YouVersion Logo
Search Icon

Eks 39

39
1NWỌN si fi ninu aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, dá aṣọ ìsin, lati ma fi sìn ni ibi mimọ́, nwọn si dá aṣọ mimọ́ ti iṣe fun Aaroni; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
2O si ṣe ẹ̀wu-efodi na ti wurà, ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ.
3Nwọn si lù wurà nì di ewé fẹlẹfẹlẹ, nwọn si là a li okùn wẹ́wẹ, ati lati fi ṣe iṣẹ ọlọnà sinu aṣọ-alaró, ati sinu elesè-àluko, ati sinu ododó, ati sinu ọ̀gbọ didara nì.
4Nwọn ṣe aṣọ ejika si i, lati so o lù: li eti mejeji li a so o lù.
5Ati onirũru-ọnà ọjá ti o wà lara rẹ̀, lati fi dì i o jẹ́ ọkanna, gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀; ti wurà, aṣọ-alaró, elesè-àluko, ti ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
6Nwọn si ṣiṣẹ́ okuta oniki ti a tò sinu oju-ìde wurà, ti a fin bi ifin èdidi-àmi ti a fin orukọ awọn ọmọ Israeli si.
7O si fi wọn si ejika ẹ̀wu-efodi na, li okuta, iranti fun awọn ọmọ Israeli: bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
8O si fi iṣẹ ọlọnà ṣiṣẹ igbàiya na, bi iṣẹ ẹ̀wu-efodi nì; ti wurà, ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododo, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ.
9Oniha mẹrin ọgbọgba ni; nwọn ṣe igbàiya na ni iṣẹpo meji: ika kan ni gigùn rẹ̀, ika kan si ni ibú rẹ̀, o jẹ́ iṣẹpo meji.
10Nwọn si tò ẹsẹ̀ okuta mẹrin si i: ẹsẹ̀ ekini ni sardiu, ati topasi, ati smaragdu; eyi li ẹsẹ̀ kini.
11Ati ẹsẹ̀ keji, emeraldi, safiru, ati diamondi.
12Ati ẹsẹ̀ kẹta, ligure, agate, ati ametistu.
13Ati ẹsẹ̀ kẹrin, berilu, oniki, ati jasperi: a si tò wọn si oju-ìde wurà ni titò wọn.
14Okuta wọnni si jasi gẹgẹ bi orukọ awọn ọmọ Israeli mejila, gẹgẹ bi orukọ wọn, bi ifin èdidi-àmi, olukuluku ti on ti orukọ rẹ̀, gẹgẹ bi ẹ̀ya mejejila.
15Nwọn si ṣe ẹ̀wọn iṣẹ-ọnà-lilọ kìki wurà si igbàiya na.
16Nwọn si ṣe oju-ìde wurà meji, ati oruka wurà meji; nwọn si fi oruka mejeji si eti igbàiya na mejeji.
17Nwọn si fi ẹ̀wọn wurà iṣẹ-ọnà-lilọ mejeji bọ̀ inu oruka wọnni, ni eti igbàiya na.
18Ati eti mejeji ti ẹ̀wọn iṣẹ-lilọ mejeji nì ni nwọn fi mọ́ inu oju-ìde mejeji, nwọn si fi wọn sara okùn ejika ẹ̀wu-efodi na niwaju rẹ̀.
19Nwọn si ṣe oruka wurà meji, nwọn si fi wọn si eti mejeji igbàiya na, si eti rẹ̀ ti o wà, ni ìha ẹ̀wu-efodi na ni ìha inu.
20Nwọn si ṣe oruka wurà meji, nwọn si fi wọn si ìha mejeji ẹ̀wu-efodi na nisalẹ, si ìha iwaju rẹ̀, ki o kọjusi isolù rẹ̀, loke ọjá ẹ̀wu-efodi na.
21Nwọn si fi oruka rẹ̀ dè igbàiya na mọ́ oruka ẹ̀wu-efodi pẹlu ọjá-àwọn aṣọ-aláró, ki o le ma wà lori onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi na, ati ki igbàiya ni ki o máṣe tú kuro lara ẹ̀wu-efodi na; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
22O si ṣe aṣọ igunwa ẹ̀wu-efodi na ni iṣẹ wiwun, gbogbo rẹ̀ jẹ́ aṣọ-aláró.
