Eks 8
8
1OLUWA si sọ fun Mose pe, Tọ̀ Farao lọ, ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA wipe, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi.
2Bi iwọ ba si kọ̀ lati jẹ ki nwọn ki o lọ, kiyesi i, emi o fi ọpọlọ kọlù gbogbo ẹkùn rẹ:
3Odò yio si bi ọpọlọ jade li ọ̀pọlọpọ, nwọn o si goke, nwọn o si wá sinu ile rẹ, ati sinu ibùsun rẹ, ati sori akete rẹ, ati sinu ile awọn ọmọ-ọdọ rẹ, ati sara awọn enia rẹ, ati sinu ãro rẹ, ati sinu ọpọ́n ìpo-iyẹfun rẹ:
4Awọn ọpọlọ na yio si gùn ọ lara, ati lara awọn enia rẹ, ati lara gbogbo awọn iranṣẹ rẹ.
5OLUWA si sọ fun Mose pe, Wi fun Aaroni pe, Nà ọwọ́ rẹ pẹlu ọpá rẹ sori odò wọnni, sori omi ṣiṣàn, ati sori ikojọpọ̀ omi, ki o si mú ọpọlọ jade wá sori ilẹ Egipti.
6Aaroni si nà ọwọ́ rẹ̀ sori omi Egipti; awọn ọpọlọ si goke wá, nwọn si bò ilẹ Egipti.
7Awọn alalupayida si fi idán wọn ṣe bẹ̃, nwọn si mú ọpọlọ jade wá sori ilẹ Egipti.
8Nigbana ni Farao pè Mose ati Aaroni, o si wipe, Ẹ bẹ̀ OLUWA, ki o le mú awọn ọpọlọ kuro lọdọ mi, ati kuro lọdọ awọn enia mi; emi o si jẹ ki awọn enia na ki o lọ, ki nwọn ki o le ṣẹbọ si OLUWA.
9Mose si wi fun Farao pe, Paṣẹ fun mi: nigbawo li emi o bẹ̀bẹ fun ọ, ati fun awọn iranṣẹ rẹ, ati fun awọn enia rẹ, lati run awọn ọpọlọ kuro lọdọ rẹ, ati kuro ninu ile rẹ, ki nwọn ki o kù ni kìki odò nikan?
10On si wipe, Li ọla. O si wipe, Ki o ri bi ọ̀rọ rẹ; ki iwọ ki o le mọ̀ pe, kò sí ẹniti o dabi OLUWA Ọlọrun wa.
11Awọn ọpọlọ yio si lọ kuro lọdọ rẹ, ati kuro ninu ile rẹ, ati kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ, ati kuro lọdọ awọn enia rẹ; ni kìki odò ni nwọn o kù si.
12Mose ati Aaroni si jade kuro lọdọ Farao: Mose si kigbe si OLUWA nitori ọpọlọ ti o ti múwa si ara Farao.
13OLUWA si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose; awọn ọpọlọ na si kú kuro ninu ile, ninu agbalá, ati kuro ninu oko.
14Nwọn si kó wọn jọ li òkiti-òkiti: ilẹ na si nrùn.
15Ṣugbọn nigbati Farao ri pe isimi wà, o mu àiya rẹ̀ le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.
16OLUWA si wi fun Mose pe, Sọ fun Aaroni pe, Nà ọpá rẹ, ki o si lù ekuru ilẹ, ki o le di iná já gbogbo ilẹ Egipti.
17Nwọn si ṣe bẹ̃; Aaroni si nà ọwọ́ rẹ̀ pẹlu ọpá rẹ̀, o si lù erupẹ ilẹ, iná si wà lara enia, ati lara ẹran; gbogbo ekuru ilẹ li o di iná já gbogbo ilẹ Egipti.
18Awọn alalupayida si fi idán wọn ṣe bẹ̃ lati mú iná jade wá, ṣugbọn nwọn kò le ṣe e: bẹ̃ni iná si wà lara enia, ati lara ẹran.
19Nigbana ni awọn alalupayida wi fun Farao pe, Ika Ọlọrun li eyi: ṣugbọn àiya Farao le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.
20OLUWA si wi fun Mose pe, Dide ni kutukutu owurọ̀, ki o si duro niwaju Farao; kiyesi i, o njade lọ si odò; ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi.
21Bi iwọ kò ba si jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, kiyesi i, emi o rán ọwọ́ eṣinṣin si ọ, ati sara iranṣẹ rẹ, ati sara awọn enia rẹ, ati sinu awọn ile rẹ: gbogbo ile awọn ara Egipti ni yio si kún fun ọwọ́ eṣinṣin, ati ilẹ ti nwọn gbé wà pẹlu.
22Li ọjọ́ na li emi o yà ilẹ Goṣeni sọ̀tọ, ninu eyiti awọn enia mi tẹ̀dó si, ti eṣinṣin ki yio sí nibẹ̀; nitori ki iwọ ki o le mọ̀ pe, emi li OLUWA lãrin ilẹ aiye.
23Emi o si pàla si agbedemeji awọn enia mi ati awọn enia rẹ: li ọla ni iṣẹ-amì yi yio si wà.
24OLUWA si ṣe bẹ̃; ọwọ́ eṣinṣin ọ̀pọlọpọ si dé sinu ile Farao, ati sinu ile awọn iranṣẹ rẹ̀: ati ni gbogbo ilẹ Egipti, ilẹ na bàjẹ́ nitori ọwọ́ eṣinṣin wọnni.
25Farao si ranṣẹ pè Mose ati Aaroni o si wipe; Ẹ ma lọ ṣẹbọ si Ọlọrun nyin ni ilẹ yi.
26Mose si wipe, Kò tọ́ lati ṣe bẹ̃; nitori awa o fi ohun irira awọn ara Egipti rubọ si OLUWA Ọlọrun wa: wò o, awa le fi ohun irira awọn ara Egipti rubọ li oju wọn, nwọn ki yio ha sọ wa li okuta?
27Awa o lọ ni ìrin ijọ́ mẹta sinu ijù, ki a si rubọ si OLUWA Ọlọrun wa, bi on o ti paṣẹ fun wa.
28Farao si wipe, Emi o jẹ ki ẹnyin lọ, ki ẹ le rubọ si OLUWA Ọlọrun nyin ni ijù; kìki ki ẹnyin ki o máṣe lọ jìna jù: ẹ bẹ̀bẹ fun mi.
29Mose si wipe, Kiyesi i, emi njade lọ kuro lọdọ rẹ, emi o si bẹ̀ OLUWA ki ọwọ́ eṣinṣin wọnyi ki o le ṣi kuro lọdọ Farao, kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ̀, ati kuro lọdọ awọn enia rẹ̀, li ọla: kìki ki Farao ki o máṣe ẹ̀tan mọ́ li aijẹ ki awọn enia na ki o lọ rubọ si OLUWA.
30Mose si jade kuro lọdọ Farao, o si bẹ̀ OLUWA.
31OLUWA si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose; o si ṣi ọwọ́ eṣinṣin na kuro lọdọ Farao, ati kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ̀, ati kuro lọdọ awọn enia rẹ̀; ọkan kò kù.
32Farao si mu àiya rẹ̀ le nigbayi pẹlu, kò si jẹ ki awọn enia na ki o lọ.
Currently Selected:
Eks 8: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.