Joṣ 10
10
Wọ́n Ṣẹgun Àwọn Ará Amori
1O SI ṣe, nigbati Adoni-sedeki ọba Jerusalemu gbọ́ pe Joṣua ti kó Ai, ti o si pa a run patapata; bi o ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀, bẹ̃li o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀; ati bi awọn ara Gibeoni ti bá Israeli ṣọrẹ, ti nwọn si ngbé ãrin wọn;
2Nwọn bẹ̀ru pipọ̀, nitoriti Gibeoni ṣe ilu nla, bi ọkan ninu awọn ilu ọba, ati nitoriti o tobi jù Ai lọ, ati gbogbo ọkunrin inu rẹ̀ jẹ́ alagbara.
3Nitorina Adoni-sedeki ọba Jerusalemu ranṣẹ si Hohamu ọba Hebroni, ati si Piramu ọba Jarmutu, ati si Jafia ọba Lakiṣi, ati si Debiri ọba Egloni, wipe,
4Ẹ gòke tọ̀ mi wá, ki ẹ si ràn mi lọwọ, ki awa ki o le kọlù Gibeoni: nitoriti o bá Joṣua ati awọn ọmọ Israeli ṣọrẹ.
5Awọn ọba Amori mararun, ọba Jerusalemu, ọba Hebroni, ọba Jarmutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egloni, kó ara wọn jọ, nwọn si gòke, awọn ati gbogbo ogun wọn, nwọn si dótì Gibeoni, nwọn si fi ìja fun u.
6Awọn ọkunrin Gibeoni si ranṣẹ si Joṣua ni ibudó ni Gilgali, wipe, Má ṣe fà ọwọ́ rẹ sẹhin kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ; gòke tọ̀ wa wá kánkán, ki o si gbà wa, ki o si ràn wa lọwọ: nitoriti gbogbo awọn ọba Amori ti ngbé ori òke kójọ pọ̀ si wa.
7Bẹ̃ni Joṣua gòke lati Gilgali lọ, on ati gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ̀, ati gbogbo awọn alagbara akọni.
8OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru wọn: nitoriti mo ti fi wọn lé ọ lọwọ; ki yio sí ọkunrin kan ninu wọn ti yio le duro niwaju rẹ.
9Joṣua si yọ si wọn lojijì; o si gòke lati Gilgali lọ ni gbogbo oru na.
10OLUWA si fọ́ wọn niwaju Israeli, o si pa wọn ni ipakupa ni Gibeoni, o si lepa wọn li ọ̀na òke Beti-horoni, o si pa wọn dé Aseka, ati dé Makkeda.
11O si ṣe, bi nwọn ti nsá niwaju Israeli, ti nwọn dé gẹrẹgẹrẹ Beti-horoni, OLUWA rọ̀ yinyin nla si wọn lati ọrun wá titi dé Aseka, nwọn si kú: awọn ti o ti ipa yinyin kú, o pọ̀ju awọn ti awọn ọmọ Israeli fi idà pa lọ.
12Nigbana ni Joṣua wi fun OLUWA li ọjọ́ ti OLUWA fi awọn Amori fun awọn ọmọ Israeli, o si wi li oju Israeli pe, Iwọ, Õrùn, duro jẹ lori Gibeoni; ati Iwọ, Oṣupa, li afonifoji Aijaloni.
13Õrùn si duro jẹ, oṣupa si duro, titi awọn enia fi gbẹsan lara awọn ọtá wọn. A kò ha kọ eyi nã sinu iwé Jaṣeri? Bẹ̃li õrùn duro li agbedemeji ọrun, kò si yára lati wọ̀ nìwọn ọjọ́ kan tọ̀tọ.
14Kò sí ọjọ́ ti o dabi rẹ̀ ṣaju rẹ̀ tabi lẹhin rẹ̀, ti OLUWA gbọ́ ohùn enia: nitoriti OLUWA jà fun Israeli.
15Joṣua si pada, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, si ibudó ni Gilgali.
Joṣua Fi Ogun Kó Àwọn Ọba Amori Maraarun
16Ṣugbọn awọn ọba marun nì sá, nwọn si fara wọn pamọ́ ni ihò kan ni Makkeda.
17A si sọ fun Joṣua pe, A ri awọn ọba marun ni ifarapamọ́ ni ihò ni Makkeda.
18Joṣua si wipe, Ẹ yí okuta nla di ẹnu ihò na, ki ẹ si yàn enia sibẹ̀ lati ṣọ́ wọn:
19Ṣugbọn ẹnyin, ẹ má ṣe duro, ẹ lepa awọn ọtá nyin, ki ẹ si kọlù wọn lẹhin; ẹ máṣe jẹ ki nwọn ki o wọ̀ ilu wọn lọ: nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi wọn lé nyin lọwọ.
20O si ṣe, nigbati Joṣua ati awọn ọmọ Israeli pa wọn ni ipakupa tán, titi a fi run wọn, ti awọn ti o kù ninu wọn wọ̀ inu ilu olodi lọ,
21Gbogbo enia si pada si ibudó sọdọ Joṣua ni Makkeda li alafia: kò sí ẹni kan ti o yọ ahọn rẹ̀ si awọn ọmọ Israeli.