23Oju-ọrùn si wà li agbedemeji aṣọ-igunwa na, o dabi oju-ẹ̀wu ogun, pẹlu ọjá yi oju na ká, ki o máṣe ya.
24Nwọn si ṣe pomegranate aṣọ: alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ si iṣẹti aṣọ-igunwa na.
25Nwọn si ṣe ṣaworo kìki wurà, nwọn si fi ṣaworo na si alafo pomegranate wọnni si eti iṣẹti aṣọ igunwa na, yiká li alafo pomegranate wọnni;
26Ṣaworo kan ati pomegranate kan, ṣaworo kan ati pomegranate kan, yi iṣẹti aṣọ-igunwa na ká lati ma fi ṣiṣẹ alufa; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
27Nwọn si ṣe ẹ̀wu ọ̀gbọ daradara ti iṣẹ híhun fun Aaroni, ati fun awọn ọmo rẹ̀,
28Ati fila ọṣọ́ ọ̀gbọ daradara, ati fila ọ̀gbọ didara, ati ṣòkoto ọ̀gbọ olokún wiwẹ,
29Ati ọjá ọ̀gbọ olokùn wiwẹ́, ati ti aṣọ-alaró, ti elesè-àluko, ati ti ododo, oniṣẹ abẹ́rẹ; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
30Nwọn si ṣe awo adé mimọ́ na ni kìki wurà, nwọn si kọwe si i, ikọwe bi fifin èdidi-àmi, MIMỌ SI OLUWA.
31Nwọn si dì ọjá àwọn alaró mọ́ ọ, lati fi dì i loke sara fila na; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.
32Bẹ̃ni gbogbo iṣẹ agọ́ ti agọ́ ajọ na pari: awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA palaṣẹ fun Mose, bẹ̃ni nwọn ṣe.
33Nwọn si mú agọ́ na tọ̀ Mose wá, agọ́ na, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀, ikọ́ rẹ̀, apáko rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, ati ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀ wọnni;
34Ati ibori awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati ibori awọ seali, ati ikele aṣọ-tita.
35Apoti ẹrí nì, ati ọpá rẹ̀ wọnni, ati itẹ́-ãnu nì;
36Tabili na, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati àkara ifihàn;
37Ọpá-fitila mimọ́, pẹlu fitila rẹ̀ wọnni, fitila ti a tò li ẹsẹ̀-ẹsẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati oróro titanna;
38Ati pẹpẹ wurà, ati oróro itasori, ati turari didùn, ati aṣọ-isorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na agọ́ na;
39Pẹpẹ idẹ, ati oju-àro-àwọn idẹ rẹ̀, ọpá rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀, agbada na ati ẹsẹ̀ rẹ̀;
40Aṣọ-tita agbalá na, ọwọ̀n rẹ̀ ati ihò-ìtẹbọ̀ rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na agbalá na, okùn rẹ̀, ati ekàn rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo ìsin agọ́ na, ani agọ́ ajọ;
41Aṣọ ìsin lati ma fi sìn ninu ibi mimọ́, ati aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa.
42Gẹgẹ bi gbogbo ohun ti OLUWA fi aṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe gbogbo iṣẹ na.
43Mose si bojuwò gbogbo iṣẹ na, si kiyesi i, nwọn si ṣe e bi OLUWA ti palaṣẹ, bẹ̃ gẹgẹ ni nwọn ṣe e; Mose si sure fun wọn.

Currently Selected:

Eks 39: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in