà, ki o fà aṣọ rẹ̀ ya, ki o si fi ori rẹ̀ silẹ ni ìhoho, ki o si fi ìbo bò ète rẹ̀ òke, ki o si ma kepe, Alaimọ́, alaimọ́.
46Ni gbogbo ọjọ́ ti àrun na mbẹ li ara rẹ̀ ni ki o jẹ́ elẽri; alaimọ́ ni: on nikan ni ki o ma gbé; lẹhin ibudó ni ibujoko rẹ̀ yio gbé wà.
Àwọn Òfin tí Ó Jẹmọ́ Kí Nǹkan Séèébu
47Ati aṣọ ti àrun ẹ̀tẹ mbẹ ninu rẹ̀, iba ṣe aṣọ kubusu, tabi aṣọ ọ̀gbọ;
48Iba ṣe ni ita, tabi ni iwun; ti ọ̀gbọ, tabi ti kubusu; iba ṣe li awọ, tabi ohun kan ti a fi awọ ṣe;
49Bi àrun na ba ṣe bi ọbẹdo tabi bi pupa lara aṣọ na, tabi lara awọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo awọ kan; àrun ẹ̀tẹ ni, ki a si fi i hàn alufa:
50Ki alufa ki o si wò àrun na, ki o si sé ohun ti o ní àrun na mọ́ ni ijọ́ meje:
51Ki o si wò àrun na ni ijọ́ keje: bi àrun na ba ràn sara aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu awọ, tabi ninu ohun ti a fi awọ ṣe; àrun oun ẹ̀tẹ kikẹ̀ ni; alaimọ́ ni.
52Nitorina ki o fi aṣọ na jóna, iba ṣe ita, tabi iwun, ni kubusu tabi li ọ̀gbọ, tabi ninu ohunèlo awọ kan, ninu eyiti àrun na gbé wà: nitoripe ẹ̀tẹ kikẹ̀ ni; ki a fi jóna.
53Bi alufa ba si wò, si kiyesi i, ti àrun na kò ba tàn sara aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo kan ti a fi awọ ṣe;
54Nigbana ni ki alufa ki o paṣẹ ki nwọn ki o fọ̀ ohun na ninu eyiti àrun na gbé wà, ki o si sé e mọ́ ni ijọ meje si i.
55Ki alufa ki o si wò àrun na, lẹhin igbati a fọ̀ ọ tán: si kiyesi i, bi àrun na kò ba pa awọ rẹ̀ dà, ti àrun na kò si ràn si i, alaimọ́ ni; ninu iná ni ki iwọ ki o sun u; o kẹ̀ ninu, iba gbo ninu tabi lode.
56Bi alufa ba si wò, si kiyesi i, ti àrun na ba ṣe bi ẹni wodú lẹhin igbati o ba fọ̀ ọ tán; nigbana ni ki o fà a ya kuro ninu aṣọ na, tabi ninu awọ na, tabi ninu ita, tabi ninu iwun:
57Bi o ba si hàn sibẹ̀ ninu aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo kan ti a fi awọ ṣe, àrun riràn ni: ki iwọ ki o fi iná sun ohun ti àrun na wà ninu rẹ̀.
58Ati aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunkohun ti a fi awọ ṣe, ti iwọ ba fọ̀, bi àrun na ba wọ́n kuro ninu wọn nigbana ni ki a tun fọ̀ ọ lẹkeji, on o si jẹ́ mimọ́.
59Eyi li ofin àrun ẹ̀tẹ, ninu aṣọ, kubusu tabi ti ọ̀gbọ, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ohunkohun èlo awọ kan, lati pè e ni mimọ́, tabi lati pè e li aimọ́.
Currently Selected:
Lef 13: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.