YouVersion Logo
Search Icon

Jer 25

25
Àwọn Ọ̀tá láti Ìhà Àríwá
1Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá nitori gbogbo enia Juda, li ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọbà Juda, ti iṣe ọdun ikini Nebukadnessari, ọba Babeli.
2Eyi ti Jeremiah, woli, sọ fun gbogbo enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu wipe:
3Lati ọdun kẹtala Josiah, ọmọ Amoni, ọba Juda, titi di oni-oloni, eyini ni, ọdun kẹtalelogun, ọ̀rọ Oluwa ti tọ mi wá, emi si ti sọ fun nyin, emi ndide ni kutukutu, emi nsọ, ṣugbọn ẹnyin kò feti si i.
4Oluwa si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli si nyin, o ndide ni kutukutu lati rán wọn, ṣugbọn ẹnyin kò feti si i, bẹ̃ni ẹnyin kò tẹ eti nyin silẹ lati gbọ́.
5Wipe, ẹ sa yipada, olukuluku kuro ni ọ̀na buburu rẹ̀, ati kuro ni buburu iṣe nyin, ẹnyin o si gbe ilẹ ti Oluwa ti fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin lai ati lailai.
6Ki ẹ má si tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati ma sìn wọn, ati lati ma foribalẹ fun wọn, ki ẹ má si ṣe fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu, emi kì yio si ṣe nyin ni ibi.
7Ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́ temi, li Oluwa wi, ki ẹnyin le fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu si ibi ara nyin.
8Nitorina, bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nitori ti ẹnyin kò gbọ́ ọ̀rọ mi.
9Sa wò o, emi o ranṣẹ, emi o si mu gbogbo idile orilẹ-ède ariwa wá, li Oluwa wi, emi o si ranṣẹ si Nebukadnessari, ọba Babeli, ọmọ-ọdọ mi, emi o si mu wọn wá si ilẹ yi, ati olugbe rẹ̀, ati si gbogbo awọn orilẹ-ède yikakiri, emi o si pa wọn patapata, emi o si sọ wọn di iyanu ati iyọṣuti si, ati ahoro ainipẹkun.
10Pẹlupẹlu emi o mu ohùn inudidùn, ati ohùn ayọ, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo, iro okuta ọlọ, ati imọlẹ fitila kuro lọdọ wọn.
11Gbogbo ilẹ yi yio si di iparun ati ahoro: orilẹ-ède wọnyi yio si sìn ọba Babeli li ãdọrin ọdun.
12Yio si ṣe, nigbati ãdọrin ọdun ba pari tan, li emi o bẹ̀ ọba Babeli, ati orilẹ-ède na, ati ilẹ awọn ara Kaldea wò, nitori ẹ̀ṣẹ wọn; li Oluwa wi, emi o si sọ ọ di ahoro titi lai.
13Emi o si mu gbogbo ọ̀rọ mi wá sori ilẹ na, ti mo ti sọ si i: ani gbogbo eyiti a ti kọ sinu iwe yi, eyiti Jeremiah ti sọtẹlẹ si gbogbo orilẹ-ède.
14Nitoriti awọn wọnyi pẹlu yio mu ki orilẹ-ède pupọ, ati awọn ọba nla sìn wọn: emi o san a fun wọn gẹgẹ bi iṣe wọn ati pẹlu gẹgẹ bi iṣẹ ọwọ wọn.
Ìdájọ́ OLUWA lórí Àwọn Orílẹ̀-èdè náà
15Nitori bayi ni Oluwa Ọlọrun Israeli wi fun mi: Gba ago ọti-waini ibinu mi yi kuro lọwọ mi, ki o si jẹ ki gbogbo orilẹ-ède ti emi o rán ọ si, mu u.
16Ki nwọn mu, ki nwọn si ma ta gbọ̀ngbọn, ki nwọn si di aṣiwere, nitori idà ti emi o rán si ãrin wọn.
17Nigbana ni mo gba ago na li ọwọ Oluwa, emi si jẹ ki gbogbo orilẹ-ède, ti Oluwa rán mi si, mu u.
