YouVersion Logo
Search Icon

Jer 52

52
Ìṣubú Jerusalẹmu
1SEDEKIAH jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun nigbati o bẹrẹ si ijọba, o si jọba, ọdun mọkanla ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Hamutali, ọmọbinrin Jeremiah, ara Libna.
2On si ṣe buburu niwaju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiakimu ti ṣe.
3Nitori ibinu Oluwa, o ri bẹ̃ ni Jerusalemu ati Juda, titi o fi tì wọn jade kuro niwaju rẹ̀. Sedekiah si ṣọtẹ si ọba Babeli.
4O si ṣe li ọdun kẹsan ijọba rẹ̀, li oṣu kẹwa, li ọjọ kẹwa oṣu, Nebukadnessari, ọba Babeli de, on ati gbogbo ogun rẹ̀ si Jerusalemu, o si dó tì i, o si mọdi tì i yikakiri.
5A si há ilu na mọ titi di ọdun ikọkanla Sedekiah ọba.
6Ati li oṣu kẹrin li ọjọ kẹsan oṣu, ìyan mu gidigidi ni ilu, tobẹ̃ ti kò si onjẹ fun awọn enia ilẹ na.
7Nigbana ni a fọ ilu, gbogbo awọn ologun si sá, nwọn si jade ni ilu li oru, nwọn gba ọ̀na ẹnu ibode ãrin odi meji, ti o wà li ẹba ọgbà ọba, ṣugbọn awọn ara Kaldea yi ilu ka: nwọn si jade lọ li ọ̀na pẹtẹlẹ.
8Ṣugbọn ogun awọn ara Kaldea lepa ọba, nwọn si ba Sedekiah ni pẹtẹlẹ Jeriko, gbogbo ogun rẹ̀ si tuka kuro lọdọ rẹ̀.
9Nwọn si mu ọba, nwọn si mu u goke wá si ọdọ ọba Babeli ni Ribla, ni ilẹ Hamati; o si sọ̀rọ idajọ lori rẹ̀.
10Ọba Babeli si pa awọn ọmọ Sedekiah niwaju rẹ̀: o pa gbogbo awọn ọlọla Juda pẹlu ni Ribla.
11Pẹlupẹlu ọba Babeli fọ Sedekiah li oju; o si fi ẹ̀wọn dè e, o si mu u lọ si Babeli, o si fi sinu tubu titi di ọjọ ikú rẹ̀.
Wọ́n Wó Tẹmpili Lulẹ̀
12Njẹ li oṣu karun, li ọjọ kẹwa oṣu, ti o jẹ ọdun kọkandilogun Nebukadnessari, ọba Babeli, ni Nebusaradani, balogun iṣọ, ti o nsin ọba Babeli, wá si Jerusalemu.
13O si kun ile Oluwa, ati ile ọba; ati gbogbo ile Jerusalemu, ati gbogbo ile nla li o fi iná sun.
14Ati gbogbo ogun awọn ara Kaldea, ti nwọn wà pẹlu balogun iṣọ, wó gbogbo odi Jerusalemu lulẹ yikakiri.
15Nebusaradani, balogun iṣọ, si kó ninu awọn talaka awọn enia, ati iyokù awọn enia ti o kù ni ilu, ni igbekun lọ si Babeli, pẹlu awọn ti o ya lọ, ti o si ya tọ̀ ọba Babeli lọ, ati iyokù awọn ọ̀pọ enia na.
16Nebusaradani, balogun iṣọ, si fi ninu awọn talaka ilẹ na silẹ lati mã ṣe alabojuto ajara ati lati ma ṣe alaroko.
17Ati ọwọ̀n idẹ wọnni ti mbẹ lẹba ile Oluwa, ati ijoko wọnni ati agbada idẹ nla ti o wà ni ile Oluwa ni awọn ara Kaldea fọ tũtu, nwọn si kó gbogbo idẹ wọn lọ si Babeli.
18Ati ìkoko wọnni, ati ọkọ́ wọnni, ati alumagaji fitila wọnni, ati ọpọ́n wọnni, ati ṣibi wọnni, ati gbogbo ohun elo idẹ wọnni ti nwọn fi nṣiṣẹ isin, ni nwọn kó lọ.
