Esr 4
4
Àtakò Sí Títún Ilé Ọlọrun Kọ́
1NIGBATI awọn ọta Juda ati Benjamini gbọ́ pe awọn ọmọ-igbekun nkọ́ tempili fun Oluwa Ọlọrun Israeli;
2Nigbana ni nwọn tọ̀ Serubbabeli wá, ati awọn olori awọn baba, nwọn si wi fun wọn pe, ẹ jẹ ki awa ki o ba nyin kọle, nitoriti awa nṣe afẹri Ọlọrun nyin, gẹgẹ bi ẹnyin; awa si nru ẹbọ si ọdọ rẹ̀, lati ọjọ Esarhaddoni, ọba Assuri, ẹniti o mu wa gòke wá ihinyi.
3Ṣugbọn Serubbabeli, ati Jeṣua ati iyokù ninu awọn olori awọn baba Israeli wi fun wọn pe, Kì iṣe fun awa pẹlu ẹnyin, lati jumọ kọ ile fun Ọlọrun wa; ṣugbọn awa tikarawa ni yio jùmọ kọle fun Oluwa Ọlọrun Israeli gẹgẹ bi Kirusi ọba, ọba Persia, ti paṣẹ fun wa,
4Nigbana ni awọn enia ilẹ na mu ọwọ awọn enia Juda rọ, nwọn si yọ wọn li ẹnu ninu kikọle na.
5Nwọn si bẹ̀ awọn ìgbimọ li ọ̀wẹ si wọn, lati sọ ipinnu wọn di asan, ni gbogbo ọjọ Kirusi, ọba Persia, ani titi di ijọba Dariusi, ọba Persia.
Àtakò sí Títún Jerusalẹmu Kọ́
6Ati ni ijọba Ahasuerusi, ni ibẹ̀rẹ ijọba rẹ̀, ni nwọn kọwe ẹ̀sun lati fi awọn ara Juda ati Jerusalemu sùn.
7Ati li ọjọ Artasasta ni Biṣlami, Mitredati, Tabeeli ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ iyokù kọwe si Artasasta, ọba Persia: a si kọ iwe na li ède Siria, a si ṣe itumọ rẹ̀ li ède Siria.
8Rehumu, adele ọba, ati Ṣimṣai, akọwe, kọ iwe ẹ̀sun Jerusalemu si Artasasta ọba, bi iru eyi:
9Nigbana ni Rehumu, adele-ọba, ati Ṣimṣai akọwe, ati awọn ẹgbẹ wọn iyokù: awọn ara Dina, ti Afarsatki, ti Tarpeli, ti Afarsi, ti Arkefi, ti Babiloni, ti Susanki, ti Dehafi ati ti Elamu,
10Ati awọn orilẹ-ède iyokù ti Asnapperi, ọlọla ati ẹni-nla nì, kó rekọja wá, ti o si fi wọn do si ilu Samaria, ati awọn iyokù ti o wà ni ihahin odò, ati ẹlomiran.
11Eyi ni atunkọ iwe na ti nwọn fi ranṣẹ si i, ani si Artasasta ọba: Iranṣẹ rẹ, awọn enia ihahin odò ati ẹlomiran.
12Ki ọba ki o mọ̀ pe, awọn Ju ti o ti ọdọ rẹ wá si ọdọ wa, nwọn de Jerusalemu, nwọn nkọ́ ọlọtẹ ilu ati ilu buburu, nwọn si ti fi odi rẹ̀ lelẹ, nwọn si ti so ipilẹ rẹ̀ mọra pọ̀.
13Ki ọba ki o mọ̀ nisisiyi pe, bi a ba kọ ilu yi, ti a si tun odi rẹ̀ gbe soke tan, nigbana ni nwọn kì o san owo ori, owo-bode, ati owo odè, ati bẹ̃ni nikẹhin yio si pa awọn ọba li ara.
14Njẹ nisisiyi lati ãfin ọba wá li a sa ti mbọ́ wa, kò si yẹ fun wa lati ri àbuku ọba, nitorina li awa ṣe ranṣẹ lati wi fun ọba daju;
15Ki a le wá inu iwe-iranti awọn baba rẹ: bẹ̃ni iwọ o ri ninu iwe-iranti, iwọ o si mọ̀ pe, ọlọtẹ ni ilu yi, ti o si pa awọn ọba ati igberiko li ara, ati pe, nwọn ti ṣọtẹ ninu ikanna lati atijọ wá, nitori eyi li a fi fọ ilu na.
16Awa mu u da ọba li oju pe, bi a ba tun ilu yi kọ, ti a si pari odi rẹ̀ nipa ọ̀na yi, iwọ kì o ni ipin mọ ni ihahin odò.
17Nigbana ni ọba fi èsi ranṣẹ si Rehumu, adele-ọba, ati si Ṣimṣai, akọwe, pẹlu awọn ẹgbẹ wọn iyokù ti ngbe Samaria, ati si awọn iyokù li oke odò: Alafia! ati kiki miran.
18A kà iwe ti ẹnyin fi ranṣẹ si wa dajudaju niwaju mi.
19Mo si paṣẹ, a si ti wá, a si ri pe, lati atijọ wá, ilu yi a ti ma ṣọ̀tẹ si awọn ọba, ati pe irukerudo ati ọ̀tẹ li a ti nṣe ninu rẹ̀.
20Pẹlupẹlu awọn ọba alagbara li o ti wà lori Jerusalemu, awọn ti o jọba lori gbogbo ilu oke-odò; owo ori, owo odè, ati owo bodè li a ti nsan fun wọn.
21Ki ẹnyin ki o paṣẹ nisisiyi lati mu awọn ọkunrin wọnyi ṣiwọ, ki a má si kọ ilu na mọ, titi aṣẹ yio fi jade lati ọdọ mi wá.
22Ẹ kiyesi ara nyin, ki ẹnyin ki o má jafara lati ṣe eyi: ẽṣe ti ìbajẹ yio fi ma dàgba si ipalara awọn ọba?
23Njẹ nigbati a ka atunkọ iwe Artasasta ọba niwaju Rehumu, ati Ṣimṣai akọwe, ati awọn ẹgbẹ wọn, nwọn gòke lọ kankán si Jerusalemu, si ọdọ awọn Ju, nwọn si fi ipá pẹlu agbara mu wọn ṣiwọ.
24Nigbana ni iṣẹ ile Ọlọrun ti o wà ni Jerusalemu, duro. Bẹ̃li o duro titi di ọdun keji Dariusi, ọba Persia.
Currently Selected:
Esr 4: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.