Jer 17
17
Ẹ̀ṣẹ̀ ati Ìjìyà Juda
1Ẹ̀ṢẸ Juda ni a fi kalamu irin kọ, a fi ṣonṣo okuta adamante gbẹ ẹ sori walã aiya wọn, ati sori iwo pẹpẹ nyin.
2Bi awọn ọmọ wọn ba ranti pẹpẹ wọn, ati ere òriṣa wọn, lẹba igi tutu, ati ibi giga wọnni.
3Oke mi ti o wà ni papa! emi o fi ohun-ini rẹ pẹlu ọrọ̀ rẹ gbogbo fun ijẹ, ati ibi giga rẹ, nitori ẹ̀ṣẹ yi gbogbo àgbegbe rẹ ka.
4Iwọ fun ara rẹ ni yio jọ̃ ogún rẹ lọwọ, ti mo ti fi fun ọ, emi o mu ọ sìn awọn ọta rẹ ni ilẹ ti iwọ kò mọ̀ ri: nitoriti ẹnyin ti tinabọ ibinu mi, ti yio jo lailai.
Oríṣìíríṣìí Ọ̀rọ̀
5Bayi li Oluwa wi: Egbe ni fun ẹniti o gbẹkẹle enia, ti o fi ẹlẹran ara ṣe apá rẹ̀, ẹniti ọkàn rẹ̀ si ṣi kuro lọdọ Oluwa!
6Nitoripe yio dabi alaini ni aginju, ti kò si ri pe rere mbọ̀: ṣugbọn yio gbe ibi iyangbẹ ilẹ wọnni ni aginju, ilẹ iyọ̀ ti a kì igbe inu rẹ̀.
7Ibukun ni fun ẹniti o gbẹkẹle Oluwa, ti o si fi Oluwa ṣe igbẹkẹle rẹ̀!
8Yio si dabi igi ti a gbìn lẹba omi, ti o nà gbòngbo rẹ̀ lẹba odò, ti kì yio bẹ̀ru bi õru ba de, ṣugbọn ewe rẹ̀ yio tutu, kì yio si ni ijaya ni ọdun ọ̀dá, bẹ̃ni kì yio dẹkun lati ma so eso.
9Ọkàn enia kún fun ẹ̀tan jù ohun gbogbo lọ, o si buru jayi! tani o le mọ̀ ọ?
10Emi, Oluwa, ni iwá awari ọkàn enia, emi ni ndan inu wò, ani lati fi fun olukuluku gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀, ati gẹgẹ bi eso iṣe rẹ̀.
11Bi aparo ti isaba lori ẹyin ti kò yin, bẹ̃ gẹgẹ ni ẹniti o kó ọrọ̀ jọ, ṣugbọn kì iṣe ni ododo; yio fi i silẹ lagbedemeji ọjọ rẹ̀, ati ni opin rẹ̀ yio jẹ aṣiwere.
12Itẹ́ ogo! ibi giga lati ipilẹsẹ ni ibi ile mimọ́ wa!
13Oluwa ni ireti Israeli! gbogbo awọn ti o kọ̀ ọ silẹ yio dãmu, awọn ti o yẹ̀ kuro lọdọ mi, ni a o kọ orukọ wọn sinu ẽkuru, si ori ilẹ, nitori nwọn ti kọ̀ Oluwa silẹ, orisun omi ìye.
Jeremiah Bèèrè fún Ìrànlọ́wọ́ OLUWA
14Wò mi sàn, Oluwa, emi o si sàn! gbà mi là, emi o si là, nitori iwọ ni iyìn mi!
15Sa wò o, nwọn wi fun mi pe, Nibo ni ọ̀rọ Oluwa wà? jẹ ki o wá wayi.
16Bi o ṣe ti emi ni, emi kò yara kuro ki emi má ṣe oluṣọ-agutan, lẹhin rẹ, bẹ̃ni emi kò bere ọjọ ipọnju, iwọ mọ̀: eyiti o jade li ète mi, o ti hàn niwaju rẹ.
17Máṣe di ibẹ̀ru fun mi! iwọ ni ireti mi li ọjọ ibi!
18Jẹ ki oju ki o tì awọn ti o nṣe inunibini si mi, ṣugbọn má jẹ ki oju ki o tì mi: jẹ ki nwọn ki o dãmu, ṣugbọn máṣe jẹ ki emi ki o dãmu: mu ọjọ ibi wá sori wọn, ki o si fi iparun iṣẹpo meji pa wọn run.
Pípa Ọjọ́ Ìsinmi Mọ́
19Bayi li Oluwa wi fun mi; Lọ, ki o si duro ni ẹnu-ọ̀na awọn enia nibi ti awọn ọba Juda nwọle, ti nwọn si njade, ati ni gbogbo ẹnu-bode Jerusalemu.
20Ki o si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọba Juda ati gbogbo Juda, ati gbogbo ẹnyin olugbe Jerusalemu, ti o nkọja ninu ẹnu-bode wọnyi.
21Bayi li Oluwa wi, Ẹ kiyesi li ọkàn nyin, ki ẹ máṣe ru ẹrù li ọjọ isimi, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe mu u wá ninu ẹnu-bode Jerusalemu:
22Bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe gbe ẹrù jade kuro ninu ile nyin li ọjọ isimi, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe iṣẹkiṣẹ, ṣugbọn ki ẹ yà ọjọ isimi si mimọ́, gẹgẹ bi mo ti paṣẹ fun awọn baba nyin.
23Ṣugbọn nwọn kò gbọ́, nwọn kò si tẹti silẹ, nwọn mu ọrun wọn le, ki nwọn ki o má ba gbọ́, ati ki nwọn o má bà gba ẹ̀kọ́.
24Yio si ṣe bi ẹnyin ba tẹtisilẹ gidigidi si mi, li Oluwa wi, ti ẹ kò ba ru ẹrù kọja ni ẹnu-bode ilu yi li ọjọ isimi, ti ẹ ba si yà ọjọ isimi si mimọ, ti ẹ kò si ṣe iṣẹkiṣẹ ninu rẹ̀,
25Nigbana ni nwọn o wọ ẹnu-bode ilu yi, ani ọba, ati ijoye ti o joko lori itẹ Dafidi, awọn ti ngun kẹ̀kẹ ati ẹṣin, awọn wọnyi pẹlu ijoye wọn, awọn ọkunrin Juda, ati olugbe Jerusalemu: nwọn o si ma gbe ilu yi lailai.
26Nwọn o si wá lati ilu Juda wọnni, ati lati àgbegbe Jerusalemu yikakiri, ati lati ilẹ Benjamini, lati pẹtẹlẹ, ati lati oke, ati lati gusu wá, nwọn o si mu ọrẹ-ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹran ati turari, ati awọn wọnyi ti o mu iyìn wá si ile Oluwa.
27Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbọ́ ti emi, lati ya ọjọ isimi si mimọ́, ti ẹ kò si ru ẹrù, ti ẹ kò tilẹ wọ ẹnu-bode Jerusalemu li ọjọ isimi; nigbana ni emi o da iná ni ẹnu-bode wọnni, yio si jo ãfin Jerusalemu run, a kì o si pa a.
Currently Selected:
Jer 17: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.