Joel 2
2
Ọ̀wọ́ Eeṣú, gẹ́gẹ́ bí Àmì Ìkéde Ọjọ́ OLUWA
1Ẹ fun ipè ni Sioni, ẹ si dá idagìri ni oke mimọ́ mi; jẹ ki awọn ará ilẹ na warìri: nitoriti ọjọ Oluwa mbọ̀ wá, nitori o kù si dẹ̀dẹ;
2Ọjọ òkunkun ati òkudu, ọjọ ikũku ati òkunkun biribiri, bi ọyẹ̀ owurọ̀ ti ilà bò ori awọn oke-nla: enia nla ati alagbara; kò ti isi iru rẹ̀ ri, bẹ̃ni iru rẹ̀ kì yio si mọ lẹhin rẹ̀, titi de ọdun iran de iran.
3Iná njó niwaju wọn; ọwọ́-iná si njó lẹhin wọn: ilẹ na dàbi ọgbà Edeni niwaju wọn, ati lẹhin wọn bi ahoro ijù; nitõtọ, kò si si ohun ti yio bọ́ lọwọ wọn.
4Irí wọn dàbi irí awọn ẹṣin; ati bi awọn ẹlẹṣin, bẹ̃ni nwọn o sure.
5Bi ariwo kẹkẹ́ lori oke ni nwọn o fò, bi ariwo ọwọ́-iná ti o jó koriko gbigbẹ, bi alagbara enia ti a tẹ́ ni itẹ́gun.
6Li oju wọn, awọn enia yio jẹ irora pupọ̀: gbogbo oju ni yio ṣú dùdu.
7Nwọn o sare bi awọn alagbara; nwọn o gùn odi bi ọkunrin ologun; olukuluku wọn o si rìn lọ li ọ̀na rẹ̀, nwọn kì yio si bà ọ̀wọ́ wọn jẹ.
8Bẹ̃ni ẹnikan kì yio tì ẹnikeji rẹ̀; olukuluku wọn o rìn li ọ̀na rẹ̀: nigbati nwọn ba si ṣubu lù idà, nwọn kì o gbọgbẹ́.
9Nwọn o sure siwa sẹhin ni ilu: nwọn o sure lori odi, nwọn o gùn ori ile; nwọn o gbà oju fèrese wọ̀ inu ile bi olè.
10Aiye yio mì niwaju wọn; awọn ọrun yio warìri: õrùn ati oṣupa yio ṣu òkunkun, awọn iràwọ yio si fà imọlẹ wọn sẹhìn.
11Oluwa yio si fọ̀ ohùn rẹ̀ jade niwaju ogun rẹ̀: nitori ibùdo rẹ̀ tobi gidigidi: nitori alagbara li on ti nmu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ; nitori ọjọ Oluwa tobi o si li ẹ̀ru gidigidi; ara tali o le gbà a?
Ìpè fún Ìrònúpìwàdà
12Njẹ nitorina nisisiyi, ni Oluwa wi, Ẹ fi gbogbo ọkàn nyin yipada si mi, ati pẹlu ãwẹ̀, ati pẹlu ẹkún, ati pẹlu ọ̀fọ.
13Ẹ si fà aiyà nyin ya, kì isi ṣe aṣọ nyin, ẹ si yipadà si Oluwa Ọlọrun nyin, nitoriti o pọ̀ li ore-ọfẹ, o si kún fun ãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ̀, o si ronupiwada ati ṣe buburu.
14Tali o mọ̀ bi on o yipadà, ki o si ronupiwàda, ki o si fi ibukún silẹ̀ lẹhin rẹ̀; ani ọrẹ-jijẹ ati ọrẹ-mimu fun Oluwa Ọlọrun nyin?
15Ẹ fun ipè ni Sioni, ẹ yà ãwẹ̀ kan si mimọ́, ẹ pè ajọ ti o ni irònu.
16Ẹ kó awọn enia jọ, ẹ yà ijọ si mimọ́, ẹ pè awọn àgba jọ, ẹ kó awọn ọmọde jọ, ati awọn ti nmu ọmú: jẹ ki ọkọ iyàwo jade kuro ni iyẹ̀wu rẹ̀, ati iyàwo kuro ninu iyẹ̀wu rẹ̀.
