YouVersion Logo
Search Icon

Iṣe Apo 6

6
A Yan Àwọn Olùrànlọ́wọ́ Meje
1NJẸ li ọjọ wọnni, nigbati iye awọn ọmọ-ẹhin npọ̀ si i, ikùn-sinu wà ninu awọn Hellene si awọn Heberu, nitoriti a nṣe igbagbé awọn opó wọn ni ipinfunni ojojumọ́.
2Awọn mejila si pè ọpọlọpọ awọn ọmọ-ẹhin jọ̀ sọdọ, nwọn wipe, Kò yẹ ti awa iba fi ọ̀rọ Ọlọrun silẹ, ki a si mã ṣe iranṣẹ tabili.
3Nitorina, ará, ẹ wo ọkunrin meje ninu nyin, olorukọ rere, ẹniti o kún fun Ẹmí Mimọ́ ati fun ọgbọ́n, ẹniti awa iba yàn si iṣẹ yi.
4Ṣugbọn awa o duro ṣinṣin ninu adura igbà, ati ninu iṣẹ iranṣẹ ọ̀rọ na.
5Ọ̀rọ na si tọ́ loju gbogbo ijọ: nwọn si yàn Stefanu, ọkunrin ti o kún fun igbagbọ́ ati fun Ẹmí Mimọ́, ati Filippi ati Prokoru, ati Nikanoru, ati Timoni, ati Parmena, ati Nikola alawọṣe Ju ara Antioku:
6Ẹniti nwọn mu duro niwaju awọn aposteli: nigbati nwọn si gbadura, nwọn fi ọwọ́ le wọn.
7Ọ̀rọ Ọlọrun si gbilẹ; iye awọn ọmọ-ẹhin si pọ̀ si i gidigidi ni Jerusalemu; ọ̀pọ ninu ẹgbẹ awọn alufa si fetisi ti igbagbọ́ na.
Àwọn Aṣiwaju Àwọn Juu Mú Stefanu
8Ati Stefanu, ti o kún fun ore-ọfẹ ati agbara, o ṣe iṣẹ iyanu, ati iṣẹ ami nla lãrin awọn enia.
9Ṣugbọn awọn kan dide ninu awọn ti sinagogu, ti a npè ni ti awọn Libertine, ati ti ara Kirene, ati ti ara Aleksandria, ati ninu awọn ara Kilikia, ati ti Asia nwọn mba Stefanu jiyàn.
10Nwọn kò si le kò ọgbọ́n ati ẹmí ti o fi nsọrọ loju.
11Nigbana ni nwọn bẹ̀ abẹtẹlẹ awọn ọkunrin, ti nwọn nwipe, Awa gbọ́ ọkunrin yi nsọ ọrọ-odi si Mose ati si Ọlọrun.
12Nwọn si rú awọn enia soke, ati awọn àgbagba, ati awọn akọwe, nwọn dide si i, nwọn gbá a mu, nwọn mu u wá si ajọ igbimọ.
13Nwọn si mu awọn ẹlẹri eke wá, ti nwọn wipe, ọkunrin yi kò simi lati sọ ọ̀rọ-òdi si ibi mimọ́ yi, ati si ofin:
14Nitori awa gbọ́ o wipe, Jesu ti Nasareti yi yio fọ́ ibi yi, yio si pa iṣe ti Mose fifun wa dà.
15Ati gbogbo awọn ti o si joko ni ajọ igbimọ tẹjumọ́ ọ, nwọn nwò oju rẹ̀ bi ẹnipe oju angẹli.

Currently Selected:

Iṣe Apo 6: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in