Joh 1:1-4
Joh 1:1-4 YBCV
LI àtetekọṣe li Ọ̀rọ wà, Ọ̀rọ si wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si li Ọ̀rọ na. On na li o wà li àtetekọṣe pẹlu Ọlọrun. Nipasẹ̀ rẹ̀ li a ti da ohun gbogbo; lẹhin rẹ̀ a ko si da ohun kan ninu ohun ti a da. Ninu rẹ̀ ni ìye wà; ìye na si ni imọlẹ̀ araiye.