A. Oni Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé Àwọn Onidajọ kún fún oríṣìíríṣìí ìtàn àkókò tí àwọn ọmọ Israẹli ń tàpá sí àṣẹ Ọlọrun, láti ìgbà tí wọ́n ti kó àwọn ará Kenaani lẹ́rú, títí di ìgbà tí wọ́n fi ètò ọba jíjẹ lélẹ̀. Àwọn ìtàn inú ìwé yìí sọ nípa ohun tí àwọn akọni aṣiwaju orílẹ̀-èdè náà, tí wọn ń pè ní “adájọ́”, ṣe ní àkókò tí olukuluku wọn wà ní ipò aṣiwaju. Jagunjagun ni ọpọlọpọ àwọn adájọ́ wọnyi, wọn kì í ṣe amòfin. A lè rí ìtàn Samsoni tí ó jẹ́ olókìkí jù láàrin wọn, kà ní orí 13-16.
Ẹ̀kọ́ pataki tí a rí kọ́ ninu ìwé yìí ni pé, ní àkókò tí àwọn ọmọ Israẹli bá tẹ̀lé òfin Ọlọrun, wọn a máa wà ní ìrọ̀rùn; ṣùgbọ́n ní àkókò tí wọ́n bá tàpá sí àṣẹ rẹ̀, ìnira ńlá níí máa dé bá wọn. Sibẹsibẹ, nígbà tí wọ́n bá wà ninu ìnira ati ìpọ́njú nítorí pé wọ́n ṣẹ̀ sí Ọlọrun, bí wọ́n bá ronupiwada tí wọ́n sì tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn, Ọlọrun a máa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn, a sì máa gbà wọ́n.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Àwọn nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ títí di ìgbà tí Joṣua kú 1:1—2:10
Àwọn adájọ́ ilẹ̀ Israẹli 2:11—16:31
Oríṣìíríṣìí ìṣẹ̀lẹ̀ 17:1—21:25
Currently Selected:
A. Oni Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.