Isa 4
4
1ATI li ọjọ na obinrin meje yio dimọ́ ọkunrin kan, wipe, Awa o jẹ onjẹ ara wa, awa o si wọ̀ aṣọ ara wa: kìkì pe, jẹ ki a fi orukọ rẹ pè wa, lati mu ẹgàn wa kuro.
A óo Tún Jerusalẹmu Kọ́
2Li ọjọ na ni ẹka Oluwa yio ni ẹwà on ogo, eso ilẹ yio si ni ọla, yio si dara fun awọn ti o sálà ni Israeli.
3Yio si ṣe, pe, ẹniti a fi silẹ ni Sioni, ati ẹniti o kù ni Jerusalemu, li a o pè ni mimọ́, ani orukọ olukuluku ẹniti a kọ pẹlu awọn alãye ni Jerusalemu.
4Nigbati Oluwa ba ti wẹ̀ ẹgbin awọn ọmọbinrin Sioni nù, ti o si ti fọ ẹ̀jẹ Jerusalemu kuro li ãrin rẹ̀ nipa ẹmi idajọ, ati nipa ẹmi ijoná.
5Lori olukuluku ibùgbe oke Sioni, ati lori awọn apejọ rẹ̀, li Oluwa yio si da awọsanma, ati ẹ̃fin li ọsan, ati didan ọwọ́ iná li oru: nitori àbò yio wá lori gbogbo ogo.
6Agọ kan yio si wà fun ojiji li ọsan kuro ninu oru, ati fun ibi isasi, ati fun ãbo kuro ninu ijì, ati kuro ninu ojò.
Currently Selected:
Isa 4: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.