A. Oni 13
13
Ìbí Samsoni
1AWỌN ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti iṣe buburu li oju OLUWA; OLUWA si fi wọn lé awọn Filistini li ọwọ́ li ogoji ọdún.
2Ọkunrin kan ara Sora si wà, ti iṣe idile Dani, orukọ rẹ̀ si ni Manoa, obinrin rẹ̀ si yàgan, kò si bimọ.
3Angeli OLUWA si farahàn obinrin na, o si wi fun u pe, Sá kiyesi i, iwọ yàgan, iwọ kò si bimọ: ṣugbọn iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan.
4Njẹ nitorina kiyesara, emi bẹ̀ ọ, máṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, má si ṣe jẹ ohun aimọ́ kan:
5Nitori kiyesi i, iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan; ki abẹ ki o má ṣe kàn a lori: nitori Nasiri Ọlọrun li ọmọ na o jẹ́ lati inu wá: on o bẹ̀rẹsi gbà Israeli li ọwọ́ awọn Filistini.
6Nigbana obinrin na wá, o si rò fun ọkọ rẹ̀, wipe, Enia Ọlọrun kan wá sọdọ mi, irí rẹ̀ si dabi irí angeli Ọlọrun, o ní ẹ̀ru gidigidi; ṣugbọn emi kò bilère ibiti o ti wá, bẹ̃li on kò si sọ orukọ rẹ̀ fun mi:
7Ṣugbọn on sọ fun mi pe, Kiyesi i, iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan; nitorina má ṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, bẹ̃ni ki o má ṣe jẹ ohun aimọ́ kan: nitori Nasiri Ọlọrun li ọmọ na o jẹ́ lati inu wá titi di ọjọ́ ikú rẹ̀.
8Nigbana ni Manoa bẹ̀ OLUWA, o si wipe, OLUWA, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki enia Ọlọrun, ti iwọ rán tun tọ̀ wa wá, ki o le kọ́ wa li ohun ti awa o ṣe si ọmọ na ti a o bi.
9Ọlọrun si gbọ ohùn Manoa; angeli Ọlọrun na si tun tọ̀ obinrin na wá, bi on ti joko ninu oko; ṣugbọn Manoa ọkọ rẹ̀ kò sí nibẹ̀ pẹlu rẹ̀.
10Obinrin na si yara kánkán, o si sure, o si sọ fun ọkọ rẹ̀, o si wi fun u pe, Kiyesi i, ọkunrin ti o tọ̀ mi wá ni ijelo farahàn mi.
11Manoa si dide, o si tẹle aya rẹ̀, o si wá sọdọ ọkunrin na, o si bi i pe, Iwọ li ọkunrin na ti o bá obinrin na sọ̀rọ? On si wipe, Emi ni.
12Manoa si wipe, Njẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o ṣẹ: ìwa ọmọ na yio ti jẹ́, iṣẹ rẹ̀ yio ti jẹ́?
13Angeli OLUWA si wi fun Manoa pe, Ni gbogbo eyiti mo sọ fun obinrin na ni ki o kiyesi.
14Ki o má ṣe jẹ ohun kan ti o ti inu àjara wá, ki o má ṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, bẹ̃ni kò gbọdọ jẹ ohun aimọ́ kan; gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun u ni ki o kiyesi.
15Manoa si wi fun angeli OLUWA na pe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki awa ki o da ọ duro, titi awa o si fi pèse ọmọ ewurẹ kan fun ọ.
16Angeli OLUWA na si wi fun Manoa pe, Bi iwọ tilẹ da mi duro, emi ki yio jẹ ninu àkara rẹ: bi iwọ o ba si ru ẹbọ sisun kan, OLUWA ni ki iwọ ki o ru u si. Nitori Manoa kò mọ̀ pe angeli OLUWA ni iṣe.
17Manoa si wi fun angeli OLUWA na pe, Orukọ rẹ, nitori nigbati ọ̀rọ rẹ ba ṣẹ ki awa ki o le bọlá fun ọ?
18Angeli OLUWA na si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi mbère orukọ mi, kiyesi i, Iyanu ni.
19Manoa si mú ọmọ ewurẹ kan pẹlu ẹbọ ohunjijẹ, o si ru u lori apata kan si OLUWA: angeli na si ṣe ohun iyanu, Manoa ati obinrin rẹ̀ si nwò o.
20O si ṣe ti ọwọ́-iná na nlọ soke ọrun lati ibi-pẹpẹ na wá, angeli OLUWA na si gòke ninu ọwọ́-iná ti o ti ibi-pẹpẹ jade wá. Manoa ati aya rẹ̀ si nwò o; nwọn si dojubolẹ.
21Ṣugbọn angeli OLUWA na kò si tun farahàn fun Manoa tabi aya rẹ̀ mọ́. Nigbana ni Manoa to wa mọ̀ pe, angeli OLUWA ni iṣe.
22Manoa si wi fun aya rẹ̀ pe, Kikú li awa o kú yi, nitoriti awa ti ri Ọlọrun.
23Aya rẹ̀ si wi fun u pe, Ibaṣepe o wù OLUWA lati pa wa, on kì ba ti gbà ẹbọ sisun ati ẹbọ ohunjijẹ li ọwọ́ wa, bẹ̃li on kì ba ti fi gbogbo nkan wọnyi hàn wa, bẹ̃li on kì ba ti sọ̀rọ irú nkan wọnyi fun wa li akokò yi.
24Obinrin na si bi ọmọkunrin kan, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Samsoni: ọmọ na si dàgba, OLUWA si bukún u.
25Ẹmi OLUWA si bẹ̀rẹsi ṣiṣẹ ninu rẹ̀ ni Mahane-dani, li agbedemeji Sora ati Eṣtaolu.
Currently Selected:
A. Oni 13: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.