Isa 49
49
Israẹli, Ìmọ́lẹ̀ fún Ayé
1Ẹ gbọ ti emi, ẹnyin erekùṣu; ki ẹ si fi etí silẹ, ẹnyin enia lati ọ̀na jijìn wá; Oluwa ti pè mi lati inu wá; lati inu iya mi li o ti dá orukọ mi.
2O si ti ṣe ẹnu mi bi idà mimú; ninu ojìji ọwọ́ rẹ̀ li o ti pa mi mọ, o si sọ mi di ọfà didán; ninu apó rẹ̀ li o ti pa mi mọ́;
3O si wi fun mi pe, Iwọ ni iranṣẹ mi, Israeli, ninu ẹniti a o yìn mi logo.
4Nigbana ni mo wi pe, Emi ti ṣiṣẹ́ lasan, emi ti lò agbara mi lofo, ati lasan: nitõtọ idajọ mi mbẹ lọdọ Oluwa, ati iṣẹ mi lọdọ Ọlọrun mi.
5Ati nisisiyi, li Oluwa wi, ẹni ti o mọ mi lati inu wá lati ṣe iranṣẹ rẹ̀, lati mu Jakobu pada wá sọdọ rẹ̀, lati ṣà Israeli jọ, ki emi le ni ogo loju Oluwa, Ọlọrun mi yio si jẹ́ agbara mi.
6O si wipe, O ṣe ohun kekere ki iwọ ṣe iranṣẹ mi, lati gbe awọn ẹyà Jakobu dide, ati lati mu awọn ipamọ Israeli pada: emi o si fi ọ ṣe imọlẹ awọn Keferi, ki iwọ ki o le ṣe igbala mi titi de opin aiye.
7Bayi ni Oluwa, Olurapada Israeli, ati Ẹni-Mimọ rẹ wi, fun ẹniti enia ngàn, fun ẹniti orilẹ-ède korira, fun iranṣẹ awọn olori, pe, Awọn ọba yio ri, nwọn o si dide, awọn ọmọ-alade pẹlu yio wolẹ sìn, nitori Oluwa ti iṣe olõtọ, Ẹni-Mimọ Israeli, on li o yàn ọ.
Ìmúpadàbọ̀sípò Jerusalẹmu
8Bayi ni Oluwa wi, Li akoko itẹwọgba emi ti gbọ́ tirẹ, ati li ọjọ igbala, mo si ti ràn ọ lọwọ: emi o si pa ọ mọ, emi o si fi ọ ṣe majẹmu awọn enia, lati fi idi aiye mulẹ, lati mu ni jogun ahoro ilẹ nini wọnni.
9Ki iwọ ki o le wi fun awọn igbekùn pe, Ẹ jade lọ; fun awọn ti o wà ni okùnkun pe, Ẹ fi ara nyin hàn. Nwọn o jẹ̀ li ọ̀na wọnni, pápa ijẹ wọn o si wà ni gbogbo ibi giga.
10Ebi kì yio pa wọn, bẹ̃ni ongbẹ kì yio si gbẹ wọn; õru kì yio mu wọn, bẹ̃ni õrùn kì yio si pa wọn: nitori ẹniti o ti ṣãnu fun wọn yio tọ́ wọn, ani nihà isun omi ni yio dà wọn.
11Emi o si sọ gbogbo awọn òke-nla mi wọnni di ọ̀na, a o si gbe ọ̀na opopo mi wọnni ga.
12Kiye si i, awọn wọnyi yio wá lati ọ̀na jijìn: si wò o, awọn wọnyi lati ariwa wá; ati lati iwọ-õrun wá, ati awọn wọnyi lati ilẹ Sinimu wá.
13Kọrin, ẹnyin ọrun; ki o si yọ̀, iwọ aiye; bú jade ninu orin, ẹnyin oke-nla: nitori Oluwa ti tù awọn enia rẹ̀ ninu, yio si ṣãnu fun awọn olupọnju rẹ̀.
14Ṣugbọn Sioni wipe, Oluwa ti kọ̀ mi silẹ; Oluwa mi si ti gbagbe mi.
15Obinrin ha lè gbagbe ọmọ ọmú rẹ̀ bi, ti kì yio fi ṣe iyọ́nu si ọmọ inu rẹ̀? lõtọ, nwọn le gbagbe, ṣugbọn emi kì yio gbagbe rẹ.
16Kiye si i, emi ti kọ ọ si atẹlẹwọ mi: awọn odi rẹ mbẹ niwaju mi nigbagbogbo.
17Awọn ọmọ rẹ yára; awọn oluparun rẹ ati awọn ti o fi ọ ṣofò yio ti ọdọ rẹ jade.
18Gbe oju rẹ soke yika kiri, si kiyesi i: gbogbo awọn wọnyi ṣà ara wọn jọ, nwọn si wá sọdọ rẹ. Oluwa wipe, Bi mo ti wà, iwọ o fi gbogbo wọn bò ara rẹ, bi ohun ọṣọ́, nitõtọ, iwọ o si há wọn mọ ara, bi iyawo.
19Nitori ibi ofò rẹ, ati ibi ahoro rẹ wọnni, ati ilẹ iparun rẹ, yio tilẹ há jù nisisiyi, nitori awọn ti ngbe inu wọn, awọn ti o gbe ọ mì yio si jinà rére.
20Awọn ọmọ-ọmọ rẹ ti o ti nù yio tun wi li eti rẹ pe, Ayè kò gbà mi, fi ayè fun mi lati ma gbé.
21Nigbana ni iwọ o wi li ọkàn rẹ pe, Tali o bi awọn wọnyi fun mi, mo sa ti wà li ailọmọ ati li àgan, igbèkun ati ẹni-iṣikiri? tani o si ti tọ́ awọn wọnyi dagba? Kiyesi i, a fi emi nikan silẹ, awọn wọnyi, nibo ni nwọn gbe ti wà.
22Bayi ni Oluwa Jehofa wi, Kiyesi i, emi o gbe ọwọ́ mi soke si awọn Keferi, emi o si gbe ọpágun mi soke si awọn enia, nwọn o si gbe awọn ọmọkunrin rẹ wá li apa wọn, a o si gbe awọn ọmọbinrin rẹ li ejìka wọn.
23Awọn ọba yio jẹ baba olutọju rẹ, awọn ayaba wọn yio si jẹ iya olutọju rẹ; ni idojubolẹ ni nwọn o ma tẹriba fun ọ, nwọn o si lá ekuru ẹsẹ rẹ; iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa; nitori oju kì yio tì awọn ti o ba duro dè mi.
24A ha le gba ikogun lọwọ alagbara bi? tabi a le gbà awọn ondè lọwọ awọn ẹniti nwọn tọ́ fun?
25Ṣugbọn bayi ni Oluwa wi, a o tilẹ̀ gbà awọn ondè kuro lọwọ awọn alagbara, a o si gbà ikogun lọwọ awọn ẹni-ẹ̀ru; nitori ẹniti o mba ọ jà li emi o ba jà, emi o si gbà awọn ọmọ rẹ là.
26Awọn ti o ni ọ lara li emi o fi ẹran ara wọn bọ́, nwọn o mu ẹjẹ ara wọn li amuyo bi ọti-waini didùn: gbogbo ẹran-ara yio si mọ̀ pe, Emi Oluwa ni Olugbala ati Olurapada rẹ, Ẹni-alagbara ti Jakobu.
Currently Selected:
Isa 49: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.