Isa 55:1-2
Isa 55:1-2 YBCV
NJẸ gbogbo ẹniti ongbẹ ngbẹ, ẹ wá sibi omi, ati ẹniti kò li owo; ẹ wá, ẹ rà, ki ẹ si jẹ; lõtọ, ẹ wá, ẹ rà ọti-waini ati wàra, laini owo ati laidiyele. Nitori kini ẹ ṣe nná owo fun eyiti kì iṣe onjẹ? ati lãla nyin fun eyi ti kì itẹnilọrun? ni gbigbọ́, ẹ gbọ́ t'emi, ki ẹ si jẹ eyi ti o dara, si jẹ ki inu nyin dùn ninu ọra.