Oni 8
8
1TALI o dabi ọlọgbọ́n enia? tali o si mọ̀ itumọ nkan? Ọgbọ́n enia mu oju rẹ̀ dán, ati igboju rẹ̀ li a o si yipada.
2Mo ba ọ mọ̀ ọ pe, ki iwọ ki o pa ofin ọba mọ́, eyini si ni nitori ibura Ọlọrun.
3Máṣe yara ati jade kuro niwaju rẹ̀: máṣe duro ninu ohun buburu; nitori ohun ti o wù u ni iṣe.
4Nibiti ọ̀rọ ọba gbe wà, agbara mbẹ nibẹ; tali o si le wi fun u pe, kini iwọ nṣe nì?
5Ẹnikẹni ti o pa ofin mọ́ kì yio mọ̀ ohun buburu: aiya ọlọgbọ́n enia si mọ̀ ìgba ati àṣa.
6Nitoripe ohun gbogbo ti o wuni ni ìgba ati àṣa wà fun, nitorina òṣi enia pọ̀ si ori ara rẹ̀.
7Nitoriti kò mọ̀ ohun ti mbọ̀: tali o si le wi fun u bi yio ti ri?
8Kò si enia kan ti o lagbara lori ẹmi lati da ẹmi duro; bẹ̃ni kò si lagbara li ọjọ ikú: kò si iránpada ninu ogun na; bẹ̃ni ìwa buburu kò le gbà awọn oluwa rẹ̀.
9Gbogbo nkan wọnyi ni mo ri, mo si fiyè si iṣẹ gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn: ìgba kan mbẹ ninu eyi ti ẹnikan nṣe olori ẹnikeji fun ifarapa rẹ̀.
10Bẹ̃ni mo si ri isinkú enia buburu, ati awọn ti o ṣe otitọ ti o wá ti o si lọ kuro ni ibi mimọ́, a si gbagbe wọn ni ilu na: asan li eyi pẹlu.
11Nitoriti a kò mu idajọ ṣẹ kánkán si iṣẹ buburu, nitorina aiya awọn ọmọ enia mura pãpa lati huwa ibi.
12Bi ẹlẹṣẹ tilẹ ṣe ibi nigba ọgọrun, ti ọjọ rẹ̀ si gùn, ṣugbọn nitõtọ, emi mọ̀ pe yio dara fun awọn ti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o bẹ̀ru niwaju rẹ̀:
13Ṣugbọn kì yio dara fun enia buburu, bẹ̃ni kì yio fa ọjọ rẹ̀ gun ti o dabi ojiji, nitoriti kò bẹ̀ru niwaju Ọlọrun.
14Asan kan mbẹ ti a nṣe li aiye; niti pe, olõtọ enia wà, awọn ti o nri fun bi iṣẹ buburu; ati pẹlu, enia buburu wà, awọn ti o nri fun bi iṣẹ olododo: mo ni asan li eyi pẹlu.
15Nigbana ni mo yìn iré, nitori enia kò ni ohun rere labẹ õrùn jù jijẹ ati mimu, ati ṣiṣe ariya: nitori eyini ni yio ba a duro ninu lãla rẹ̀ li ọjọ aiye rẹ̀, ti Ọlọrun fi fun u labẹ õrùn.
16Nigbati mo fi aiya mi si ati mọ̀ ọgbọ́n, on ati ri ohun ti a ṣe lori ilẹ: (ẹnikan sa wà pẹlu ti kò fi oju rẹ̀ ba orun li ọsan ati li oru.)
17Nigbana ni mo wò gbogbo iṣẹ Ọlọrun, pe enia kò le ridi iṣẹ ti a nṣe labẹ õrùn: nitoripe bi enia tilẹ gbiyanju ati wadi rẹ̀, sibẹ kì yio le ri i; ati pẹlupẹlu bi ọlọgbọ́n enia rò lati wadi rẹ̀, sibẹ kì yio lè ridi rẹ̀.
Currently Selected:
Oni 8: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.