Ẹniti iṣe aworan Ọlọrun ti a kò ri, akọbi gbogbo ẹda: Nitori ninu rẹ̀ li a ti dá ohun gbogbo, ohun ti mbẹ li ọrun, ati ohun ti mbẹ li aiye, eyiti a ri, ati eyiti a kò ri, nwọn iba ṣe itẹ́, tabi oye, tabi ijọba, tabi ọla: nipasẹ rẹ̀ li a ti dá ohun gbogbo, ati fun u: On si wà ṣaju ohun gbogbo, ati ninu rẹ̀ li ohun gbogbo duro ṣọkan. On si jẹ ori fun ara, eyini ni ìjọ: ẹniti iṣe ipilẹṣẹ, akọbi lati inu okú wá; pe, ninu ohun gbogbo ki on ki o le ni ipò ti o ga julọ. Nitori didun inu Baba ni pe ki ẹkún gbogbo le mã gbé inu rẹ̀; Ati nipasẹ rẹ̀ lati bá ohun gbogbo lajà, lẹhin ti o ti fi ẹjẹ agbelebu rẹ̀ pari ija; mo ni, nipasẹ rẹ̀, nwọn iba ṣe ohun ti mbẹ li aiye, tabi ohun ti mbẹ li ọrun. Ati ẹnyin ti o ti jẹ alejò ati ọtá rí li ọkàn nyin ni iṣẹ buburu nyin, ẹnyin li o si ti bá laja nisisiyi, Ninu ara rẹ̀ nipa ikú, lati mu nyin wá iwaju rẹ̀ ni mimọ́ ati ailabawọn ati ainibawi; Bi ẹnyin ba duro ninu igbagbọ́, ti ẹ fẹsẹmulẹ ti ẹ si duro ṣinṣin, ti ẹ kò si yẹsẹ kuro ninu ireti ihinrere ti ẹnyin ti gbọ́, eyiti a si ti wasu rẹ̀ ninu gbogbo ẹda ti mbẹ labẹ ọrun, eyiti a fi emi Paulu ṣe iranṣẹ fun.
Read Kol 1
Listen to Kol 1
Share
Compare All Versions: Kol 1:15-23
Save verses, read offline, watch teaching clips, and more!
YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy
Home
Bible
Plans
Videos