YouVersion Logo
Search Icon

Jer 9

9
1ORI mi iba jẹ omi, ati oju mi iba jẹ orisun omije, ki emi le sọkun lọsan ati loru fun awọn ti a pa ninu ọmọbinrin enia mi!
2A! emi iba ni buka ero ni iju, ki emi ki o le fi enia mi silẹ, ki nlọ kuro lọdọ wọn! nitori gbogbo nwọn ni panṣaga, ajọ alarekereke enia ni nwọn.
3Nwọn si fà ahọn wọn bi ọrun fun eke; ṣugbọn nwọn kò ṣe akoso fun otitọ lori ilẹ, nitoripe nwọn ti inu buburu lọ si buburu nwọn kò si mọ̀ mi, li Oluwa wi.
4Ẹ mã ṣọra, olukuluku nyin lọdọ aladugbo rẹ̀, ki ẹ má si gbẹkẹle arakunrin karakunrin: nitoripe olukuluku arakunrin fi arekereke ṣẹtan patapata, ati olukuluku aladugbo nsọ̀rọ ẹnilẹhin.
5Ẹnikini ntàn ẹnikeji rẹ̀ jẹ, nwọn kò si sọ otitọ: nwọn ti kọ́ ahọn wọn lati ṣeke, nwọn si ti ṣe ara wọn lãrẹ lati ṣe aiṣedede.
6Ibugbe rẹ mbẹ lãrin ẹ̀tan; nipa ẹ̀tan nwọn kọ̀ lati mọ̀ mi, li Oluwa wi.
7Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, sa wò o, emi o yọ́ wọn, emi o si dán wọn wò, nitori kili emi o ṣe fun ọmọbinrin enia mi.
8Ahọn wọn dabi ọfa ti a ta, o nsọ ẹ̀tan, ẹnikini nfi ẹnu rẹ̀ sọ alafia fun ẹnikeji rẹ̀, ṣugbọn li ọkàn rẹ̀ o ba dè e.
9Emi kì yio ha bẹ̀ wọn wò nitori nkan wọnyi? li Oluwa wi, ọkàn mi kì yio ha gbẹsan lara orilẹ-ède bi iru eyi?
10Fun awọn oke-nla ni emi o gbe ẹkún ati ohùnrere soke, ati ẹkún irora lori papa oko aginju wọnnì, nitoriti nwọn jona, ẹnikan kò le kọja nibẹ, bẹ̃ni a kò gbọ́ ohùn ẹran-ọsin, lati ẹiyẹ oju-ọrun titi de ẹranko ti sa kuro, nwọn ti lọ.
11Emi o sọ Jerusalemu di okiti àlapa, ati iho awọn ikõko, emi o si sọ ilu Juda di ahoro, laini olugbe.
12Tani enia na ti o gbọ́n, ti o moye yi? ati tani ẹniti ẹnu Oluwa ti sọ fun, ki o ba le kede rẹ̀, pe: kili o ṣe ti ilẹ fi ṣegbe, ti o si sun jona bi aginju, ti ẹnikan kò kọja nibẹ?
13Oluwa si wipe, nitoriti nwọn ti kọ̀ ofin mi silẹ ti mo ti gbe kalẹ niwaju wọn, ti nwọn kò si gbà ohùn mi gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò si rin ninu rẹ̀.
14Ṣugbọn nwọn ti rin nipa agidi ọkàn wọn ati nipasẹ Baalimu, ti awọn baba wọn kọ́ wọn:
15Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi; sa wò o, awọn enia yi pãpa ni emi o fi wahala bọ́, emi o si mu wọn mu omi orõro.
16Emi o si tú wọn ka ninu awọn keferi, ti awọn tikarawọn ati baba wọn kò mọ ri, emi o si rán idà si wọn titi emi o fi run wọn.
Àwọn Eniyan Jerusalẹmu kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́
17Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ẹ kiye si i, ki ẹ si pe awọn obinrin ti nṣọfọ, ki nwọn wá; ẹ si ranṣẹ pè awọn obinrin ti o moye, ki nwọn wá.
18Ki nwọn ki o si yara, ki nwọn pohùnrere ẹkun fun wa, ki oju wa ki o le sun omije ẹkun, ati ki ipenpeju wa le tu omi jade.
19Nitori a gbọ́ ohùn ẹkun lati Sioni, pe, A ti pa wa run to! awa dãmu jọjọ, nitoriti a kọ̀ ilẹ yi silẹ, nitoriti ibugbe wa tì wa jade.
20Njẹ ẹnyin obinrin, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹ jẹ ki eti nyin gbọ́ ọ̀rọ ẹnu rẹ̀, ki ẹ si kọ́ ọmọbinrin nyin ni ẹkun, ati ki olukuluku obinrin ki o kọ́ aladugbo rẹ̀ ni arò.
21Nitori iku ti de oju ferese wa, o ti wọ̀ inu ãfin wa, lati ke awọn ọmọ-ọmu kuro ni ita, ati awọn ọmọdekunrin kuro ni igboro.
22Sọ pe, Bayi li Oluwa wi, Okú enia yio ṣubu bi àtan li oko, ati bi ibukunwọ lẹhin olukore, ti ẹnikan ko kojọ.
23Bayi li Oluwa wi, ki ọlọgbọ́n ki o má ṣogo nitori ọgbọ́n rẹ̀, bẹ̃ni ki alagbara ki o má ṣogo nitori agbara rẹ̀, ki ọlọrọ̀ ki o má ṣogo nitori ọrọ̀ rẹ̀.
24Ṣugbọn ki ẹnikẹni ti yio ba ma ṣogo, ki o ṣe e ninu eyi pe: on ni oye, on si mọ̀ mi; pe, Emi li Oluwa ti nṣe ãnu ati idajọ ati ododo li aiye: nitori inu mi dùn ninu ohun wọnyi, li Oluwa wi.
25Sa wò o, ọjọ mbọ̀ li Oluwa wi, ti emi o jẹ gbogbo awọn ti a kọ ni ilà pẹlu awọn alaikọla ni ìya;
26Egipti ati Juda ati Edomu, ati awọn ọmọ Ammoni ati Moabu, pẹlu gbogbo awọn ti ndá òṣu, ti ngbe aginju: nitori alaikọla ni gbogbo orilẹ-ède yi, ṣugbọn gbogbo ile Israeli jẹ alaikọla ọkàn.

Currently Selected:

Jer 9: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in