Job 23
23
1NIGBANA ni Jobu si dahùn wipe,
2Ani loni ni ọ̀ran mi korò; ọwọ mi si wuwo si ikerora mi.
3A! emi iba mọ̀ ibi ti emi iba wá Ọlọrun ri! ki emi ki o tọ̀ ọ lọ si ibujoko rẹ̀,
4Emi iba si tò ọran na niwaju rẹ̀, ẹnu mi iba si kún fun aroye.
5Emi iba si mọ̀ ọ̀rọ ti on iba fi da mi lohùn, oye ohun ti iba wi a si ye mi.
6Yio ha fi agbara nla ba mi wijọ bi? agbẹdọ̀! kiki on o si kiyesi mi:
7Nibẹ li olododo le iba a wijọ, bẹ̃li emi o si bọ́ li ọwọ onidajọ mi lailai.
8Si wò! bi emi ba lọ si iha ila-õrùn, on kò si nibẹ, ati si iwọ-õrùn ni, emi kò si roye rẹ̀:
9Niha ariwa bi o ba ṣiṣẹ nibẹ, emi kò ri i, o fi ara rẹ̀ pamọ niha gusu, ti emi kò le ri i.
10Ṣugbọn on mọ̀ ọ̀na ti emi ntọ̀, nigbati o ba dan mi wò, emi o jade bi wura.
11Ẹsẹ mi ti tẹle ipasẹ irin rẹ, ọ̀na rẹ̀ ni mo ti kiyesi, ti nkò si yà kuro.
12Bẹ̃ni emi kò pada sẹhin kuro ninu ofin ẹnu rẹ̀, emi si pa ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ mọ́ jù ofin inu mi lọ.
13Ṣugbọn oninukan li on, tani yio si yi i pada? Eyiti ọkàn rẹ̀ si ti fẹ, eyi na ni iṣe.
14Nitõtọ ohun ti ati yàn silẹ fun mi ni nṣe, ọ̀pọlọpọ iru bẹ li o wà li ọwọ rẹ̀.
15Nitorina ni ara ko ṣe rọ̀ mi niwaju rẹ̀, nigbati mo ba rò o, ẹ̀ru a ba mi.
16Nitoripe Ọlọrun ti pá mi li aiya, Olodumare si ndamu mi.
17Nitoriti a kò ti ke mi kuro niwaju òkunkun, bẹ̃ni kò pa òkùnkùn-biribiri mọ kuro niwaju mi.
Currently Selected:
Job 23: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.