YouVersion Logo
Search Icon

Isa 29

29
Òkè Sioni Ìlú Dafidi
1EGBE ni fun Arieli, fun Arieli, ilu ti Dafidi ti ngbe! ẹ fi ọdun kún ọdun; jẹ ki wọn pa ẹran rubọ.
2Ṣugbọn emi o pọ́n Arieli loju, àwẹ on ibanujẹ yio si wà; yio si dabi Arieli si mi.
3Emi o si dótì ọ yika, emi o si wà odi tì ọ, emi o si mọ odi giga tì ọ.
4A o si rẹ̀ ọ silẹ, iwọ o sọ̀rọ lati ilẹ jade, ọ̀rọ rẹ yio rẹ̀lẹ lati inu ekuru wá, ohùn rẹ yio si dabi ti ẹnikan ti o li ẹmi àfọṣẹ lati ilẹ jade, ọ̀rọ rẹ yio si dún lati inu erupẹ ilẹ wá.
5Ọpọlọpọ awọn ọtá rẹ yio dabi ekuru lẹ́bulẹ́bu, ọpọlọpọ aninilara rẹ yio dabi ìyangbo ti o kọja lọ: lõtọ, yio ri bẹ̃ nisisiyi lojiji.
6Ãrá, ìṣẹlẹ, ati iró nla, pẹlu ìji on ẹfúfu, ati ọwọ́ ajonirun iná ni a o fi bẹ̀ ọ wò lati ọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun wá.
7Bi alá iran oru li ọ̀pọlọpọ awọn orilẹ-ède ti mba Arieli jà yio ri; gbogbo ẹniti o bá ati on, ati odi agbara rẹ̀ jà, ti nwọn si pọ́n ọ loju.
8Yio si dabi igbati ẹni ebi npa nla alá; si wo o, o njẹun; ṣugbọn o ji, ọkàn rẹ̀ si ṣofo: tabi bi igbati ẹniti ongbẹ ngbẹ nla alá, si wo o, o nmu omi, ṣugbọn o ji, si wo o, o dáku, ongbẹ si ngbẹ ọkàn rẹ̀; gẹgẹ bẹ̃ ni gbogbo ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède yio ri, ti mba oke Sioni jà.
Ìkìlọ̀ tí A kò Náání
9Mu ara duro jẹ, ki ẹnu ki o yà nyin; ẹ fọ́ ara nyin loju, ẹ si fọju: nwọn mu amupara; ṣugbọn kì iṣe fun ọti-waini, nwọn nta gbọngbọ́n ṣugbọn kì iṣe fun ohun mimu lile.
10Nitori Oluwa dà ẹmi õrun ijìka lù nyin, o si se nyin li oju: awọn wolĩ ati awọn olori awọn ariran nyin li o bò li oju.
11Iran gbogbo si dabi ọ̀rọ iwe kan fun nyin ti a dí, ti a fi fun ẹnikan ti o mọ̀ ọ kà, wipe, Emi bẹ̀ ọ, kà eyi, ti o si wipe, emi kò le ṣe e; nitori a ti dí i.
12A si fi iwe na fun ẹniti kò mọ̀ iwe, wipe, Emi bẹ̀ ọ, kà eyi, on si wipe, emi kò mọ̀ iwe.
13Nitorina Oluwa wipe, Niwọ̀n bi awọn enia yi ti nfi ẹnu wọn fà mọ mi, ti nwọn si nfi etè wọn yìn mi, ṣugbọn ti ọkàn wọn jìna si mi, ti nwọn si bẹru mi nipa ilana enia ti a kọ́ wọn.
14Nitorina, Kiye si i, emi o ma ṣe iṣẹ́ iyanu lọ lãrin awọn enia yi, ani iṣẹ iyanu ati ajeji: ọgbọ́n awọn ọlọgbọ́n wọn yio si ṣegbe, oye awọn amoye wọn yio si põra.
15Egbe ni fun awọn ti nwá ọ̀na lati fi ipinnu buruburu wọn pamọ́ kuro loju Oluwa, ti iṣẹ wọn si wà li okunkun, ti nwọn si wipe, Tali o ri wa? tali o mọ̀ wa?
Ìrètí Ọjọ́ Ọ̀la
16A, iyipo nyin! a ha le kà amọ̀koko si bi amọ̀: ohun ti a mọ ti ṣe lè wi fun ẹniti o ṣe e pe, On kò ṣe mi? ìkoko ti a mọ le wi fun ẹniti o mọ ọ pe, On kò moye?
17Kò ha ṣe pe ìgba diẹ kiun si i, a o sọ Lebanoni di ọgbà eleso, ati ọgbà eleso li a o kà si bi igbo?
18Ati li ọjọ na awọn aditi yio si gbọ́ ọ̀rọ iwe nì, awọn afọju yio si riran lati inu owúsuwusù, ati lati inu okunkun.
19Ayọ̀ awọn onirẹlẹ yio bí si i ninu Oluwa, ati inu awọn talaka ninu awọn enia yio si dùn ninu Ẹni-Mimọ Israeli.
20Nitori a sọ aninilara na di asan, a si pa ẹlẹgàn run, a si ké gbogbo awọn ti nṣọ́ aiṣedede kuro.
21Ẹniti o dá enia li ẹbi nitori ọ̀rọ kan, ti nwọn dẹkùn silẹ fun ẹniti o baniwi ni ẹnubodè, ti nwọn si tì olododo si apakan, si ibi ofo.
22Nitorina bayi li Oluwa, ẹniti o rà Abrahamu padà wi, pe, niti ile Jakobu, oju kì yio tì Jakobu mọ bẹ̃ni oju rẹ̀ kì yio yipada mọ.
23Ṣugbọn nigbati on nri awọn ọmọ rẹ̀, iṣẹ́ ọwọ́ mi, li ãrin rẹ̀, nwọn o yà orukọ mi si mimọ́, nwọn o si yà Ẹni-Mimọ Jakobu nì si mimọ́, nwọn o si bẹ̀ru Ọlọrun Israeli.
24Awọn pẹlu ti o ṣinà nipa ẹmi, oye yio wá yé wọn, ati awọn ti nsọ bótibòti yio kọ́ ẹkọ́.

Currently Selected:

Isa 29: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy