YouVersion Logo
Search Icon

Deu 14

14
Àṣà Tí A kò Gbọdọ̀ Dá tí A bá ń Ṣọ̀fọ̀
1ỌMỌ OLUWA Ọlọrun nyin li ẹnyin iṣe: ẹnyin kò gbọdọ̀ bù ara nyin li abẹ, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ fá iwaju nyin nitori okú.
2Nitoripe enia mimọ́ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ, OLUWA si ti yàn ọ lati ma ṣe enia ọ̀tọ fun ara rẹ̀, jù gbogbo orilẹ-ède lọ ti mbẹ lori ilẹ.
Ẹran Tí Ó Mọ́ ati Èyí Tí Kò Mọ́
(Lef 11:1-47)
3Iwọ kò gbọdọ jẹ ohun irira kan.
4Wọnyi li ẹranko ti ẹnyin o ma jẹ: akọmalu, agutan, ati ewurẹ,
5Agbọnrin, ati esuwo, ati gala, ati ewurẹ igbẹ́, ati pigargi, ati ẹfọ̀n, ati ẹtu.
6Ati gbogbo ẹranko ti o là bàta-ẹsẹ̀, ti o si pinyà bàta-ẹsẹ̀ si meji, ti o si njẹ apọjẹ ninu ẹranko, eyinì ni ki ẹnyin ki o ma jẹ.
7Ṣugbọn wọnyi ni ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu awọn ti njẹ apọjẹ, tabi ninu awọn ti o là bàta-ẹsẹ̀; bi ibakasiẹ, ati ehoro, ati garà, nitoriti nwọn njẹ apọjẹ ṣugbọn nwọn kò là bàta-ẹsẹ̀, alaimọ́ ni nwọn jasi fun nyin:
8Ati ẹlẹdẹ̀, nitoriti o là bàta-ẹsẹ̀ ṣugbọn kò jẹ apọjẹ, alaimọ́ ni fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu ẹran wọn, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fọwọkàn okú wọn.
9Wọnyi ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu gbogbo eyiti mbẹ ninu omi: gbogbo eyiti o ní lẹbẹ ti o si ní ipẹ́ ni ki ẹnyin ki o ma jẹ.
10Ati ohunkohun ti kò ba ní lẹbẹ ti kò si ní ipẹ́, ki ẹnyin ki o máṣe jẹ ẹ; alaimọ́ ni fun nyin.
11Gbogbo ẹiyẹ ti o mọ́ ni ki ẹnyin ki o ma jẹ.
12Ṣugbọn wọnyi li awọn ti ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu wọn: idì, ati aṣa-idì, ati idì-ẹja.
13Ati glede, ati aṣá, ati gunugun li onirũru rẹ̀;
14Ati gbogbo ìwo li onirũru rẹ̀;
15Ati ogongo, ati owiwi, ati ẹlulu, ati awodi li onirũru rẹ̀;
16Owiwi kekere, ati owiwi nla, ati ogbugbu;
17Ati pelikan, ati àkala, ati ìgo;
18Ati àkọ, ati ondẹ li onirũru rẹ̀, ati atọka, ati adán.
19Ati ohun gbogbo ti nrakò ti nfò, o jẹ́ alaimọ́ fun nyin: a kò gbọdọ jẹ wọn.
20Ṣugbọn gbogbo ẹiyẹ ti o mọ́ ni ki ẹnyin ki o ma jẹ.
21Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ohunkohun ti o tikara rẹ̀ kú: iwọ le fi i fun alejò ti mbẹ ninu ibode rẹ, ki on ki o jẹ ẹ; tabi ki iwọ ki o tà a fun ajeji: nitoripe enia mimọ́ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ. Iwọ kò gbọdọ bọ̀ ọmọ ewurẹ ninu warà iya rẹ̀.
Òfin nípa Ìdámẹ́wàá
22Ki iwọ ki o dá idamẹwa gbogbo ibisi irugbìn rẹ, ti nti oko rẹ wá li ọdọdún.
23Niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni ibi ti on o gbé yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, ni ki iwọ ki o si ma jẹ idamẹwa ọkà rẹ, ti ọti-waini rẹ, ati ti oróro rẹ, ati akọ́bi ọwọ́-ẹran rẹ, ati ti agbo-ẹran rẹ; ki iwọ ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ nigbagbogbo.
24Bi ọ̀na na ba si jìn jù fun ọ, ti iwọ ki yio fi le rù u lọ, tabi bi ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si ba jìn jù fun ọ, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba bukún ọ:
25Njẹ ki iwọ ki o yi i si owo, ki iwọ ki o si dì owo na li ọwọ́ rẹ, ki o si lọ si ibi na, ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn.
26Ki iwọ ki o si ná owo na si ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́, si akọmalu, tabi agutan, tabi ọti-waini, tabi ọti lile kan, tabi si ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́: ki iwọ ki o si ma jẹ nibẹ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o si ma yọ̀, iwọ, ati awọn ara ile rẹ:
27Ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode rẹ; iwọ kò gbọdọ kọ̀ ọ silẹ; nitoriti kò ní ipín tabi iní pẹlu rẹ.
28Li opin ọdún mẹta ni ki iwọ ki o mú gbogbo idamẹwa ibisi rẹ wa li ọdún na, ki iwọ ki o si gbé e kalẹ ninu ibode rẹ:
29Ati ọmọ Lefi, nitoriti kò ní ipín tabi iní pẹlu rẹ, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ ninu ibode rẹ, yio wá, nwọn o si jẹ nwọn o si yó; ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le bukún ọ ninu gbogbo iṣẹ ọwọ́ rẹ ti iwọ nṣe.

Currently Selected:

Deu 14: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in