19Ati awo-koto wọnni, ati ohun ifọnna wọnni, ati ọpọ́n wọnni, ati ìkoko wọnni, ati ọpa fitila wọnni, ati ṣibi wọnni, ati ago wọnni, eyiti iṣe ti wura, wura, ati eyiti iṣe ti fadaka, fadaka, ni balogun iṣọ kó lọ.
20Awọn ọwọ̀n meji, agbada nla kan, ati awọn malu idẹ mejila ti o wà labẹ ijoko, ti Solomoni ọba, ti ṣe fun ile Oluwa: idẹ gbogbo ohun-elo wọnyi alaini iwọ̀n ni.
21Ati ọwọ̀n mejeji, giga ọwọ̀n kan ni igbọnwọ mejidilogun; okùn igbọnwọ mejila si yi i ka; ninipọn wọn si jẹ ika mẹrin, nwọn ni iho ninu.
22Ati ọna-ori idẹ wà lori rẹ̀; giga ọna-ori kan si ni igbọnwọ marun, pẹlu iṣẹ wiwun ati pomegranate lara ọna ori wọnni yikakiri, gbogbo rẹ̀ jẹ ti idẹ: gẹgẹ bi wọnyi ni ọwọ̀n ekeji pẹlu, ati pomegranate rẹ̀.
23Pomegranate mẹrindilọgọrun li o wà ni gbangba: gbogbo pomegranate lori iṣẹ wiwun na jẹ ọgọrun yikakiri.
Wọ́n Kó Àwọn Ará Juda ní Ìgbèkùn Lọ sí Babiloni
24Balogun iṣọ si mu Seraiah, olori ninu awọn alufa, ati Sefaniah, alufa keji, ati awọn oluṣọ iloro mẹta:
25Ati lati inu ilu o mu iwẹfa kan, ti o ni itọju awọn ologun; ati awọn ọkunrin meje ti nwọn nduro niwaju ọba, ti a ri ni ilu na; ati akọwe olori ogun ẹniti ntò awọn enia ilẹ na; ati ọgọta enia ninu awọn enia ilẹ na, ti a ri li ãrin ilu na.
26Nebusaradani, balogun iṣọ, si mu wọn, o si mu wọn tọ̀ ọba Babeli wá si Ribla.
27Ọba Babeli si kọlu wọn, o si pa wọn ni Ribla ni ilẹ Hamati. Bẹ̃li a mu Juda kuro ni ilẹ rẹ̀.
28Eyi li awọn enia ti Nebukadnessari kó ni ìgbekun lọ: li ọdun keje, ẹgbẹdogun o le mẹtalelogun ara Juda.
29Li ọdun kejidilogun Nebukadnessari, o kó ẹgbẹrin enia o le mejilelọgbọn ni igbèkun lati Jerusalemu lọ:
30Li ọdun kẹtalelogun Nebukadnessari, Nebusaradani, balogun iṣọ, kó ọtadilẹgbẹrin enia o di marun awọn ara Juda ni igbekun lọ: gbogbo awọn enia na jẹ ẹgbẹtalelogun.
31O si ṣe, li ọdun kẹtadilogoji Jehoiakimu, ọba Juda, li oṣu kejila, li ọjọ kẹdọgbọn oṣu, Efil-Merodaki, ọba Babeli, li ọdun ekini ijọba rẹ̀, o gbe ori Jehoiakimu, ọba Juda, soke, o si mu u jade ninu ile túbu.
32O si sọ̀rọ rere fun u, o si gbe itẹ rẹ̀ ga jù itẹ awọn ọba ti o wà pẹlu rẹ̀ ni Babeli.
33O si parọ aṣọ túbu rẹ̀: o si njẹun nigbagbogbo niwaju rẹ̀ ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀.
34Ati ipin onjẹ rẹ̀, ipin onjẹ igbagbogbo, ti ọba Babeli nfi fun u lojojumọ ni ipin tirẹ̀, titi di ọjọ ikú rẹ̀, ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀.

Currently Selected:

Jer 52: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in