17Jẹ ki awọn alufa, awọn iranṣẹ Oluwa, sọkun lãrin iloro ati pẹpẹ, si jẹ ki wọn wi pe, Dá awọn enia rẹ si, Oluwa, má si ṣe fi iní rẹ fun ẹ̀gan, ti awọn keferi yio fi ma jọba lori wọn: ẽṣe ti nwọn o fi wi ninu awọn enia pe, Ọlọrun wọn há da?
Ọlọrun Yóo Dá Ìbísí Pada sórí Ilẹ̀ náà
18Nigbana ni Oluwa yio jowú fun ilẹ rẹ̀, yio si kãnu fun enia rẹ̀.
19Nitõtọ, Oluwa yio dahùn, yio si wi fun awọn enia rẹ̀ pe, Wò o emi o rán ọkà, ati ọti-waini, ati ororo si nyin, a o si fi wọn tẹ́ nyin lọrùn: emi kì yio si fi nyin ṣe ẹ̀gan mọ lãrin awọn keferi.
20Ṣugbọn emi o ṣi ogun ariwa nì jinà rére kuro lọdọ nyin, emi o si le e lọ si ilẹ ti o ṣá, ti o si di ahoro, pẹlu oju rẹ̀ si okun ila-õrun, ati ẹhìn rẹ̀ si ipẹkùn okun, õrùn rẹ̀ yio si goke, õrùn buburu rẹ̀ yio si goke, nitoriti o ti ṣe ohun nla.
21Má bẹ̀ru, iwọ ilẹ; jẹ ki inu rẹ dùn, ki o si yọ̀: nitori Oluwa yio ṣe ohun nla.
22Ẹ má bẹ̀ru, ẹranko igbẹ: nitori pápa-oko aginju nrú, nitori igi nso eso rẹ̀, igi ọ̀pọtọ ati àjara nso eso ipá wọn.
23Njẹ jẹ ki inu nyin dùn, ẹnyin ọmọ Sioni, ẹ si yọ̀ ninu Oluwa Ọlọrun nyin; nitoriti o ti fi akọrọ̀ ojò fun nyin bi o ti tọ́, on o si mu ki ojò rọ̀ silẹ fun nyin, akọrọ̀ ati arọ̀kuro ojò ni oṣù ikini.
24Ati awọn ilẹ ipakà yio kún fun ọkà, ati ọpọ́n wọnni yio ṣàn jade pẹlu ọti-waini ati ororo.
25Emi o si mu ọdun wọnni padà fun nyin wá, eyi ti ẽṣú on iru kòkoro jewejewe, ati iru kòkoro keji, ati iru kòkoro jewejewe miràn ti fi jẹ, awọn ogun nla mi ti mo rán sãrin nyin.
26Ẹnyin o si jẹun li ọ̀pọlọpọ, ẹ o si yó, ẹ o si yìn orukọ Oluwa Ọlọrun nyin, ẹniti o fi iyanu ba nyin lò; oju kì o si tì awọn enia mi lai.
27Ẹnyin o si mọ̀ pe, emi wà lãrin Israeli, ati pe: Emi li Oluwa Ọlọrun nyin, kì iṣe ẹlomiràn: oju kì yio si tì awọn enia mi lai.
Ọjọ́ OLUWA
28Yio si ṣe, nikẹhìn emi o tú ẹmi mi jade si ara enia gbogbo; ati awọn ọmọ nyin ọkunrin, ati awọn ọmọ nyin obinrin yio ma ṣotẹlẹ, awọn arugbo nyin yio ma lá alá, awọn ọdọmọkunrin nyin yio ma riran:
29Ati pẹlu si ara awọn ọmọ-ọdọ ọkunrin, ati si ara awọn ọmọ-ọdọ obinrin, li emi o tú ẹmi mi jade li ọjọ wọnni.
30Emi o si fi iṣẹ iyanu hàn li ọrun ati li aiye, ẹjẹ̀ ati iná, ati ọwọ̀n ẹ̃fin.
31A ó sọ õrùn di òkunkun, ati oṣùpá di ẹjẹ̀, ki ọjọ nla ati ẹ̀ru Oluwa to de.
32Yio si ṣe ẹnikẹni ti o ba ke pè orukọ Oluwa li a o gbàla: nitori li oke Sioni ati ni Jerusalemu ni igbàla yio gbe wà, bi Oluwa ti wi, ati ninu awọn iyokù ti Oluwa yio pè.
Currently Selected:
Joel 2: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.