YouVersion Logo
Search Icon

Est 7

7
1Bẹ̃ni ọba ati Hamani wá iba Esteri ayaba jẹ àse.
2Ọba si tun wi fun Esteri ni ijọ keji ni ibi àse ti nwọn nmu ọti-waini pe, kini ẹbẹ rẹ, Esteri ayaba? a o si fi fun ọ: ki si ni ibère rẹ? a o si ṣe e, ani lọ ide idaji ijọba.
3Nigbana ni Esteri ayaba dahùn wi pe, bi mo ba ri ore-ọfẹ loju rẹ ọba, bi o ba si wù ọba, mo bẹbẹ ki a fi ẹmi mi bùn mi nipa ẹbẹ mi, ati awọn enia mi nipa ibère mi.
4Nitori a ti tà wa, emi ati awọn enia mi, lati run wa, lati pa wa, ki a le parun. Ṣugbọn bi o ṣe pe, a ti tà wa fun ẹrúkunrin, ati ẹrúbirin ni, emi iba pa ẹnu mi mọ́, bi o tilẹ jẹ pe ọta na kò le di ofò ọba.
5Nigbana ni Ahaswerusi ọba dahùn, o si wi fun Esteri ayaba pe, Tali oluwa rẹ̀ na, nibo li o si wà, ti o jẹ gbe e le ọkàn rẹ̀ lati ṣe bẹ̃?
6Esteri si wi pe, ọlọtẹ enia ati ọta na ni Hamani, ẹni buburu yi. Nigbana ni ẹ̀ru ba Hamani niwaju ọba ati ayaba.
7Ọba si dide ni ibinu rẹ̀ kuro ni ibi àse ti nwọn nmu ọti-waini, o bọ́ si àgbala ãfin. Hamani si dide duro lati tọrọ ẹmi rẹ̀ lọwọ Esteri ayaba; nitori o ti ri pe ọba ti pinnu ibi si on.
8Nigbana ni ọba pẹhinda lati inu àgbala ãfin sinu ibiti nwọn ti nmu ọti-waini, Hamani si ṣubu le ibi ìrọgbọkú lori eyi ti Esteri joko; nigbana ni ọba wi pe, yio ha tẹ́ ayaba lọdọ mi ninu ile bi? Bi ọ̀rọ na ti ti ẹnu ọba jade, nwọn bò oju Hamani.
9Harbona ọkan ninu awọn ìwẹfa si wi niwaju ọba pe, Sa wò o, igi ti o ga ni ãdọta igbọnwọ ti Hamani ti rì nitori Mordekai ti o ti sọ ọ̀rọ rere fun ọba, o wà li oró ni ile Hamani. Ọba si wi pe, Ẹ so o rọ̀ lori rẹ̀.
10Bẹ̃ni nwọn so Hamani rọ̀ sori igi ti o ti rì fun Mordekai; ibinu ọba si rọ̀.

Currently Selected:

Est 7: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in