YouVersion Logo
Search Icon

Isa 40:27-31

Isa 40:27-31 YBCV

Ẽṣe ti iwọ fi nwi, Iwọ Jakobu, ti iwọ si nsọ, Iwọ Israeli pe, Ọ̀na mi pamọ kuro lọdọ Oluwa, idajọ mi si rekọja kuro lọdọ Ọlọrun mi? Iwọ kò ti imọ? iwọ kò ti igbọ́ pe, Ọlọrun aiyeraiye, Oluwa, Ẹlẹda gbogbo ipẹkun aiye, kì iṣãrẹ̀, bẹ̃ni ãrẹ̀ kì imu u? kò si awari oye rẹ̀. O nfi agbara fun alãrẹ̀; o si fi agbara kún awọn ti kò ni ipá. Ani ãrẹ̀ yio mu awọn ọdọmọde, yio si rẹ̀ wọn, ati awọn ọdọmọkunrin yio tilẹ ṣubu patapata: Ṣugbọn awọn ti o ba duro de Oluwa yio tun agbara wọn ṣe; nwọn o fi iyẹ́ gùn oke bi idì; nwọn o sare, kì yio si rẹ̀ wọn; nwọn o rìn, ãrẹ̀ kì yio si mu wọn.