18Ani Jerusalemu ati ilu Juda wọnni, ati awọn ọba wọn pẹlu awọn ijoye, lati sọ wọn di ahoro, idãmu, ẹsin, ati egún, gẹgẹ bi o ti ri loni.
19Farao, ọba Egipti, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo enia rẹ̀.
20Ati gbogbo awọn enia ajeji, ati gbogbo ọba ilẹ Usi, gbogbo ọba ilẹ Filistia, ati Aṣkeloni, ati Gasa, ati Ekroni, ati awọn iyokù Aṣdodi,
21Edomu, ati Moabu, ati awọn ọmọ Ammoni,
22Ati gbogbo awọn ọba Tire, ati gbogbo awọn ọba Sidoni, ati awọn ọba erekuṣu wọnni ti mbẹ ni ikọja okun,
23Dedani, ati Tema, ati Busi, ati gbogbo awọn ti nda òṣu.
24Ati gbogbo awọn ọba Arabia, pẹlu awọn ọba awọn enia ajeji ti ngbe inu aginju.
25Ati gbogbo awọn ọba Simri, ati gbogbo awọn ọba Elamu, ati gbogbo awọn ọba Medea.
26Ati gbogbo awọn ọba ariwa, ti itosi ati ti ọ̀na jijin, ẹnikini pẹlu ẹnikeji rẹ̀, ati gbogbo ijọba aiye, ti mbẹ li oju aiye, ọba Ṣeṣaki yio si mu lẹhin wọn.
27Iwọ o si wi fun wọn pe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, Ẹ mu, ki ẹ si mu amuyo, ki ẹ bì, ki ẹ si ṣubu, ki ẹ má si le dide mọ́, nitori idà ti emi o rán sãrin nyin.
28Yio si ṣe, bi nwọn ba kọ̀ lati gba ago lọwọ rẹ lati mu, ni iwọ o si wi fun wọn pe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ni mimu ẹnyin o mu!
29Sa wò o, nitori ti emi bẹrẹ si imu ibi wá sori ilu na ti a pè li orukọ mi, ẹnyin fẹ ijẹ alaijiya? ẹnyin kì yio ṣe alaijiya: nitori emi o pè fun idà sori gbogbo olugbe aiye, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
30Njẹ iwọ sọ asọtẹlẹ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun wọn, ki o si wi fun wọn pe, Oluwa yio kọ lati oke wá, yio si fọ ohùn rẹ̀ lati ibugbe rẹ̀ mimọ́, ni kikọ, yio kọ sori ibugbe rẹ̀, yio pariwo sori gbogbo olugbe aiye, bi awọn ti ntẹ ifunti.
31Igbe kan yio wá titi de opin ilẹ aiye; nitori Oluwa ni ijà ti yio ba awọn orilẹ-ède ja, yio ba gbogbo ẹran-ara wijọ, yio fi awọn oluṣe-buburu fun idà, li Oluwa wi.
32Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, sa wò o, ibi yio jade lati orilẹ-ède de orilẹ-ède, ìji nlanla yio ru soke lati agbegbe aiye.
33Awọn ti Oluwa pa yio wà li ọjọ na lati ipẹkun kini aiye titi de ipẹkun keji aiye, a kì yio ṣọ̀fọ wọn, a kì yio ko wọn jọpọ, bẹ̃ni a kì yio sin wọn, nwọn o di àtan lori ilẹ.
34Ke! ẹnyin oluṣọ-agutan! ki ẹ si sọkun! ẹ fi ara nyin yilẹ ninu ẽru, ẹnyin ọlọla agbo-ẹran! nitori ọjọ a ti pa nyin ati lati tú nyin ka pe, ẹnyin o si ṣubu bi ohun-elo iyebiye.
35Sisa kì yio si fun awọn oluṣọ-agutan, bẹ̃ni asalà kì yio si fun awọn ọlọla agbo-ẹran.
36Ohùn ẹkun awọn oluṣọ-agutan, ati igbe awọn ọlọla agbo-ẹran li a o gbọ́: nitori Oluwa bà papa-oko tutu wọn jẹ.
37Ibùgbe alafia li o di ahoro, niwaju ibinu kikan Oluwa.
38O ti fi pantiri rẹ̀ silẹ bi kiniun nitori ti ilẹ wọn di ahoro, niwaju ibinu idà aninilara, ati niwaju ibinu kikan rẹ̀.

Currently Selected:

Jer 25: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in