YouVersion Logo
Search Icon

Deu 30:15-19

Deu 30:15-19 YBCV

Wò o, emi fi ìye ati ire, ati ikú ati ibi, siwaju rẹ li oni; Li eyiti mo palaṣẹ fun ọ li oni lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀, ati lati ma pa aṣẹ rẹ̀, ati ìlana rẹ̀, ati idajọ rẹ̀ mọ́, ki iwọ ki o le yè, ki o si ma bisi i, ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le busi i fun ọ ni ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a. Ṣugbọn bi àiya rẹ ba pada, ti iwọ kò ba si gbọ́, ṣugbọn ti iwọ di ẹni fifà lọ, ti iwọ si mbọ oriṣa, ti iwọ si nsìn wọn; Emi sọ fun nyin li oni, pe ṣiṣegbé li ẹnyin o ṣegbé; ẹnyin ki yio mu ọjọ́ nyin pẹ lori ilẹ, nibiti iwọ ngòke Jordani lọ lati gbà a. Emi pè ọrun ati ilẹ jẹri tì nyin li oni pe, emi fi ìye ati ikú, ibukún ati egún siwaju rẹ: nitorina yàn ìye, ki iwọ ki o le yè, iwọ ati irú-ọmọ rẹ