YouVersion Logo
Search Icon

Job 20

20
1NIGBANA ni Sofari, ara Naama, dahùn o si wipe,
2Nitorina ni ìro inu mi da mi lohùn, ati nitori eyi na ni mo si yara si gidigidi.
3Mo ti gbọ́ ẹsan ẹ̀gan mi, ẹmi oye mi si da mi lohùn.
4Iwọ kò mọ̀ eyi ri ni igba atijọ, lati igba ti a sọ enia lọjọ̀ silẹ aiye?
5Pe, orin ayọ̀ enia buburu igba kukuru ni, ati pe, ni iṣẹju kan li ayọ̀ àgabagebe.
6Bi ọlanla rẹ̀ tilẹ goke de ọrun, ti ori rẹ̀ si kan awọsanma.
7Ṣugbọn yio ṣegbe lailai bi igbẹ́ ara rẹ̀; awọn ti o ti ri i rí, yio wipe, On ha dà?
8Yio fò lọ bi alá, a kì yio si ri i, ani a o lé e lọ bi iran oru.
9Oju ti o ti ri i rí pẹlu, kì yio si ri i mọ́, bẹ̃ni ibujoko rẹ̀ kì yio si ri i mọ́.
10Awọn ọmọ rẹ̀ yio ma wá ati ri oju-rere lọdọ talaka, ọwọ rẹ̀ yio si kó ẹrù wọn pada.
11Egungun rẹ̀ kún fun agbara igba ewe rẹ̀, ti yio ba a dubulẹ ninu erupẹ.
12Bi ìwa buburu tilẹ dùn li ẹnu rẹ̀, bi o tilẹ pa a mọ́ nisalẹ ahọn rẹ̀.
13Bi o tilẹ dá a si, ti kò si kọ̀ ọ silẹ, ti o pa a mọ sibẹ li ẹnu rẹ̀,
14Ṣugbọn onjẹ rẹ̀ ninu ikùn rẹ̀ ti yipada, o jasi orõro pamọlẹ ninu rẹ̀;
15O ti gbe ọrọ̀ mì, yio si tun bì i jade, Ọlọrun yio pọ̀ ọ yọ jade lati inu rẹ̀ wá.
16O ti fà oró pamọlẹ mu, ahọn gunte ni yio pa a.
17Kì yio ri odò wọnni, iṣan omi, odò ṣiṣàn oyin ati ti ori amọ́.
18Ohun ti o ṣíṣẹ fun ni yio mu u pada, kì yio si gbe e mì; gẹgẹ bi ọrọ̀ ti o ni, kì yio si yọ̀ ninu rẹ̀.
19Nitoriti o ninilara, o si ti kẹhinda talaka, nitoriti o fi agbara gbe ile ti on kò kọ́.
20Nitori on kò mọ̀ iwa-pẹlẹ ninu ara rẹ̀, ki yio si gbà ninu eyiti ọkàn rẹ̀ fẹ silẹ.
21Ohun kan kò kù fun jijẹ rẹ̀, nitorina ọrọ̀ rẹ̀ kì yio duro pẹ́.
22Ninu titó ìkún rẹ̀ yio wà ninu ihale, ọwọ gbogbo awọn oniyọnu ni yio dide si i lori.
23Yio si ṣe pe, nigbati o ma fi kún inu rẹ̀ yo nì, Ọlọrun yio fa riru ibinu rẹ̀ si i lori, nigbati o ba njẹun lọwọ.
24Yio sá kuro lọwọ ohun-ogun irin, ọrun akọ-irin ni yio ta a po yọ.
25O fà a yọ, o si jade kuro lara, ani idà didan ni njade lati inu orõro wá: ẹ̀ru-nla mbẹ li ara rẹ̀.
26Okunkun gbogbo ni a ti pamọ́ fun iṣura rẹ̀, iná ti a kò fẹ́ ni yio jo o run: yio si jẹ eyi ti o kù ninu agọ rẹ̀ run.
27Ọrun yio fi ẹ̀ṣẹ rẹ̀ hàn, aiye yio si dide duro si i.
28Ibisi ile rẹ̀ yio kọja lọ, ati ohun ini rẹ̀ yio ṣàn danu lọ li ọjọ ibinu Ọlọrun.
29Eyi ni ipin enia buburu lati ọdọ Ọlọrun wá, ati ogún ti a yàn silẹ fun u lati ọdọ Oluwa wá.

Currently Selected:

Job 20: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in