22Nigbana ni Joṣua wipe, Ẹ ṣi ẹnu ihò na, ki ẹ si mú awọn ọba mararun na jade kuro ninu ihò tọ̀ mi wá.
23Nwọn si ṣe bẹ̃, nwọn si mú awọn ọba mararun nì jade lati inu ihò na tọ̀ ọ wá, ọba Jerusalemu, ọba Hebroni, ọba Jarmutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egloni.
24O si ṣe, nigbati nwọn mú awọn ọba na tọ̀ Joṣua wá, ni Joṣua pè gbogbo awọn ọkunrin Israeli, o si wi fun awọn olori awọn ọmọ-ogun ti o bá a lọ pe, Ẹ sunmọ ihin, ẹ si fi ẹsẹ̀ nyin lé ọrùn awọn ọba wọnyi. Nwọn si sunmọ wọn, nwọn si gbé ẹsẹ̀ wọn lé wọn li ọrùn.
25Joṣua si wi fun wọn pe, Ẹ má ṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe fòya; ẹ ṣe giri, ki ẹ si mu àiya le: nitoripe bayi li OLUWA yio ṣe si awọn ọtá nyin gbogbo ti ẹnyin mbájà.
26Lẹhin na ni Joṣua si kọlù wọn, o si pa wọn, o si so wọn rọ̀ lori igi marun: nwọn si sorọ̀ lori igi titi di aṣalẹ.
27O si ṣe li akokò ìwọ-õrùn, Joṣua paṣẹ, nwọn si sọ̀ wọn kalẹ kuro lori igi, nwọn si gbé wọn sọ sinu ihò na ninu eyiti nwọn ti sapamọ́ si, nwọn si fi okuta nla di ẹnu ihò na, ti o wà titi di oni-oloni.
Joṣua Tún Gba Àwọn Ìlú Amori Mìíràn Sí i
28Li ọjọ́ na ni Joṣua kó Makkeda, o si fi oju idà kọlù u, ati ọba rẹ̀; o pa wọn run patapata, ati gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀, kò kù ẹnikan silẹ: o si ṣe si ọba Makkeda gẹgẹ bi o ti ṣe si ọba Jeriko.
29Joṣua si kọja lati Makkeda lọ si Libna, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, o si fi ijà fun Libna:
30OLUWA si fi i lé Israeli lọwọ pẹlu, ati ọba rẹ̀: o si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀; kò kù ẹnikan ninu rẹ̀; o si ṣe si ọba rẹ̀ gẹgẹ bi o ti ṣe si ọba Jeriko.
31Joṣua si kọja lati Libna lọ si Lakiṣi, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, o si dótì i, o si fi ìja fun u.
32OLUWA si fi Lakiṣi lé Israeli lọwọ, o si kó o ni ijọ́ keji, o si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe si Libna.
33Nigbana ni Horamu ọba Geseri gòke lati ràn Lakiṣi lọwọ; Joṣua si kọlù u ati awọn enia rẹ̀, tobẹ̃ ti kò fi kù ẹnikan silẹ fun u.
34Lati Lakiṣi Joṣua kọja lọ si Egloni, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀; nwọn si dótì i, nwọn si fi ijà fun u;
35Nwọn si kó o li ọjọ́ na, nwọn si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀ li o parun patapata li ọjọ́ na, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe si Lakiṣi.
36Joṣua si gòke lati Egloni lọ si Hebroni, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀; nwọn si fi ijà fun u:
37Nwọn si kó o, nwọn si fi oju idà kọlù u, ati ọba rẹ̀, ati gbogbo ilu rẹ̀, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀; kò kù enikan silẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe si Egloni; o si pa a run patapata, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀.
38Joṣua si pada lọ si Debiri, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀; o si fi ijà fun u:
39O si kó o, ati ọba rẹ̀, ati gbogbo ilu rẹ̀; nwọn si fi oju idà kọlù wọn; nwọn si pa gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀ run patapata; kò si kù ẹnikan silẹ: gẹgẹ bi o ti ṣe si Hebroni, bẹ̃li o ṣe si Debiri, ati ọba rẹ̀; ati gẹgẹ bi o ti ṣe si Libna, ati ọba rẹ̀.
40Bẹ̃ni Joṣua kọlù gbogbo ilẹ, ilẹ òke, ati ti Gusù, ati ti pẹtẹlẹ̀, ati ti ẹsẹ̀-òke, ati awọn ọba wọn gbogbo; kò kù ẹnikan silẹ: ṣugbọn o pa ohun gbogbo ti nmí run patapata, gẹgẹ bi OLUWA, Ọlọrun Israeli, ti pa a laṣẹ.
41Joṣua si kọlù wọn lati Kadeṣi-barnea lọ titi dé Gasa, ati gbogbo ilẹ Goṣeni, ani titi dé Gibeoni.
42Ati gbogbo awọn ọba wọnyi ati ilẹ wọn, ni Joṣua kó ni ìgba kanna, nitoriti OLUWA, Ọlọrun Israeli, jà fun Israeli.
43Joṣua si pada, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, si ibudó ni Gilgali.
Currently Selected:
Joṣ 10: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.