YouVersion Logo
Search Icon

Esek 7

7
Òpin ti dé Tán fún Israẹli
1Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
2Iwọ ọmọ enia, bayi li Oluwa Ọlọrun wi pẹlu si ile Israeli; Opin, opin de sori igun mẹrẹrin ilẹ.
3Opin de si ọ wayi, emi o si rán ibinu mi sori rẹ, emi o si da ọ lẹjọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ; emi o si san gbogbo irira rẹ pada si ọ lori.
4Oju mi kì yio si dasi, bẹ̃li emi kì yio ṣãnu: ṣugbọn emi o san ọ̀na rẹ pada si ọ lori, ati irira rẹ yio wà li ãrin rẹ: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.
5Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; ibi kan, ibi kanṣoṣo, kiye si i, o de.
6Opin de, opin de: o jí si ọ; kiye si i, o de.
7Ilẹ mọ́ ọ, iwọ ẹniti ngbe ilẹ na: akokò na de, ọjọ wahala sunmọ tosí; kì isi ṣe ariwo awọn oke-nla.
8Nisisiyi li emi o dà ikannu mi si ọ lori, emi o si mu ibinu mi ṣẹ si ọ lori: emi o si dá ọ lẹjọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ, emi o si san fun ọ nitori gbogbo irira rẹ.
9Oju mi kì yio si dasi, bẹ̃li emi kì yio ṣãnu: emi o si san fun ọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ, ati irira rẹ ti mbẹ lãrin rẹ; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa ti nkọlu.
10Kiye si i ọjọ na, kiyesi i, o de: ilẹ ti mọ́; ọpá ti tanná, irera ti rudi.
11Iwa-ipa ti dide di ọpa ìwa buburu: ọkan ninu wọn kì yio kù, tabi ninu ọ̀pọlọpọ wọn, tabi ninu ohun kan wọn, bẹ̃ni kì yio si ipohùnreré ẹkun fun wọn.
12Akoko na de, ọjọ na sunmọ itosi: ki olùra máṣe yọ̀, bẹ̃ni ki olùta máṣe gbãwẹ: nitori ibinu de ba gbogbo wọn.
13Nitori olùta kì yio pada si eyi ti a tà, bi wọn tilẹ wà lãye: nitori iran na kàn gbogbo enia ibẹ̀, ti kì yio pada; bẹ̃ni kò si ẹniti yio mu ara rẹ̀ le ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
14Nwọn ti fọn ipè, lati jẹ ki gbogbo wọn mura; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o lọ si ogun: nitori ibinu mi wà lori gbogbo wọn.
15Idà mbẹ lode, ajakálẹ àrun ati iyàn si mbẹ ninu: ẹniti o wà li oko yio kú nipa idà; ẹniti o wà ninu ilu, iyàn ati ajakálẹ àrun ni yio si jẹ ẹ run.
16Ṣugbọn awọn ti o bọ́ ninu wọn yio salà, nwọn o si wà lori oke bi adabà afonifoji, gbogbo nwọn o ma gbãwẹ, olukuluku nitori aiṣedede rẹ̀.
17Gbogbo ọwọ́ ni yio rọ, gbogbo ẽkun ni yio si di ailera bi omi.
18Aṣọ ọ̀fọ ni nwọn o fi gbajá pẹlu; ìbẹru ikú yio si bò wọn mọlẹ; itiju yio si wà loju gbogbo wọn, ẽpá yio si wà li ori gbogbo wọn.
19Nwọn o sọ fadaka wọn si igboro, wura wọn li a o si mu kuro; fadaka wọn ati wura wọn kì yio si le gbà wọn là li ọjọ ibinu Oluwa: nwọn kì yio tẹ́ ọkàn wọn lọrùn, bẹ̃ni nwọn kì yio kún inu wọn; nitori on ni idùgbolu aiṣedede wọn.
20Bi o ṣe ti ẹwà ohun ọṣọ́ rẹ̀ ni, o gbe e ka ibi ọlanla: ṣugbọn nwọn yá ere irira wọn ati ohun ikorira wọn ninu rẹ̀: nitorina li emi ṣe mu u jina si wọn.
21Emi o si fi i si ọwọ́ awọn alejo fun ijẹ, ati fun enia buburu aiye fun ikogun: nwọn o si bà a jẹ.
22Oju mi pẹlu li emi o yipada kuro lọdọ wọn, nwọn o si ba ibi ikọkọ mi jẹ; nitori awọn ọlọṣà yio wọ inu rẹ̀, nwọn o si bà a jẹ.
23Rọ ẹ̀wọn kan; nitori ilẹ na kún fun ẹ̀ṣẹ ẹjẹ, ilu-nla na si kún fun iwa ipa.
24Nitorina li emi o mu awọn keferi ti o burujulọ, nwọn o si jogun ile wọn: emi o si mu ọṣọ-nla awọn alagbara tán pẹlu, ibi mimọ́ wọn li a o si bajẹ.
25Iparun mbọ̀ wá, nwọn o si wá alafia, kì yio si si.
26Tulasì yio gori tulasi, irọkẹ̀kẹ yio si gori irọkẹ̀kẹ; nigbana ni nwọn o bere lọdọ woli; ṣugbọn ofin yio ṣegbé kuro lọdọ alufa, ati imọ̀ kuro lọdọ awọn agbà.
27Ọba yio ṣọ̀fọ, a o si fi idahoro wọ̀ ọmọ-alade, ọwọ́ awọn enia ilẹ na li a o wahala, emi o ṣe si wọn gẹgẹ bi ọ̀na wọn, ati gẹgẹ bi ẹjọ wọn ti ri li emi o dá a fun wọn: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Currently Selected:

Esek 7: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in