Jer 43
43
Wọ́n Mú Jeremiah Lọ sí Ijipti
1O si ṣe, nigbati Jeremiah pari ọ̀rọ isọ fun gbogbo awọn enia, ani gbogbo ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun wọn, eyiti Oluwa Ọlọrun wọn ti rán a si wọn, ani gbogbo ọ̀rọ wọnyi.
2Nigbana ni Asariah, ọmọ Hoṣaiah, ati Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn agberaga enia, wi fun Jeremiah pe, Iwọ ṣe eke! Oluwa, Ọlọrun wa, kò ran ọ lati wipe, Ẹ má lọ si Egipti lati ṣatipo nibẹ:
3Ṣugbọn Baruku, ọmọ Neriah, li o fi ọ̀rọ si ọ li ẹnu si wa, nitori lati fi wa le awọn ara Kaldea lọwọ, lati pa wa ati lati kó wa ni igbekun lọ si Babeli.
4Bẹ̃ni Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun, ati gbogbo awọn enia, kò gbà ohùn Oluwa gbọ́, lati má gbe ilẹ Juda,
5Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun, si mu gbogbo iyokù Juda, ti nwọn pada lati gbogbo orilẹ-ède wá, ni ibi ti a ti le wọn si, lati ma gbe ilẹ Juda;
6Awọn ọkunrin, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọde, ati awọn ọmọbinrin ọba, ati gbogbo enia ti Nebusaradani, balogun iṣọ, ti kù silẹ lọdọ Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ati Jeremiah woli, ati Baruku, ọmọ Neriah,
7Nwọn si wá si ilẹ Egipti: nitori nwọn kò gbà ohùn Oluwa gbọ́: bayi ni nwọn wá si Tafanesi.
8Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá ni Tafanesi, wipe,
9Mu okuta nla li ọwọ rẹ ki o si fi wọn pamọ sinu amọ̀, ni ile-iná briki ti o wà ni ẹnu-ọ̀na ile Farao ni Tafanesi, li oju awọn ọkunrin Juda.
10Ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi, pe, wò o, emi o ranṣẹ, emi o si mu Nebukadnessari, ọba Babeli, iranṣẹ mi, emi o si gbe itẹ rẹ̀ kalẹ lori okuta wọnyi, ti emi ti fi pamọ; on o si tẹ itẹ ọla rẹ̀ lori wọn.
11Nigbati o ba si de, on o kọlu ilẹ Egipti, on o si fi ti ikú, fun ikú: ti igbekun, fun igbekun; ati ti idà, fun idà.
12Emi o si dá iná kan ni ile awọn oriṣa Egipti; on o si sun wọn, yio si kó wọn lọ; on o si fi ilẹ Egipti wọ ara rẹ̀ laṣọ gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ti iwọ̀ aṣọ rẹ̀; yio si jade lati ibẹ lọ li alafia.
13Yio si fọ́ ere ile-õrùn, ti o wà ni ilẹ Egipti tũtu, yio si fi iná kun ile awọn oriṣa awọn ara Egipti.
Currently Selected:
Jer 43: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.