Isa 59
59
Wolii Lòdì sí Ẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Eniyan
1KIYESI i, ọwọ́ Oluwa kò kuru lati gbàni, bẹ̃ni eti rẹ̀ kò wuwo ti kì yio fi gbọ́.
2Ṣugbọn aiṣedede nyin li o yà nyin kuro lọdọ Ọlọrun nyin, ati ẹ̀ṣẹ nyin li o pa oju rẹ̀ mọ kuro lọdọ nyin, ti on kì yio fi gbọ́.
3Nitori ọwọ́ nyin di alaimọ́ fun ẹ̀jẹ, ati ika nyin fun aiṣedede, ète nyin nsọ eke, ahọn nyin nsọ ibi jade.
4Kò si ẹniti nwá ẹtọ́, bẹ̃ni kò si ẹniti ndajọ ni otitọ: nwọn gbẹkẹle ohun asan, nwọn nsọ eke; nwọn loyun ikà, nwọn mbí iparun.
5Nwọn npa ẹyin pamọlẹ, nwọn nhun okùn alantakùn: ẹniti o jẹ ninu ẹyin wọn yio kú, ati eyi ti a tẹ̀ bẹ́ ọká jade.
6Okùn wọn kì yio di ẹwù, bẹ̃ni nwọn kì yio fi iṣẹ wọn bò ara wọn: iṣẹ wọn ni iṣẹ ikà, iṣe ipá si mbẹ li ọwọ́ wọn.
7Ẹsẹ wọn sare si ibi, nwọn si yara lati tajẹ̀ alaiṣẹ̀ silẹ: èro wọn èro ibi ni; ibajẹ ati iparun mbẹ ni ipa wọn.
8Ọ̀na alafia ni nwọn kò mọ̀; kò si idajọ kan ninu ìrin wọn: nwọn ṣe ipa-ọ̀na wiwọ́ fun ara wọn: ẹnikẹni ti o ba tọ̀ ọ kì yio mọ̀ alafia.
Àwọn Eniyan Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ wọn
9Nitori na ni idajọ jìna si wa, bẹ̃ni ododo kì yio le wa bá, awa duro dè imọlẹ, ṣugbọn kiyesi i, okunkun, a duro de imọlẹ, ṣugbọn a nrin ninu okunkun.
10A nwá ogiri kiri bi afọju, awa si nwá ọ̀na bi ẹniti kò li oju: awa nkọsẹ lọsangangan bi ẹnipe loru, ni ibi ahoro, bi okú.
11Gbogbo wa mbu bi beari, awa si npohunrere bi oriri: awa wò ọ̀na fun idajọ, ṣugbọn kò si, fun igbala, ṣugbọn o jìna si wa.
12Nitori irekọja wa npọ̀ si i niwaju rẹ, ẹ̀ṣẹ wa njẹri gbè wa, nitori irekọja wa mbẹ lọdọ wa, niti aiṣedede wa, awa mọ̀ wọn.
13Ni rirekọja ati ṣiṣeke si Oluwa, ifaṣẹhin kuro lọdọ Ọlọrun wa, isọrọ inilara ati ìṣọtẹ, liloyun ati sisọrọ eke lati inu jade wá.
14A dá idajọ pada, ẹtọ́ si duro lokerè rére: otitọ ṣubu ni igboro, aiṣègbe kò le wọ ile.
15Otitọ kò si, ẹniti o si kuro ninu ibi o sọ ara rẹ̀ di ijẹ: Oluwa si ri i, o si buru loju rẹ̀, ti idajọ kò si.
OLUWA Ṣetán láti Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀
16O si ri pe kò si ẹnikan, ẹnu si yà a pe onipẹ̀ kò si, nitorina apá rẹ̀ mu igbala fun u wá; ati ododo rẹ̀, on li o gbé e ró.
17O si gbe ododo wọ̀ bi awo-aiya, o si fi aṣibori irin igbala dé ara rẹ̀ lori: o wọ̀ ẹwù igbẹsan li aṣọ, a si fi itara wọ̀ ọ bi agbada.
18Gẹgẹ bi ere iṣe wọn, bẹ̃ gẹgẹ ni yio san a fun wọn, irunú fun awọn ọta rẹ̀, igbẹsan fun awọn ọta rẹ̀; fun awọn erekuṣu yio san ẹsan.
19Nwọn o si bẹ̀ru orukọ Oluwa lati ìwọ-õrùn wá, ati ogo rẹ̀ lati ilà-õrun wá. Nigbati ọta yio de bi kikún omi, Ẹmi Oluwa yio gbe ọpágun soke si i.
20Olurapada yio si wá si Sioni, ati sọdọ awọn ti o yipada kuro ninu irekọja ni Jakobu, ni Oluwa wi.
21Niti emi, eyi ni majẹmu mi pẹlu wọn, ni Oluwa wi; Ẹmi mi ti o wà lara rẹ̀, ati ọ̀rọ mi ti mo fi si ẹnu rẹ, kì yio kuro li ẹnu rẹ, tabi kuro lẹnu iru-ọmọ rẹ, tabi kuro lẹnu iru-ọmọ ọmọ rẹ, ni Oluwa wi, lati isisiyi lọ ati lailai.
Currently Selected:
Isa 59: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.