YouVersion Logo
Search Icon

Gal 6:1-9

Gal 6:1-9 YBCV

ARÁ, bi a tilẹ mu enia ninu iṣubu kan, ki ẹnyin ti iṣe ti Ẹmí ki o mu irú ẹni bẹ̃ bọ̀ sipò ni ẹmí iwa tutu; ki iwọ tikararẹ mã kiyesara, ki a má ba dan iwọ nã wò pẹlu. Ẹ mã rù ẹrù ọmọnikeji nyin, ki ẹ si fi bẹ̃ mu ofin Kristi ṣẹ. Nitori bi enia kan ba nrò ara rẹ̀ si ẹnikan, nigbati kò jẹ nkan, o ntàn ara rẹ̀ jẹ. Ṣugbọn ki olukuluku ki o yẹ iṣẹ ara rẹ̀ wò, nigbana ni yio si ni ohun iṣogo nipa ti ara rẹ̀ nikan, kì yio si ṣe nipa ti ọmọnikeji rẹ̀. Nitori olukuluku ni yio rù ẹrù ti ara rẹ̀. Ṣugbọn ki ẹniti a nkọ́ ninu ọ̀rọ na mã pese ohun rere gbogbo fun ẹniti nkọni. Ki a máṣe tàn nyin jẹ; a kò le gàn Ọlọrun: nitori ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká. Nitori ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti ara rẹ̀, nipa ti ara ni yio ká idibajẹ; ṣugbọn ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti Ẹmí, nipa ti Ẹmí ni yio ká ìye ainipẹkun. Ẹ má si jẹ ki agãra da wa ni rere iṣe: nitori awa ó ká nigbati akokò ba de, bi a kò bá ṣe ãrẹ̀.